Ìròyìn tán ràn-ìn lórí ayélujára wí pé, ní ìparí ọdún yìí, bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (CBN) yóò fòpinsí lílo Form A, èyí tí máa ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń kàwé ní òkè òkun láti san owó ẹ̀kọ́ wọn.
Ní ipasẹ̀ form A yìí, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń kàwé l’ókè òkun máa ń r’áyè san owó ẹ̀kọ́ wọn pẹ̀lú òṣùwọ̀n pasípárọ ti ìjọba, dípò àwọn tó ń ṣe pàṣípàrọ̀ dọ́là sí náírà nínú ọjà, eléyìí tí ó wọ́n ju ti ìjọba lọ.
Àwọn ọmọ Nàìjíríà ní orí ayélujára ti fíbínúhàn lórí ìròyìn pé, láti oṣù kínní ọdún 2023, owó ẹ̀kọ́ tí wọn yóò máa san yóò lé si.
“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ìròyìn kan pé, ní oṣù kejìlá ọdún yìí, bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò fagilé Form A. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń f’ojú sọ́nà láti kàwé l’ókè òkun máa ní láti gba òṣùwọ̀n pásípáro ọ̀dọ àwọn tí wọ́n ń ṣe káràkátà owó. Ní ṣe ni ó tún burú si,” Adéwálé Adétọ̀nà, olùmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter), kọ èyí sí ojú òpó rẹ̀. Àwọn ènìyàn tí s’àtúnpín àtẹ̀jáde yìí ní ọ̀nà ọ̀kan dín ní ọ̀rìn-lé-ní-igba, àwọn olùmúlò míràn sì ti bu ọwọ́ ìfẹ́ lu àtẹ̀jáde yìí ní ọnà eéjìlá dín ní ọrìn lélọ́ọ̀dúnrún.
I just read that from December 2022, the CBN is canceling Form A. Prospective International Students from Nigeria will have to get FX for their school fees from black market. It keeps getting worse.
— Slimfit (@iSlimfit) June 21, 2022
Àhesọ yìí tí ó wà l’órí ìkànnì Abẹ́yẹfò (Twitter) àti Facebook gbé àwòrán àtẹ̀jáde kan tó wá láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Manchester Metropolitan/Manchester Metropolitan Yunifásiti (Manchester Metropolitan University).
Àkòrí àtẹ̀jáde náà sọ wí pé, “ìdínkù nínú àwọn ìdíyelé Form A ti bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí yóò bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 2022”.
Apparently Manchester Metropolitan University sent this circular alleging that CBN is withdrawing form A by end of 2022 for fee payments. Japa via studies about to be more expensive if true. pic.twitter.com/FOPPz0PpkY
— Wissam Ben Yedder (@DipoAW) June 21, 2022
Èsì ilé ẹ̀kọ́ giga Manchester Metropolitan Yunifásití
TheCable kàn sí àwọn olúṣàkóso ilé ẹ̀kọ́ gíga Manchester Metropolitan Yunifásiti láti ṣe ìwádìí àhesọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní ó wá láti ilé ẹ̀kọ́ náà.
“A mòye pé bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò mú Form A kúrò nílẹ̀ ní ìparí ọdún yìí. Nítorínáà a fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ní ìtọ́sọ́nà tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí,” agbẹnusọ ilé ẹ̀kọ́ náà ni ó wí báyìí.
Iṣamudaju
Osita Nwanisobi, olùdarí ẹ̀ka ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ wí pé irọ́ gbá ni àtẹ̀jáde tí ó wá láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Manchester Metropolitan Yunifásiti.
Nwanisobi ní,“Ìlànà yìí ò wá láti bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”
Ó rọ àwọn òbí àti akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n má ṣe ṣ’àfiyèsí àtẹ̀jáde náà pé kí wọ́n san ọ̀pọ̀ lára owó ẹ̀kọ́ wọn pẹ̀lú Flywire síwájú ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 2022.
Àbọ̀ Ìwádìí
Àbájáde ìwádìí fihàn pé bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò tíì ṣe ìkéde ìlànà pé wọn yóò fòpinsí lílo Form A ní ìparí ọdún yìí. Àhesọ ni ọ̀rọ̀ yìí.