Ọ̀rọ̀ kan lórí ayélujára sọ pé ìjọba àpapọ̀ ti “sọ ilé ẹ̀kọ́ gírámà, èyí tí inú wọn jẹ́ ti ijọba àpapọ̀ di ti aládáni” ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ yìí síta tí a mọ̀ sí Ọlọ́runyẹmí Kẹhinde Patrick, sọ lórí fesibuuku (facebook) pé Ààrẹ Bọla Tinubu “láìyanilẹ́nu” ṣe ìkéde ètò nípa “gbígbé owó orí mìíràn jáde.”
Nínú ọ̀rọ̀ yìí, ẹni yìí sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí ìjọba máa san ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó ó dín ogún náírà fún ọdún kan.
Patrick ṣe ìpín owó náà láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ìdí tí ó fi tó iye yìí. Ó ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó dín mẹ́ta náírà ni owó ilé-ìwé, ẹgbẹ̀rún mẹwa náírà fún owó ibi tí wọ́n máa gbé ní ilé-ìwé, ẹgbẹ̀rún marundinniaadọta náírà fún ìwé kíkà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá náírà fún ìwé tí wọ́n máa kọ nkan sí.
Àwọn owó tí ó kù ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà fún aṣọ ilé-ìwé, ẹgbẹ̀rún mẹwa náírà fún ètò ìpèsè fún òfò, ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà fún àwọn nǹkan tí wọ́n fi máa ń kọ eléyìí, kọ tọun àti ẹgbẹ̀rún mẹwa fún ẹ̀kọ́ tí wọ́n máa ń kọ lẹhìn ìgbà tí ilé ìwé bá lu ago ìlọsílé.
“Nígbà tó jẹ́ ọ̀dọ̀ Tinubu ni ọ̀rọ̀ yìí ti wá, eléyìí kìí ṣe ìròyìn gidi. Tí Tinubu kò bá ṣe èyí ni ìròyìn,” báyìí ni ọ̀rọ̀ tí Patrick kọ ṣe wí.
“Kó má jẹ́ pé ó tún fẹ́ gbé owó orí mìíràn jáde lórí ẹ̀kọ́ gírámà láti lè rí owó tó fi máa ra ọkọ̀ òfuurufú tuntun fún Akpabio àti Abbas, agbẹnusọ fún ilé igbimọ asofin kékeré fún gbogbo “ATILẸYIN” tí wọ́n se fún ara wọn láti ba Nàìjíríà jẹ́.
Ìgbà ọgọ́rin ni àwọn ènìyàn fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, ìgbà mẹtadinlọgọrin ni àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ìgbà mẹrindinlọgbọn ni àwọn tí wọ́n ń lo ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media) pín ọ̀rọ̀ yìí.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àkíyèsí àwọn àsìkọ̀ àti adirẹsi Ibùgbé inú ọ̀rọ̀ yìí.
Ní akọkọ, wọ́n si ìkan nínú owó ilé-ìwé kọ. Bí àpẹẹrẹ, lára àwọn àsìkọ yìí ni “school media” tí wọ́n kọ gẹ́gẹ́bí “skool media”.
Láfikún, ẹni yìí sọ pé atẹjade tí òhun fi síta yìí wá láti “office of the director, senior secondary school education operatives” èyí tí ó yẹ kí o jẹ́ “office of the director, senior secondary school department”, èyí tí ó jẹ́ adirẹsi tí ó yẹ.
TheCable tún rí ìyàtọ̀ láàárín ontẹ (signature) lórí atẹjade ẹni yìí àti ontẹ Binta Abdulkadir, olùdarí senior secondary school education.
A tún ríi pé àwọn ilé isẹ ìròyìn tí wọ́n ṣeé gbára lé kò sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn bloggers nikan ló gbé e jáde.
Ẹka ìjọba àpapọ̀ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ sọ pé ọ̀rọ̀ kátíkàti ni ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n ní iye owó tí ó pọ̀ jù tí àwọn ọmọ Federal Unity Colleges (FUCs) san ni ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún náírà, èyí tí ó jẹ́ owó ilé-ìwé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ gbà sí ilé-ìwé. Owó yìí jẹ́ owó aṣọ ilé-ìwé àti owó àwọn nǹkan tí wọ́n máa rà fi kọ ìwé.
Ẹka ìjọba yìí sọ pé ọ̀rọ̀ Patrick yìí máa si àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí Patrick sọ yìí kìí ṣe òótọ́.