Ọ̀rọ̀ kan sọ pé Davido, gbajúmọ̀ akọrin àti Chioma Adeleke, ìyàwó rẹ̀ ń gbaradì fún ọmọ wọn tuntun, èyí tí ó ma jẹ́ ìkẹta.
Joshua Ijeakhena ló fi ọ̀rọ̀ yìí síta. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹrindinlọgbọn ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn tó ju ẹgbẹ̀rún kan ni wọn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí.
Ọ̀rọ̀ yìí, tí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti pín kiri lórí ayélujára (the internet) ní àwòrán (fọ́tò) Davido àti ti Chioma níbi tí wọ́n ti wọ aṣọ aláwọ̀ òrùlé.
Nínú àwòrán kan, Davido di ìbàdí Chioma mú, wọ́n sì ń rẹ́rìn-ín.
A rí Chioma pẹ̀lú irú ikùn tí obìnrin máa ń ní tó bá lóyún nínú àwòrán yìí.
“Èyí dára púpọ̀, Chioma Adeleke ti lóyún! Davido àti ìyàwó rẹ̀, Chioma Adeleke, ń retí ọmọ kẹta. Wọ́n fi ìròyìn tó múnúdùn yìí síta lẹ́hìn ìgbà tí Davido se ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀,” báyìí ni ọ̀rọ̀ tí Ijeakhena fi síta se sọ.
Ẹ lè rí ọ̀rọ̀ yìí níbí, níbí àti níbí.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí tí Cablecheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára se fi hàn pé àwòrán tí àwọn ènìyàn pín kiri yìí jẹ́ ti inú fídíò kan.
CableCheck ṣàkíyèsí pé àwọn àwòrán yìí jẹ́ àwọn àwòrán tí àwọn ènìyàn yọ láti inú fídíò tí Chioma fi síta láti se ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kẹtalelọgbọn (33rd birthday) tí Davido se.
Chioma fi àwọn àwòrán àti àwọn fídíò kan síta lórí Instagram, ohun ìgbàlódé orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta láti se ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kẹtalelọgbọn tí ọkọ̀ rẹ̀ se.
Ní ọjọ́ kọkanlelogun, osù kọkànlá, ọdún 2025, Davido se ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ kẹtalelọgbọn, ó sì se ìkéde pé òhun yóò gbé àwọn orin tuntun jáde ní ọdún 2026.
Ó dàbí ẹni pé wọ́n se fídíò yìí nìgbà tí wọ́n ń se àjọyọ̀ oyún àwọn ìbejì tí Chioma bí ní ọdún 2023.
Davido àti Chioma mọ̀ọ́mọ̀ má fi àwọn ọmọ wọn yìí síta láti ìgbà tí wọ́n ti bí wọn.
Wọ́n bí àwọn ọmọ ìbejì yìí ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lẹ́hìn ọdún kan tí Ifeanyi, ọmọ wọn àkọ́kọ́/àkọ́bí kú.
Àyẹ̀wò tí Cablecheck tún se fi hàn pé Chioma kò ní ikùn tí àwọn olóyún máa ń ní (baby bump) nígbà tí ó wá sí ayẹyẹ kan tí àwọn ẹbí Davido se.
Àwòrán mìíràn tí wọn yà láti se ìyàlẹ́nu fún Davido nígbà ọjọ́ ìbí rẹ̀ yìí se àfihàn Chioma, ikùn rẹ̀ kò dàbí ẹni tó lóyún.
CableCheck tún ṣàkíyèsí pé kò sí ilé isẹ́ ìròyìn tí wọ́n seé gbàgbọ́ tí wọ́n gbé ìròyìn nípa ọ̀rọ̀ yìí jáde.
BÍ CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Kò sí ẹ̀rí tó sàfihàn pé Davido àti Chioma ń retí ọmọ mìíràn. Àwọn ilé isẹ́ ìròyìn tí wọ́n seé gbàgbọ́ máa tí gbé irú ìròyìn báyìí jáde tó bá jẹ́ òótọ́.