Kọ́lá Abíọ́lá, olùdíje fún ipò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Redemption Party (PRP), sọ láìpẹ́ yìí pé igbimọ tó ń ṣojú ètò àbò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (National Security Council) kò tíì ní ìpàdé kankan láti ọdún 1999.
Abiola sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ibi ifiọ̀rọ̀wálẹ́nuwò ìta gbangba àwọn Ólùdíje fún ipò ààrẹ tí àjọ kan tó ń polongo ìjọba àwa-ara-wa àti ìdàgbàsókè, Centre for Democracy and Development (CDD), ṣètò pẹ̀lú ajọṣepọ ilé-isẹ iroyin Arise News ní Abuja, olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Abiola jẹ́ ìkan nínú àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ mẹ́rin tí wọn pésẹ̀ sí ibi àpéjọ náà ní ọjọ́ àìkú.
Àwọn olùdíje mẹ́ta míràn tó wà ní ibi ifiọ̀rọ̀wálẹ́nuwo ọ̀ún ni Peter Obi, olùdíje fún ipò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labour Party), Rabiu Kwankwaso, tí ó jẹ ti ẹgbẹ́ ́òṣèlú New Nigeria Peoples Party (NNPP) àti Ifeanyi Okowa, igbá-kejì Atiku Abubakar, tí ó jẹ olùdíje fún ipò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP).
Gbogbo àwọn olùdíje náà ló sọ̀rọ̀ nípa ètò ààbò ati ọrọ ajé tí wọn yóò gbekalẹ ti won bá dé ipò ààrẹ.
Nínú ifọrọwaniẹnuwo náà, Reuben Abati, olóòtú ètò náà bèrè lọ́wọ́ àwọn olùdíje ìgbésẹ tí wọ́n yóò gbé, bí wọ́n bá jẹ ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìgbà tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ akọlu tireni tí ó rin ní ojú irin Kaduna sí Abuja ní oṣù kẹta, ọdún 2022 bá ṣẹlẹ̀.
Abiola f’èsì pé igbimọ tó ṣojú ètò àbò l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà ò tíì jókòó láti ọdún 1999.
“Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yìí jẹ́ ọ̀kan nínú ìdojúkọ orílẹ̀-èdè yìí ní ti ètò ààbò láti ọdún tó ti pẹ. A ní láti s’agbeyẹwo ètò ààbò wa lórílẹ̀ èdè yìí.
“Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ lati sọ nípa ètò ààbò ṣùgbọ́n ṣé oun tó kàn ní èyí? Lati ọdún 1999, igbimọ tó ń ṣojú ètò àbò l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò tíì jókòó láti ọdún 1999,” Abiola ló sọ báyìí.
Isewadi
TheCable ṣe agbeyẹwo abala ẹtalelaadọjọ, apá kẹdọgbọn ti ìwé òfin ọdún 1999 (section 153, subsection 25 of the 1999 constitution) tí ó se agbekalẹ àwọn tí yóò wà ní ìgbìmọ̀ ọ̀ún.
“Igbimọ tó ṣojú ètò àbò l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbọ́dọ̀ ní: (a) ààrẹ orílẹ̀-èdè tí ó jẹ alága ìjókòó náà; (b) igbá-kejì ààrẹ tí yóò jẹ igbá-kejì alága; (c) ọgagun òṣìṣẹ́ lórí ètò ààbò orílẹ̀-èdè (d) mínísítà nípa ọ̀rọ̀ ìlú (e) mínísítà nípa ètò ààbò (f) Mínísítà fún ọrọ ilẹ òkèèrè (g) oludamọran ààrẹ lórí ètò ààbò (h) ọga pátápátá fún àwọn Ọlọpa àti (i) ẹnikẹ́ni tí ààrẹ bá yàn.”
Apá kẹrindinlọgbọn f’ikun-un wí pé ètò igbimọ náà ní láti gba ààrẹ ní ìmọ̀ràn lórí ètò ààbò “àti àwọn ọ̀rọ̀ míràn tó nííse pẹ̀lú àwọn Ilé isẹ tí òfin gbé kalẹ̀ fún ètò ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”
Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹwa ọdún yìí, TheCable gbé ìròyìn pé ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe Ìpàdé pẹ̀lú igbimọ tó ń ṣojú ètò ààbò nì ìlú Abuja.
Àwọn míràn tó pesẹ si ibi Ìpàdé náà ni ìgbákeji ààrẹ, Yemi Osinbajo, Boss Mustapha, akọ̀wé àgbà fún ìjọba àpapọ̀, Babagana Monguno, olùdámọ̀ràn ààrẹ Buhari lórí ètò ààbò àti Ibrahim Gambari, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà.
Àwọn mínísítà míràn tí ó wà nibẹ ni Bashir Magashi, mínísítà nípa ètò ààbò, Rauf Aregbesola, mínísítà tó ń rí sí ọrọ abẹle àti Maigari Dingyadi, mínísítà fún ọrọ àwọn ọlọpa. Gbogbo àwọn olórí òṣìṣẹ́ ìjọba àti olórí àwọn ẹṣọ alaabo ló péjú sí ibi àpéjọ náà.
Ní ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù kẹwa ọdún 2022, ìròyìn tàn pé ààrẹ Buhari pe fún ìjokòó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ igbimọ aṣoju ètò ààbò.
Ìpàdé náà wáyé ni ilu Abuja láti ṣe agbeyẹwo lẹkunrẹrẹ àti láti fí okun kún agbára fún àwọn ẹṣọ aláàbò ni Orílẹ̀-èdè yìí.
Àbájáde ìwádìí
Ìrọ́ gbàá ni ọrọ tí Abiola sọ pé igbimọ aṣojú ètò ààbò ní orílẹ̀-èdè yìí ko jókòó/ṣe ìpàdé láti ọdún 1999. Ààrẹ Buhari pe ìpàdé igbimọ náà laipẹ yìí.