Ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi tí sọ pé fídíò kan tí wọ́n fi AI se tí àwọn ènìyàn ti ń pín kiri tó sọ pé wọ́n ń kọ́ ibi ọkọ̀ òfuurufú nínú aginjù kan ní Argungu wá láti orílẹ̀ èdè Colombia.
Charly Boy, gbajúgbajà olorin kan ló fi fídíò yìí síta ní ojú òpó rẹ̀ lórí Instagram, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta ní ọjọ́ ajé, osù kẹwàá, ọdún 2025.
Àmọ́sá, nínu ọ̀rọ̀ tó sọ pẹ̀lú àwọn oniroyin ní ọjọ́bọ̀, Rabiu Sokoto, ọ̀gá fún àwọn tí a mọ̀ sí National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ní ìpínlẹ̀ Kebbi, sọ pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí.
“Irú nnkan báyìí kò ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ yìí. A ti lọ sí gbogbo àwọn ibi tí ó yẹ kí a lọ, a ti se ìwádìí, kò sí nnkan báyìí,” Sokoto ló sọ báyìí.
Yakubu Birnin Kebbi, kọmisọnna fún ọ̀rọ̀ àti àṣà ni Kebbi sọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú alátakò ló fi fídíò yìí síta láti ba orúkọ ìjọba ìpínlẹ̀ yìí jẹ́ àti láti dá wàhálà ṣílẹ̀.
“Ìwà pàlàpálá ni èyí. Àwọn ènìyàn kan ń hùwà laibikita fún ohun tó lè fà ni ìpínlẹ̀ yìí,” báyìí ni kọmisọnna se wí.
“Ibùdó ọkọ̀ òfuurufú kan soso tó wà ní Kebbi ni Sir Ahmadu Bello International Airport, ní Birnin Kebbi. Argungu kò ní ibùdó ọkọ̀ òfuurufú tàbí ohun tó jọ èyí,” báyìí ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi ṣe sọ.
“Ní àfikún, gbogbo orúkọ àwọn ènìyàn ti wọ́n dá nínú fídíò yìí kìí se òótọ́, kò sì sí àkọsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àjọ ìjọba bíi Nigeria Customs Service, the National Drug Law Enforcement Agency tó sọ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí,” báyìí ni ìpínlẹ̀ Kebbi tún sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Ijoba ìpínlẹ̀ Kebbi sọ síwájú pé pípín ọ̀rọ̀ tí kìí se òótọ́ ká báyìí láti si àwọn ènìyàn lọ́nà ń kọ àwọn lóminú.
Ìpínlẹ̀ Kebbi rọ àwọn ènìyàn kí wọ́n má ka ọ̀rọ̀ yìí sí.