TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Amupitan, ẹni tí Ààrẹ Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn gẹ́gẹ́bí alága tuntun fún INEC kò sí lára àwọn agbẹjọ́rò fún Tinubu ní ilé ẹjọ́ ìbò
Share
Latest News
FACT CHECK: Did Nigerian army use old pictures for recent rescue operation?
FACT CHECK: Tinubu’s speech on Trump’s tariff misrepresented as recent comment on US watchlist
Claim wey tok sey FIFA give Kenya $1.2m to build Talanta stadium no correct
Ókwụ́ nà FIFA jị́rị́ $1.2m rụ́ọ́ stadium Talanta nké Kenya bụ̀ ásị́
Irọ́ ni pé mílíọ̀nù kan àti igba dọ́là ni wọ́n fi kọ́ pápá ìṣeré Talanta ní Kenya, FIFA kọ ló sì kọ́ọ
Da’awar cewa filin wasa na Talanta na Kenya ya ci $1.2m, wanda FIFA ta gina karya ne
DISINFO ALERT: Man in viral image NOT chairman of reps’ youth committee
Kebbi deny video wey claim sey ‘secret airport dey Argungu for cocaine trafficking’
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Amupitan, ẹni tí Ààrẹ Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn gẹ́gẹ́bí alága tuntun fún INEC kò sí lára àwọn agbẹjọ́rò fún Tinubu ní ilé ẹjọ́ ìbò

Yemi Michael
By Yemi Michael Published October 15, 2025 9 Min Read
Share

Àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń lo àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára sọ pé Joash Amupitan, alága tuntun fún Independent National Electoral Commission (INEC) ti Ààrẹ Bọ́lá Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn wà lára àwọn agbẹjọ́rò fún Tinubu ní ilé ẹjọ́ ìbò ní ọdún 2023.

Ara àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta sọ pé Amupitan kò tọ́ sí ẹni tí ó yẹ kí o dárí àjọ ètò ìdìbò yìí nítorí pé ó wà lára àwọn agbẹjọ́rò fún Tinubu.

Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pin ọ̀rọ̀ yìí kiri lórí ayélujára lẹ́hìn ìgbà tí Tinubu yan Amupitan gẹ́gẹ́bí alága tuntun fún INEC, lẹ́hìn ìgbà tí Mahmood Yakubu, alága fún INEC fi ipò yìí sílẹ̀ nígbà tí ó parí ọdún márùn-ún tó ṣe ní ìgbà méjì (ọdún mẹwa) gẹ́gẹ́bí alága INEC.

Amupitan, ọmọ ọdún mejidinlọgọta, jẹ́ profẹsọ/ọ̀jọ̀gbọ́n (professor) tó mọ̀ nípa òfin (professor of law) ní Yunifásítì ti ìlú Jos (University of Jos-UniJos), ní ìpínlẹ̀ Plateau, níbi tí ó ti jẹ́ igbá-kejì lórí ọ̀rọ̀ ìṣàkóso fún ọ̀gá pátápátá ilé ẹ̀kọ́ yìí.

Nínú ìròyìn kan tí National Periscope gbé jáde, wọ́n ní Coalition of Civil Society Organisations in Nigeria (COCSON) sọ pé Amupitan ni olórí àwọn agbẹjọ́rò fún ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress (APC) àti Tinubu níbi tí wọ́n ti ń gbọ ẹjọ́ nípa ètò ìdìbò fún Ààrẹ ní ọdún 2023 (2023 presidential election tribunal).

Ẹni kan tó ń jẹ́ @dangbanamanger, tí ó ń lo X, ohun ìgbàlódé alámì krọọsi ti wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Àwọn kan tí wọ́n ń pè ní National Council of State tí ó ní àwọn bíi Ààrẹ, igbá-kejì Ààrẹ, àwọn Ààrẹ tẹ́lẹ̀, àwọn adájọ́ tí wọ́n nípò jùlọ tí wọ́n pẹ̀lú àwọn olùṣejọba ni Nàìjíríà, olórí àwọn ọmọ asòfin ilé ìgbìmọ̀ àgbà, agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ asojusofin kékeré, gbogbo àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ àti ẹni tí ó ń rí sí bí ìjọba àpapọ̀ se ń nọ owó fi ọwọ́ sí yíyàn tí Ààrẹ yan alága tuntun yìí. Ọkùnrin yìí kan náà jẹ́ agbẹjọ́rò fún APC, ó sì tún jẹ́ ara àwọn agbẹjọ́rò fún Tinubu níbi tí wọ́n ti yanjú ọ̀rọ̀ ìbò. Nísìnyí, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú alátakò ti sọ ara wọn di aláwàdà tàbí kó jẹ́ pé wọ́n ń tan àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ,” báyìí ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi síta yìí lórí ayélujára se sọ.

Wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta níbí àti níbí.

ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ

Láti mọ̀ pé Amupitan jẹ́ ara àwọn agbẹjọ́rò fún Tinubu tàbí kii se ara wọn, CableCheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣàyẹ̀wò ìwé kan tí wọ́n ń pè ní certified true copies (CTC), àwọn ìwé tí wọ́n jẹ́ gidi tí wọ́n bu ọwọ́ lù fún ìdájọ́ ètò ìdìbò fún ipò Ààrẹ níbi tí wọn ti yẹ ọ̀rọ̀ yìí wò (verdicts of the presidential election petition tribunal) àti ti ilé ẹjọ́ tó ga jù ní Nàìjíríà (Supreme Court) nípa ìdìbò ọdún 2023.

CTC sáábà máa ń ní gbogbo orúkọ àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n gba ẹjọ́ rò tàbí ṣojú àwọn tí ẹjọ́ kàn. CableCheck ríi pé orúkọ Amupitan kò sí lára àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n gba ẹjọ́ rò fún Tinubu lórí ìdìbò ọdún 2023.

Àmọ́sá, a ríi pé orúkọ ẹnì kan tí ó ń jẹ́ “Taiwo Ọsipitan” wà lára àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n ṣojú Tinubu fún ọ̀rọ̀ yìí.

Ó lè jẹ́ pé ara àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta se àṣìṣe nípa fífi orúkọ Joash Amupitan síta dípò Táíwò Ọsipitan.

Táíwò Ọsipitan, tí ó ti dé ipò tó jù tí agbẹjọ́rò lè dé ní Nàìjíríà (senior advocate of Nigeria-SAN), jẹ́ profẹsọ/ọ̀jọ̀gbọ́n tó mọ̀ nípa òfin ní University of Lagos (UNILAG). Wọlé Ọlánipẹ̀kun (SAN) jẹ́ olórí àwọn agbẹjọ́rò fún Tinubu níbi tí àwọn ènìyàn ti pe ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìdìbò (election petition tribunal) àti ilé ẹjọ́ tó ga jù (Supreme Court).

Àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n gba ẹjọ́ rò fún Tinubu, Kashim Shettima, igbá-kejì Tinubu, Kabir Masari àti ẹgbẹ́ òsèlú APC lórí ọ̀rọ̀ ìdìbò tí ẹgbẹ́ òsèlú Allied Peoples Movement (APM) mú wá sí election petition tribunal ni:

  • L.O. Fagbemi (SAN)
  • Adeniyi Akintola (SAN)
  • Aliyu O. Saiki (SAN)
  • A.M. Rafindadi (SAN)
  • Ahmad El-Marzuq (Esq)
  • Omosanya Popoola (Esq)
  • Folake Abiodun (Esq)
  • Wole Olanipekun (SAN)
  • Akin Olujinmi (SAN)
  • Yusuf All (SAN)
  • Babatunde Ogala (SAN)
  • Funmilayo Quadri (SAN)
  • A.R. Arobo (Esq)
  • Akintola Makinde (Esq)
  • Yinka Ajenifuja (Esq)
  • Rowland Otaru (SAN)
  • A.A. Malik (SAN)
  • Chris E. Agbiti (Esq)
  • Gabriel M. Ishom (Esq)
  • Yomi Aliyu (SAN)
  • G.M. Ishom (Esq)
  • O.R. Iyere (Esq)
  • Edeji Adaeze (Esq)

Àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n gba ẹjọ́ rò fún Tinubu, Shettima, àti APC fún ẹjọ́ ìdìbò fún ipò Ààrẹ tí Peter Obi, olùdíje fún ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party (LP) pè ní ọdún 2023 ni:

  • Wole Olanipekun (SAN)
  • Akin Olujinmi (SAN)
  • Yusuf Ali (SAN)
  • Emmanuel Ukala (SAN)
  • Talwo Osipitan (SAN)
  • Dele Adesina (SAN)
  • Hassan Liman (SAN)
  • Olatunde Busari (SAN)
  • A.U. Mustapha (SAN)
  • Kehinde Ogunwumiju (SAN)
  • Bode Olanipekun (SAN)
  • A.A. Malik (SAN)
  • Funmilayo Quadri (SAN)
  • Babatunde Ogala (SAN)
  • Remi Olatubora (SAN)
  • M.O. Adebayo (SAN)
  • Emmanuel Uwadoka (Esq)
  • Yinka Ajenifuja (Esq)
  • Akintola Makinde (Esq)
  • L.O. Fagbemi (SAN)
  • Charles U. Edosomwan (SAN)
  • Adeniyi Akintola (SAN)
  • Afolabi Fashanu (SAN)
  • Chukwuma Ekomani (SAN)
  • Abiodun Owonikoko (SAN)
  • Solomon Umoh (SAN)
  • Hakeem O. Afolabi (SAN)
  • Y.Η.Α.Ruba (SAN)
  • Anthony Adeniyi (SAN)
  • Mumuni Hanafi (SAN)
  • Japhat Opawale (Esq)
  • Olanrewaju Akinshola (Esq)
  • Huwaila M. Ibrahim (Esq)

Àwọn agbẹjọ́rò tí orúkọ wọn wà ní ìsàlẹ̀ yìí ni wọ́n gba ẹjọ́ rò fún Tinubu, Shettima àti APC nígbà tí Atiku Abubakar, adijedupo fún ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP) pè wọ́n lẹ́jọ́ fún ìdìbò ọdún 2023:

  • Wole Olanipekun (SAN)
  • Akin Olujinmi (SAN)
  • Yusuf Ali (SAN)
  • Emmanuel Ukala (SAN)
  • Taiwo Osipitan (SAN)
  • Adebayo Adelodun (SAN)
  • Oladele Adesina (SAN)
  • Hassan Liman (SAN)
  • Olatunde Busari (SAN)
  • Kehinde Ogunwumiju (SAN)
  • Bode Olanipekun (SAN)
  • Funmilayo Quadri (SAN)
  • Babatunde Ogala (SAN)
  • Remi Olatubora (SAN)
  • M.O. Adebayo (SAN)
  • A.A. Malik (SAN)
  • Yinka Ajenifuja (Esq)
  • Akintola Makinde (Esq)
  • Julius Ishola (Esq)
  • L.O. Fagbemi (SAN)
  • Charles U. Edosomwan (SAN)
  • Adeniyi Akintola (SAN)
  • A. Fashanu (SAN)
  • Chukwuma Ekoneani (SAN)
  • Abiodun J. Owonikoko (SAN)
  • Sam T. Ologunorisha (SAN)
  • Solomon Umoh (SAN)
  • Hakeem O. Afolabi (SAN)
  • Olusola Oke (SAN)
  • Aliyu O. Saiki (SAN)
  • Y.H.A. Ruba (SAN)
  • Anthony Adeniyi (SAN)
  • Mumuni Hanafi (SAN)
  • Ahmad El-Marzuq (Esq)
  • Seun Ajayi (Esq)
  • Omosanya Popoola (Esq)
  • Adeniji Kazeem (SAN)

Ní ilé ẹjọ́ tó ga jù, àwọn agbẹjọ́rò tí orúkọ wọ́n wà ní ìsàlẹ̀ yìí ni wọ́n gba ẹjọ́ rò fún Tinubu, Shettima àti APC:

  • Wole Olanipekun (SAN)
  • Yusuf Ali (SAN)
  • Emmanuel Ukala (SAN)
  • Taiwo Osipitan (SAN)
  • Akintola Makinde (Esq)
  • Akin Olujinmi (SAN)
  • Charles Uwensuji Edosomwon
  • Adeniyi Akintola (SAN)
  • Afolabi Fashanu (SAN)
  • Olumide Olujinmi (Esq)

Ẹ lè rí ìwé tí wọ́n kọ ìdájọ́ yìí sí níbí àti níbí.

BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ

Ẹ̀rí tí a rí fi hàn pé Amupitan kò sí lára àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n gba ẹjọ́ rò fún Tinubu ní ilé ẹjọ́ ìbò ní ọdún 2023.

TAGGED: Bola Tinubu, Election Tribunal, Factcheck in Yorùbá Language, INEC, Joash Amupitan, Legal Team, News in Yorùbá Language, Tinubu's legal team

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael October 15, 2025 October 15, 2025
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print

POPULAR POSTS

Advertisement

FACT CHECK: Did Nigerian army use old pictures for recent rescue operation?

On Monday, the Nigerian army published a statement alongside some pictures across its official social…

November 4, 2025

FACT CHECK: Tinubu’s speech on Trump’s tariff misrepresented as recent comment on US watchlist

On Sunday, a website — Politics Nigeria — published a 25-second video on Facebook wherein…

November 4, 2025

Claim wey tok sey FIFA give Kenya $1.2m to build Talanta stadium no correct

On October 26, Dino Melaye claim sey FIFA give Nigeria and Kenya $1.2 million to…

October 31, 2025

Ókwụ́ nà FIFA jị́rị́ $1.2m rụ́ọ́ stadium Talanta nké Kenya bụ̀ ásị́

N'ụbọchị iri abụọ n'isii nke ọnwa Ọktoba, Dino Melaye kwụrụ na FIFA nyere Naijiria na…

October 31, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

FACT CHECK: Tinubu’s speech on Trump’s tariff misrepresented as recent comment on US watchlist

On Sunday, a website — Politics Nigeria — published a 25-second video on Facebook wherein President Bola said “we have…

Fact Check
November 4, 2025

Claim wey tok sey FIFA give Kenya $1.2m to build Talanta stadium no correct

On October 26, Dino Melaye claim sey FIFA give Nigeria and Kenya $1.2 million to build stadiums for dia kontris. …

CHECK AM FOR WAZOBIA
October 31, 2025

Ókwụ́ nà FIFA jị́rị́ $1.2m rụ́ọ́ stadium Talanta nké Kenya bụ̀ ásị́

N'ụbọchị iri abụọ n'isii nke ọnwa Ọktoba, Dino Melaye kwụrụ na FIFA nyere Naijiria na Kenya otu nde Dollar na…

CHECK AM FOR WAZOBIA
October 31, 2025

Irọ́ ni pé mílíọ̀nù kan àti igba dọ́là ni wọ́n fi kọ́ pápá ìṣeré Talanta ní Kenya, FIFA kọ ló sì kọ́ọ

Ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, osù kẹwàá, ọdún 2025, Dino Melaye sọ pé FIFA fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Kenya ní mílíọ̀nù…

CHECK AM FOR WAZOBIA
October 31, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?