Ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, osù kẹwàá, ọdún 2025, Dino Melaye sọ pé FIFA fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Kenya ní mílíọ̀nù kan àti igba dọ́là kí wọ́n fi kọ́ pápá ìṣeré.
Nínú ọ̀rọ̀ kan tí ẹnì kan fi síta lórí X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi ti wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀, Melaye, ẹni tí ó ti díje dupo rí fún ipò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Kogi fi àwòrán kan tí ó ní pápá ìṣeré meji tí wọ́n ní FIFA ló kọ́ọ síta, ó sì sọ pé àwọn alákòóso ni Nàìjíríà nọ́ owó náà lọ́nà tí kò yẹ.
Àwọn pápá ìṣeré tó fi síta yìí jẹ́ pápá ìṣeré olówó kékeré kan ní Birnin-Kebbi, ní ìpínlẹ̀ Kebbi àti Talanta Sports Stadium tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní Kenya.
“Ìdí tí wọ́n fi fún wọn lówó yìí ni pé kí wọ́n lè kọ́ pápá ìṣeré ìgbábọọlu. Àwọn oníwà pálapàla, àwọn olè ni a máa ń yẹ́ sí,” báyìí ni ọ̀rọ̀ Melaye lórí X se sọ.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀ta àti mọkanlelogun ni wọ́n ti rí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹjọ ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹẹdẹgbẹta ló pín in.
Nínú irú ọ̀rọ̀ yìí, èyí tó yàtọ̀ díẹ̀ sí ti Melaye, ẹni kan tí ó ń jẹ́ @CitizenObs sọ pé FIFA fún Nàìjíríà ní mílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là, wọ́n sì tún fún Kenya ní iye owó kan náà láti fi kọ́ àwọn pápá ìṣeré. Ẹni yìí lo irú àwọn àwòrán kan náà tí Melaye lò.
ÀWỌN OHUN TÍ Ó YẸ KÍ Ẹ KỌ́KỌ́ MỌ̀ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Ní àìpẹ́ yìí, àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń lo àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media users) ti fi ẹ̀sùn kan Nigeria Football Federation (NFF), ẹ̀ka ìjọba Nàìjíríà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ eré bọọlu aláfẹsẹ̀gbá pé wọ́n kó owó jẹ.
Àwọn ọ̀rọ̀ kan sọ pé ara owó tí NFF kó jẹ jẹ́ owó tí FIFA fún wọn.
Ara àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn fi ẹ̀sùn kan NFF lórí ni pápá ìṣeré kékeré tí FIFA fún ìpínlẹ̀ Kebbi lowo pé kí wọ́n kọ́, tí wọ́n kọ́ sí Birnin-Kebbi. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ọ ní ọdún 2020, wọ́n sì síi ní ọdún 2023. Wọ́n ní mílíọ̀nù kan ó lé díẹ̀ dọ́là ($1.19) ni wọ́n fi kọ́ọ.
FIFA se àtìlẹ́hìn pẹ̀lú ètò wọn kan tí wọ́n pè ní “Forward Programme”, èyí tí wọ́n gbékalẹ̀ láti pèsè owó ìrànlọ́wọ́ fún eré bọọlu aláfẹsẹ̀gbá káàkiri àgbáyé. Pápá ìṣeré Kebbi yìí jẹ́ ìkan nínú méjì ohun ère idaraya tí FIFA ran Nàìjíríà lọ́wọ́ láti kọ́. Pápá ìṣeré kékeré kejì wà ní Ugborodo, ní ìpínlẹ̀ Delta.

Wọ́n ń kọ́ pápá ìṣeré tó wà ní Talanta yii lọ́wọ́ ní Nairobi, Kenya. Ibí yìí ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìdíje tí a mọ̀ sí 2027 Africa Cup of Nations (AFCON), tí Kenya, Tanzania àti Uganda yóò ṣe ìgbàlejò rẹ̀.
Pápá ìṣeré yìí yóò gba àwọn ènìyàn bíi ọgọ́ta ẹgbẹ̀rún tí wọ́n ba parí ẹ̀. Ijoba orílẹ̀ èdè Kenya ló gbé owó ṣílẹ̀ kí wón fi kọ, China Road and Bridge Corporation (CRBC) ni wọ́n gbé fún kí wọ́n kọ́ọ.
Gẹ́gẹ́bí ìwé ìròyìn kan tí a mọ̀ sí The Times Kenya se sọ, owó tí wọ́n máa fi kọ́ Talanta Sports City Stadium máa tó mílíọ̀nù lọ́nà ọọdunrun àti bíi marundinlogoji dọ́là.
Wọ́n sọ ọ̀rọ̀ nípa iye owó yìí nínú osù kẹrin nínú ìwé kan tí Soipan Tuya, mú wá sí iwájú àwọn ilé ìgbìmọ̀ asojusofin tí wọ́n ń rí sí ọ̀rọ̀ eré ìdárayá àti àṣà ni Kenya.
BÍ CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Ọ̀rọ̀ tí ẹnì yìí sọ pé pé iye owó kan náà ni wọ́n ń nọ́ láti kọ pápá ìṣeré kékeré kan ní Birnin-Kebbi àti Talanta Sports Stadium ni Kenya kìí ṣe òótọ́.
Irọ́ sì tún ni ọ̀rọ tó sọ pé FIFA ló gbé owó sílẹ̀ kí wọ́n fi kọ́ pápá ìṣeré tí wọ́n ń kọ́ sí Talanta. Ijoba Kenya ni ó máa pèsè owó iṣẹ́ yìí.