Ẹni kan, tí wọ́n ń pè ní @xagreat, tó ń lo X, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, ohun ìgbàlódé ibaraẹnise orí ayélujára, sọ pé ọrọ̀ ajé kankan kò wá sí Ìpínlẹ̀ Kaduna láti ìgbà tí Nasir el-Rufai, gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna nígbàkanrí, ti kúrò ní ipò gómìnà.
Ẹni tó sọ̀rọ̀ yìí, sọ pé, nígbà tí eto ìdìbò 2027 bá dé, àwọn yóò fi ìbò yọ Uba Sani, gómìnà Ìpínlẹ̀ náà nísìnyìí, láti lè jẹ́ kí Ìpínlẹ̀ náà dàgbà sókè.
“Láti ìgbà tí El-Rufai tí fi ipò gómìnà sílẹ̀, ọrọ̀ ajé (Foreign Direct Investment-FDI) kankan kò wá sí Ìpínlẹ̀ Kaduna. Eléyìí ni wọ́n ń pè ní ilọsẹhin,” báyìí ni ẹni yìí se wí.
“A máa fi ẹ̀yìn Uba Sani tì ní ọdún 2027, láti lè gba Kaduna sílẹ̀ lọ́wọ́ ilọsẹhin.”
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ló ti rí/wo ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn òjìlénígba ó dín mẹ́jọ ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn mejidinlọgọrin ló pin in nígbà tí a wòó ní ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹta, ọdún 2025.
KÍ NI ÌDÍ TÍ ỌRỌ̀ AJÉ LÁTI ORÍLẸ̀ ÈDÈ MÍRÀN (FDI) SE SE KÓKÓ?
FDI jẹ́ ọrọ̀ ajé láti orílẹ̀ èdè kan tí ó ń wọ/wá sí orílẹ̀ èdè mìíràn tí ó máa wà níbẹ̀ fún ìgbà pipẹ.
Ó jẹ́ ohun tí ó máa ń jẹ́ kí ìdàgbàsókè wà níbi tí ó bá wà. Àwọn ohun tí a lè pè ní ìdàgbàsókè lè jẹ́ isẹ pípèsè fún àwọn ènìyàn, owó tí ìjọba máa rí ní owó orí, àwọn owó mìíràn tí wọ́n máa rí, ó sì tún máa ń jẹ́ kí ìjọba rí owó fi pamọ sí orílẹ̀ èdè mìíràn.
FDI tún máa ń jẹ́ kí a mọ bí ibì kan se n dàgbà sókè tàbí ní ìlọsíwájú si, èyí tí ó túmọ̀ sí pé ibi tí kò bá ní irú ọrọ̀ ajé yìí kò lọ síwájú.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ THECABLE NEWSPAPER SE RÈÉ
Wọ́n búra fún Sani gẹ́gẹ́bí gómìnà ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2023.
CableCheck se àyẹ̀wò àwọn ọrọ̀ ajé láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn tí National Bureau of Statistics (NBS), àjọ tó ń ṣètò kíka nǹkan, fi síta fún oṣù keje sí oṣù kẹsàn-án (third quarter-Q3), ọdún 2023 sí oṣù keje sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024 (third quarter-Q3, 2024.
Atẹsita NBS fi hàn pé Kaduna kò ní FDI láti oṣù keje sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2023 sí oṣù kẹrin sí oṣù kẹfà (second quarter-Q2), ọdún 2024.
Ninu atẹsita fún FDI fún ọdún 2024, NBS sọ pé FDI tí owó ẹ̀ tó biliọnu méjì dín ní aadọta mílíọ̀nù dọ́là ní o wọlé sí Ìpínlẹ̀ Kaduna ní oṣù keje sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024.
NBS sọ pé Kaduna wà lára àwọn Ìpínlẹ̀ márùn-ún tí ó ní FDI, ní oṣù keje sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024, èyí tí owó ẹ̀ tó biliọnu kan àti mílíọ̀nù marundinlọgọrun dọ́là, eléyìí tí ó jẹ́ bí ìdá kan lára gbogbo FDI, tí owó ẹ̀ jẹ́ biliọnu kan àti mílíọ̀nù igba àti àádọ́ta, tó wọlé sí Nàìjíríà láàárín oṣù keje sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí @xagreat sọ yìí kìí se òótọ́.