Ikilọ: Ìròyìn yìí ní àwọn àwòrán tí wọ́n lè kọni lominu.
Tí ó bá jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tí ó sì máa ń gbọ́ ìròyìn déédéé, ó ṣeéṣe kí ó ti kà tàbí gbọ́ nípa aarun (disease) tí ó ń fa ọgbẹ́ ọ̀fun àti ahọ́n, ọfinkin, ọrùn wíwú àti ailemi dáadáa (diphtheria-difitẹria).
Àkóràn yìí máa ń kọlu imú, ọ̀fun àti ẹran ara nígbà míràn. Àwọn ohun tí ó máa ń jẹ́ kí ènìyàn mọ̀ pé ó ń ṣe ohun ni àìsàn ibà, ọfinkin, ọgbe ọ̀fun, ikọ́, ojú pípọ́n, ọrùn wíwú àti ailemi dáadáa.
Láti jẹ́ kí ó dínkù, ètò abẹ́rẹ́ igbogunti aarun fún àwọn ọmọdé ṣe àlàyé àwọn ìwọn lílo abẹ́rẹ́ tí a gbọ́dọ̀ máa lò fún àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́fà, mẹwa àti mẹ́rìnlá.
Pẹ̀lúpẹ̀lù pé ẹ̀ka ìjọba Àpapọ̀ tí ó ń rí sí ètò igbogunti aarun (Nigeria Centre for Disease Control-NCDC) fi tó àwọn ènìyàn létí pé àwọn ń gbìyànjú láti kápá aarun yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ó sọ pé Bill Gates ni ó fà aarun yìí ní Nàìjíríà.
Nínú oṣù kẹfà, Geeti (Gates) wá sí Nàìjíríà láti jíròrò lórí ọ̀rọ̀ ìlera àgbáyé àti bí èyí yóò ṣe ní ìlọsíwájú pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ yìí kàn.
Irinajo rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ láti Abuja, níbi tí ó ti ṣe ìjíròrò pẹ̀lú Ààrẹ Bola Tinubu. Lẹ́hìn tí ó kúrò ní Nàìjíríà, ó lọ sí orílẹ̀-èdè Niger Republic, ó sì padà wá sí ìlú Èkó láti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́.
Ní ọjọ́ kẹta, oṣù keje, lẹ́hìn ìgbà tí ó padà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn Alákóso Abuja, Olú ìlú Nàìjíríà sọọ lẹhin àyẹ̀wò àwọn kan ni agbègbè tí a mọ̀ sí Dei-dei, pé aarun yìí ti bẹ́ sílẹ̀ ní Nàìjíríà.
Sadiq Abdulrahman, ẹni tí ó jẹ́ adarí ẹ̀ka ìlera àwùjọ sọ wí pé ọmọ ọdún mẹ́rin kan fi ara kó aarun náà, eléyìí tí ó sì se ikú paá.
Nígbà tí ó jẹ́ pé Geeti wá sí Nàìjíríà laipẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó sọ pé òhun ni ó fà aarun náà.
TheCable, ìwé ìròyìn ayélujára rí àwọn ọ̀rọ̀ oríṣiríṣi tí àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ ní orí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé (social media) níbi tí wọ́n ti sọ wí pé Geeti ni ó fa aarun náà.
Hahaha After Bill Gates Visit 🤣🤣🤣🤣🤣🤣🤣🤣
— YUNGROC (@iamyungroc) July 4, 2023
Bill Gates just vissited Abuja, suddenly we have out break Diphtheria.
— Ifediba (@Ifediba5) July 4, 2023
Eléyìí kò ya ni lẹ́nu tí a bá wo ẹ̀sùn tí àwọn ènìyàn fi kàn-án wí pé òhun ni ó fa ajakalẹ aarun kofiidi (Covid19) láti lè dárí àwọn ènìyàn kí ó lè rí èrè yanturu.
ṢÉ WÍWÁ GEETI SÍ NÀÌJÍRÍÀ NÍ OHUNKÓHUN ṢE PẸ̀LÚ AARUN ỌGBẸ́ Ọ̀FUN YÌÍ NÍ NÀÌJÍRÍÀ?
Láti lè dáhùn ọ̀rọ̀ yìí, a wo nkan tí ìtàn sọ.
Bíbẹ́ sílẹ̀ aarun difitẹria yìí kìí ṣe tuntun. Èyí túmọ̀ sí pé kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀. Abuja kọ́ ni ó ti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀.
Ní ọdún méjìlá sẹhin, láàárín oṣù kejì sí oṣù kọkànlá, ọdún 2011, aarun yìí bẹ́ sílẹ̀ ní abúlé Kimba àti àwọn agbègbè rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Borno.
Nígbà tí ó ṣẹlẹ̀, ènìyàn mejidinlọgọrun ni ó ṣe, àwọn mọkanlelogun ni ó sì kú nínú wọn. Ní ìgbà yẹn, NCDC sọ wí pé aarun yìí bẹ́ sílẹ̀ nítorípé kò sí àyẹ̀wò ní àsìkò àti wí pé abẹ́rẹ́ àjẹsára àwọn ènìyàn kò tó.
Nínú oṣù kejìlá, ọdún 2022, wọ́n fi ìbẹ́sílẹ̀ aarun yìí tó NCDC létí ní Ìpínlẹ̀ Kano àti Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó sì ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn Ìpínlẹ̀ bíi Katsina, Cross River, Kaduna, Osun ati Federal Capital Territory (FCT).
Láàárín oṣù kejìlá, ọdún 2022 àti ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kẹfà, ọdún 2023, ẹgbẹ̀rin ó dín méjì àwọn ènìyàn ní àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba rí aridaju pé aarun yìí ṣe. Àwọn ọgọ́rin ènìyàn nínú wọ́n ni ó kú nínú wọn ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹtalelọgbọn ní Ìpínlẹ̀ mẹjọ. Ènìyàn kan ni aarun yí pa ní Abuja.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ahesọ ọ̀rọ̀ gbáà ni ọ̀rọ̀ pé Geeti ni ó fà aarun yìí. Aarun yìí ti bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún méjìlá sẹhin ní ìpínlẹ̀ Borno.Ó sì tún ṣẹlẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ yìí ní oṣù mẹ́fà kí Geeti tó wá sí Nàìjíríà. Èyí túmọ̀ sí pé ahesọ lásán-làsàn ni ọ̀rọ̀ yìí.