TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ṣé Lawan kọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílè fún ẹgbẹ́ alatako PDP?
Share
Latest News
No, Emefiele no return N4trn to FG
Rárá, Emefiele kò dá triliọnu mẹrin náírà padà fún ijọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Ḿbà, Emefiele ènyéghàchìghị̀ FG ọ́nụ́ égó N4trn
A’a, Emefiele bai mayarwa FG N4trn ba
FACT CHECK: No, Emefiele didn’t return N4trn to FG
FAKE NEWS ALERT: Akume hasn’t been replaced as SGF, says presidency
Rárá, Nàìjíríà kò fi àwọn ọmọ iṣẹ́ ológun rán sẹ sí Ísírẹ́lì láti dá rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró
Slurs, smears, slander… how gendered disinformation targets high-profile Nigerian women
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ṣé Lawan kọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílè fún ẹgbẹ́ alatako PDP?

Elizabeth Ogunbamowo
By Elizabeth Ogunbamowo Published June 22, 2022 4 Min Read
Share

Ní ọjọ́ ketàdínlogun oṣù kẹfà, ìròyìn tàn ràn-ìn lórí ìkànnì abẹ́yẹfò Twitter pé ààrẹ ilè ìgbìmọ̀ aṣòfin apapo, Ahmad Lawani kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀.

Àwọn àtẹ̀jáde kan lórí ìkànnì náà wi pe  ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party (APC) sílẹ̀, ó sí tí darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alatako, Peoples Democratic Party (PDP).

“Ahmad Lawan ti kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC, o sì ti darapọ̀ mọ́ PDP torí pé o fẹ ṣetọju ibujoko rẹ̀ ni Ile igbimo asofin   apapo, kìíṣe pé ó fẹ́ sin awọn ènìyàn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba agbegbe rẹ̀. Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́: àpò arawọn ní wọ́n lé,” báyìí ni èyán kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ Mustapha kọ sí ojú òpó ìkànnì abẹ́yẹfò rẹ.

Àtẹ̀jáde yìí ti ní, ókéré jù, atunpin ní ọnà egbeje le ni ogoji ati mejo, àwọn olumulo oju opo naa ti iye won je egberun ni ona merin ati eedegbeta o le mejo sí tí bù ọwọ ìfẹ́ lu.

Ojú òpó kan tó gbé àmì àṣẹ ìkànnì Twitter, @GoldmyneTV náà gbé àhesọ ọ̀rọ̀ naa pe  Lawan ti kọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílè. Ojú òpó yìí ní òntẹ̀lẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbò (50,000), ó sí ma ń sàtúpín àwọn ìròyìn nípa eré ìdárayá.

 

Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí 

Alága ẹgbẹ́ APC, Abdullahi Adamu ti kọ́kọ́ sọ pé Lawan ni olùdíje àjùmọ̀yàn ẹgbẹ́ náà.

Àbálọ àbábọ̀, Lawan kópa nínú ìdíje náà, tí ó sí gbé ipò kẹrin pẹ̀lú ìbò éjì lé ní àádọ̀jọ.

Ààrẹ ilè ìgbìmọ̀ aṣòfin náà kùnà níbi ìdìbò abẹ́nú náà, èyí tí Bola Tinubu, gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ìpínlè Èkó ti jáwé olubori pẹlu ìbò egbefa ati aadorin o lekan .

Iṣamudaju

Ní àsìkò tí ìròyìn yìí n tán ràn-ìn lórí ìkànnì abẹ́yẹfò Twitter yìí, àyẹwò TheCable fihàn pé kò sí ilé iṣẹ́ ìròyìn tó ṣe gbẹ́kẹ̀lé tó gbé ìròyìn náà.

Nínú àtẹ̀jáde kan ní ọjọ́ àbámẹ́ta, Ọlá Awoniyi, agbẹnusọ ààrẹ ilè ìgbìmọ̀ aṣòfin náà sọ wípé ìròyìn òfégè ní àhesọ naa pe Lawan kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Ṣáájú nínú ọ̀sẹ̀ yìí, ààrẹ ilè ìgbìmọ̀ aṣòfin ti kéde pé àwọn aṣòfin méjì láti ìpínlè Kebbi ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú náà sílẹ̀.

Yahaya Abdullahi, aṣoju s’ofin Kebbi North, ati Adamu Aliero, aṣoju s’ofin Kebbi Central, fi ìwé ranṣẹ pe won ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀, wọ́n sì ti darapọ̀ mọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

“Fídíò kan tó ṣàfihàn ibi ti ààrẹ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ń ka lẹ́tà ti Aliero fi rànṣẹ̀ ní àwọn èèyàn kàn ṣe ayédèrú rẹ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn rò pé Lawani ti kọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀,” Awoniyi ni o wi bayi.

Ó ṣàlàyé pé ojúlówó fídíò jẹ́ ìsẹ́jú mẹ̀ta, àti ìṣẹ́jú aaya ọgbọ̀n, fihàn pé Lawan ka lẹta Aliero, tí ó fi to  àwọn akẹgbẹ́ rẹ leti   pe òun ti kúrò lẹgbẹ òṣèlú kan sí omiran. Fídíò yìí ní àwọn kan gé kúrú si ìṣẹ́ju-aaya mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.

Ẹ̀yà fídíò tí wọ́n tí ṣatunkọ rẹ yìí ni wọ́n ti fi tan àwọn ará ìlú.

 

Àbájáde ìwádì

Àhesọ ọ̀rọ̀ nipe ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ahmad Lawan ti kọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ fún ẹgbẹ́ alatako PDP. Iro gbàá ni èyí.

 

A kọ ìròyìn yìí ni ajọṣepọ pẹlu Report for the World, eto agbaye ti o ṣe atilẹyin iṣẹ iroyin tiwa-n-tiwa.

TAGGED: Ahmad Lawan, APC, Elections 2023., PDP

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Elizabeth Ogunbamowo June 22, 2022 June 22, 2022
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

No, Emefiele no return N4trn to FG

One video wey dey waka for social media show as Facebook user claim sey Godwin…

July 4, 2025

Rárá, Emefiele kò dá triliọnu mẹrin náírà padà fún ijọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ti ń pín lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára,…

July 4, 2025

Ḿbà, Emefiele ènyéghàchìghị̀ FG ọ́nụ́ égó N4trn

Ótù ihe ngosị nà soshal midia egosila ebe ótù onye ji Facebook ekesa ozi kwuru…

July 4, 2025

A’a, Emefiele bai mayarwa FG N4trn ba

Wani faifan bidiyo da ke yawo a kafafen sada zumunta ya nuna wani ma’abocin Facebook…

July 4, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

No, Emefiele no return N4trn to FG

One video wey dey waka for social media show as Facebook user claim sey Godwin Emefiele, di forma govnor of…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 4, 2025

Rárá, Emefiele kò dá triliọnu mẹrin náírà padà fún ijọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ti ń pín lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára, tí ó ṣe àfihàn ẹni…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 4, 2025

Ḿbà, Emefiele ènyéghàchìghị̀ FG ọ́nụ́ égó N4trn

Ótù ihe ngosị nà soshal midia egosila ebe ótù onye ji Facebook ekesa ozi kwuru na Godwin Emefiele, onye bụbu…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 4, 2025

A’a, Emefiele bai mayarwa FG N4trn ba

Wani faifan bidiyo da ke yawo a kafafen sada zumunta ya nuna wani ma’abocin Facebook yana ikirarin Godwin Emefiele, tsohon…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 4, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?