Ní ọjọ́ ajé, àwọn òṣìṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fi ọ̀rọ̀ kan síta pẹ̀lú àwọn àwòrán lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára wọn láti lè sọ fún àwọn ènìyàn nípa àwọn ènìyàn méjì tí wọ́n gbà silẹ ní ọwọ́ àwọn ajinigbe ní ìpínlẹ̀ Kogi.
Nínú ọ̀rọ̀ yìí, àwọn òṣìṣẹ́ ológun Nàìjíríà sọ pé àwọn gba àwọn ènìyàn méjì tí wọ́n jigbe yìí ní ọjọ́ ìsinmi, “lẹ́hìn ìgbà tí àwọn ènìyàn fi ọ̀rọ̀ tó àwọn létí pe ìwà ijinigbe kan ń lọ lọ́wọ́ ni òpópónà Itobe-Adumu-Ejule.”
Àwọn òṣìṣẹ́ ológun yìí sọ pé àwọn gba mílíọ̀nù mẹta àti ẹgbẹ̀rin naira tí wọ́n fẹ́ fi gba àwọn ènìyàn yìí ṣílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajinigbe.
“Àwọn òṣìṣẹ́ ológun gbéra laifi àsìkò ṣòfò, a sì rán àwọn ọmọ ológun nisẹ sí ibẹ̀ láti dojú ìjà kọ àwọn ènìyàn yìí. Àmọ́sá, nígbà tí a ń lọ síbẹ̀, àwọn ọ̀daràn yìí dojú ìjà kọ àwọn ọmọ ológun. Àwọn ọmọ ológun kápá wọn, wọn si tú àwọn ènìyàn méjì tí wọ́n jigbe pẹ̀lú owó tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wọn sílẹ̀”, báyìí ni àwọn ọmọ ológun se sọ.
Hassan Abdullahi, ẹni tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn òṣìṣẹ́ ológun ló bu ọwọ́ lu ọ̀rọ̀ yìí.
Àwọn òṣìṣẹ́ ológun fi àwòrán mẹ́rin tó sàfihàn àwọn ènìyàn ti wọ́n jigbe yìí pẹ̀lú àwọn ọmọ iṣẹ́ ológun àti àwọn ọlọ́dẹ síta.
ÀRÍYÀNJIYÀN YÌÍ
Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀ tí àwọn ọmọ òṣìṣẹ́ ológun fi ọ̀rọ̀ àti àwòrán síta lórí X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi ti wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń lo X sọ pé igbanisilẹ̀ yìí ti pẹ́.
Ẹnì kan béèrè ọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ àwòrán ọ̀rọ̀ yìí tó wá lórí Google tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun fi síta.
Àwòrán ọ̀rọ̀ yìí lórí Google sàfihàn pé ìkan nínú àwọn àwòrán yìí tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun fi síta ti wà lórí ayélujára láti bíi osù mẹsan sí ọdún méjì.
Ìkan lára àwọn àyẹ̀wò orí Google fihàn pé Olubunmi Aro, (@bummiero) fi aworan yìí síta ní osù mẹsan ṣẹ́hìn. Àyẹ̀wò mìíràn fihàn pé ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun ń lò lórí Instagram, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta fi àwòrán yìí síta ní ọdún méjì ṣẹ́hìn.
Àwòrán ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì sọ pé bí àwọn òṣìṣẹ́ ológun se lo àwòrán tó ti pẹ́ fún ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò pẹ́ yìí kò dára.

Àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń lo X sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ológun lo àwòrán tó ti pẹ́ yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí Donald Trump, Ààrẹ Amẹ́ríkà sọ pé wọ́n ń pa àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ ní Nàìjíríà.
ÀBÁJÁDE Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Láti lè mọ̀ bóyá àwọn àwòrán tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun fi síta ní ọjọ́ kẹta, osù kọkànlá, ọdún 2025 tí jáde lórí orí ayélujára tẹ́lẹ̀, CableCheck, tí TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣàyẹ̀wò ìkan nínú àwọn àwòrán yìí nípa lílo Google Lens.
Ibi tí ó máa sàfihàn “exact matches” sàfihàn pé kò tii tó ọjọ́ kejì, osù kọkànlá, ọdún 2025 tí àwòrán yìí ti wà lórí ayélujára.
Ìkan nínú èsì tí a rí fi hàn pé @bummiero fi àwòrán yìí síta ní osù mẹsan ṣẹ́hìn.
Nígbà tí Cablecheck ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tí @bummiero fi síta ní àárọ̀ ọjọ́bọ̀, kò sí ọ̀rọ̀ kankan tó sọ pé ẹni yìí tó ń lo X tí fi ọ̀rọ̀ yìí síta ní osù mẹsan ṣẹ́hìn.
Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, @bummiero fi ọ̀rọ̀ kan síta. Ó sọ pé òhun kò fi irú àwòrán báyìí síta.

CableCheck tún ṣàyẹ̀wò àwòrán ọ̀rọ̀ yìí kejì lórí Google. Abayade ayẹwo wa fihan pé ọdún méjì ṣẹ́hìn ni wọ́n ti fi àwòrán yìí síta. Nígbà tí a gbé ọwọ́ lé ọ̀rọ̀ yìí, ó sàfihàn ọ̀rọ̀ tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun fi síta.
Ọ̀rọ̀ yìí, èyí tí wón fi síta ní ọdún 2023 jẹ́ àwòrán kan tí ó ní ètò kan tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun fi tó àwọn ènìyàn létí.
CableCheck tún ṣàyẹ̀wò Instagram àwọn òṣìṣẹ́ ológun, a kò rí àwòrán igbanisilẹ̀ kankan.
CableCheck tún ṣàyẹ̀wò lórí Google léraléra. A ríi pé, nígbà míràn, Google máa ń ṣe àṣìṣe. Àwọn àwòrán tó máa ń gbé jáde kò kii ń bá ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn mu.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, Google kii fún ni ní èsì tó yaranti. Èyí túmọ̀ sí pé èsì kii bá àyẹ̀wò mu nìgbà míràn.
Níwọ̀n ìgbà tí a kò rí àwòrán tó bá àyẹ̀wò wa mu, èyí túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ yìí kò ṣeé gbára lé. A kò lè sọ pàtó pé àwọn òṣìṣẹ́ ológun Nàìjíríà tàbí àwọn tí wọ́n sún mọ́ wọn ni wọ́n fi àwọn àwòrán báyìí sórí ayélujára kó tó di ọjọ́ kẹta, osù kọkànlá, ọdún 2025.