TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ǹjẹ́ Nàìjíría ni àgbàrá ti gbé ọkọ̀ bọ̀gìnì yìí lọ?
Share
Latest News
FACT CHECK: No, Emefiele didn’t return N4trn to FG
FAKE NEWS ALERT: Akume hasn’t been replaced as SGF, says presidency
Rárá, Nàìjíríà kò fi àwọn ọmọ iṣẹ́ ológun rán sẹ sí Ísírẹ́lì láti dá rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró
Slurs, smears, slander… how gendered disinformation targets high-profile Nigerian women
Ḿbà, Naijiria ézipụ̀ghị̀ ńdị́ ágha ńkwàdó ùdó nà òbòdò Isreal
No, Nigeria no send peace support mission go Israel
A’a, Najeriya ba ta tura tawagar taimakon zaman lafiya zuwa Isra’ila ba
Ǹjẹ́ Tinubu àti Alexander Zingman lọ sí ilé-ìwé kan náà? Èyí ni ohun tí a mọ̀
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ǹjẹ́ Nàìjíría ni àgbàrá ti gbé ọkọ̀ bọ̀gìnì yìí lọ?

Elizabeth Ogunbamowo
By Elizabeth Ogunbamowo Published October 26, 2022 3 Min Read
Share

Dakore Egbuson-Akande, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà Nollywood fi àwọn fọ́nrán kàn sí ojú òpó rẹ̀ lórí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ (Instagram). Fọ́nrán náà ṣ’àfihàn ìjàmbá omiya’le, àgbàrá ya ṣọọbu tí ń da àwọn ènìyàn láàmú ni agbègbè Niger Delta orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Dakore ní ontẹle tí ó pọ̀ tó mílíọ̀nù kan lé ní irínwó lórí oun àmúlò ìgbàlódé ayélujára náà.

Òṣèré obínrin náà fí fídíò mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí ojú òpó rẹ̀ ni ọjọ́ àìkú, ìkan nínú àwọn fọ́nrán wọ̀nyí ṣ’àfihàn ọkọ̀ bọ̀gìnì funfun kan tí ó ń gbìyànjú láti kọjá sódì kejì nínú àgbàrá òjò.

Ṣùgbọ́n, ọkọ̀ náà há sí àárín ọ̀nà lẹ́yìn tí ẹkun omi fìí sí ẹ̀gbẹ kòtò kan. Lẹ́yìn o rẹyin, ọkọ̀ náà bọ́ sí inú kòtò botilẹjẹpe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tó wà ní sàkání ìṣẹ̀lẹ̀ náà pariwo.

“A ti finá sórí òrùlé sùn!!! Ìṣẹ̀lẹ̀ abanilẹru lo ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá ni Niger Delta, inú mi bajẹ fún orílẹ̀-èdè mi Nàìjíríà. Ni ìgbà wo ni àwọn olùdarí wa máa bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìtọ́jú àwọn ènìyàn?” Egbuson-Akande kọ èyí sí ojú òpó rẹ̀.

Àwọn aṣàmúlò ojú òpó bù ọwọ ìfẹ́ lú fọ́nrán ọkọ̀ bọ̀gìnì yìí ati àwọn fónrán márùn-ún tó s’àfihàn bí àgbàrá òjò se ṣọṣẹ ní àwọn agbègbè kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ni ìgbà ẹgbẹrun mẹ́fà àti ẹgbẹ̀rin dín ní mọ́kànlélógún (6,779). Kò sí àyè fún àwọn ènìyàn láti wo èsì fún ọ̀rọ̀ náà.

TheCable ṣe ìwádìí fídíò náà, èsì ìwádìí wà nì yìí:

Ifiidiododomulẹ

A se itọpinpin àwòrán àti ẹyin wa (reverse image search) lórí àwòrán tí a gba silẹ láti inú fọ́nrán àkọ́kọ́ yìí nípa lílo Labnol, ohun àmúlò ìgbàlódé tí a fi ń se ìwádìí oríṣun/ibi tí àwòrán àti àwọn mìíràn tó jọọ́ ti wá lórí ayélujára.

Àbájáde ìwádìí wa fihàn pé, fọ́nrán yìí ti wà lórí ayélujára láti ọdún 2017, àwọn olùmúlò sì ti lòó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, láti fi s’àfihàn ẹkun omi ní agbègbè míràn káàkiri àgbáyé. Kódà, wọ́n ti lo fọ́nrán náà fún Tropical Cyclone Dineo, èyí tí ó jẹ́ ìkan nínú afẹ́fẹ́ ìjì líle tó burú jùlọ tó ṣẹlẹ̀ ní iha ìwọ̀ oòrùn ti òkun orílẹ̀-èdè India (south-west Indian Ocean) àti agbede-méjì gúsù (southern hemisphere)

Ìwádìí ìwé ìròyìn TheCable fihàn pé wọ́n gbà fídíò náà silẹ ni Chaman ni ìlú Pakistan, ni ìgbà tí àgbàrá òjò bá ìlú náà fínra ni ọdún 2017.

Ní ìgbà tí a wo fídíò náà ni kíkún, a ríi wí pé àwọn ènìyàn tó n wòran nínú fídíò náà gbìyànjú láti ṣe iranlọwọ fún àwọn èrò inú ọkọ̀ náà.

Àbájáde ìwádìí: Wọn gba fọ́nrán yìí silẹ láti ọdún 2017 ni ìlú Pakistan, kìíse Nàìjíríà bí òṣèré tíátà yìí ti wí.

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Elizabeth Ogunbamowo December 13, 2023 October 26, 2022
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

FACT CHECK: No, Emefiele didn’t return N4trn to FG

A video circulating on social media shows a Facebook user claiming Godwin Emefiele, the former…

July 2, 2025

FAKE NEWS ALERT: Akume hasn’t been replaced as SGF, says presidency

The presidency says reports on George Akume, secretary to the government of the federation (SGF),…

June 29, 2025

Rárá, Nàìjíríà kò fi àwọn ọmọ iṣẹ́ ológun rán sẹ sí Ísírẹ́lì láti dá rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró

Ìròyìn lati inú fídíò Facebook kan sọ pé Nàìjíríà fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí…

June 28, 2025

Slurs, smears, slander… how gendered disinformation targets high-profile Nigerian women

In the early hours of April 15, 2025, armed men wielding firearms and cutlasses attacked…

June 28, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

FAKE NEWS ALERT: Akume hasn’t been replaced as SGF, says presidency

The presidency says reports on George Akume, secretary to the government of the federation (SGF), being replaced are a fabrication.…

Fact CheckFake News AlertTop Stories
June 29, 2025

Rárá, Nàìjíríà kò fi àwọn ọmọ iṣẹ́ ológun rán sẹ sí Ísírẹ́lì láti dá rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró

Ìròyìn lati inú fídíò Facebook kan sọ pé Nàìjíríà fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì kí rògbòdìyàn…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 28, 2025

Ḿbà, Naijiria ézipụ̀ghị̀ ńdị́ ágha ńkwàdó ùdó nà òbòdò Isreal

Ótù ihe ngosị si na Facebook kwuru na Naijiria zipụrụ ndị agha ka ha gaa kwàdó udo na mba Isreal.…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 28, 2025

No, Nigeria no send peace support mission go Israel

One Facebook video claim sey Nigeria send soldiers go Israel for joint peace support mission. One male broadcaster wey dey…

CHECK AM FOR WAZOBIA
June 28, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?