Atẹjade kan lórí ayélujára sọ pé òògùn ìbílẹ̀ nìkan ló lè ṣeé tọju oyún ìju tó sì máa jẹ́ kí aisedeedee ara yìí “kúrò lára” pátápátá.
Ẹnì kan fi ọ̀rọ̀ yìí síta ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù keje, ọdún 2024 láti sọ̀rọ̀ nípa fídíò tí Ini Dima-Okojie, gbajúmọ̀ obìnrin osere Nollywood kan sọ fún àwọn ènìyàn pé oyún ìju tí ó ń ṣe òhun tí òhun ṣe iṣẹ́ abẹ fún ní ọdún 2020 ti padà sí ní ṣe òhun.
Nínú fídíò yìí tí ènìyàn kan fi síta lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí a mọ̀ sí X (tí wọn ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀), Dima-Okojie sọ pé òhun fi ọ̀rọ̀ yìí síta láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ìṣòro tí ó ń dojúkọ òhun àti láti gba àwọn ènìyàn tí wọ́n ní irú ìṣòro yìí níyànjú àti pé òhun mọ bí wàhálà aisedeedee ara yìí ṣe ń ṣe wọ́n.
Ó ní pé òhun kò ní kánjú ṣe iṣẹ́ abẹ mìíràn. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òhun yóò fara balẹ̀ wá ìtọ́jú tó péye láti lè dín ìju (fibroids) náà kù.
Ẹnì kan tí a mọ̀ sí @HerbalistChief lórí X dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó ní òògùn ìbílẹ̀ nìkan ló lè wo oyún ìju. Ó ní iṣẹ́ abẹ kò lè ṣiṣẹ́.
“Kò sí iṣẹ́ abẹ tó lè ṣiṣẹ́ fún ìju. Ní pàtó, lẹ́hìn iṣẹ́ abẹ, ìju yìí yóò tún padà sí ara. Òògùn ìbílẹ̀ nìkan ló lè lé aisedeedee yìí lọ pátápátá,” báyìí arákùnrin yìí ṣe wí.
Àwọn ènìyàn ti rí ọ̀rọ̀ yìí ní ìgba mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹẹdẹgbẹrin, wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ẹẹdẹgbẹrun, wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà pamọ́ ní ìgbà ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ẹẹdẹgbẹrun ló pín ín, àwọn ènìyàn ọọdunrun ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
KÍNI ÌJU?
Ìju jẹ́ ohun tí ó máa ń yọ lára tí ó ní àrùn jẹjẹrẹ tí kò lè pani lára tí ó máa ń jẹ yọ nínú ilé ọmọ àwọn obìnrin. A kò mọ àmọ̀daju tàbí ní àrídájú ìdí tí ìju fi máa ń jẹ yọ. Ìju máa ń gba ohun tí ó máa ń jẹ kí wọ́n yọ, tí ó sì máa jẹ́ kí wọ́n gbilẹ̀ láti ara ohun tí ó máa ń jẹ́ kí obinrin lè lóyún àti bímọ ni ìrọ̀rùn (estrogen).
Nípa ìdí èyí, ìju kìí sáábà máa ń ṣẹlẹ̀ kí àwọn obìnrin tó ba lágà tàbí ṣe ńnkan oṣù (menopause). Estrogen kìí fi bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn obìnrin ní Ìgbà méjèèjì yìí.
Àmọ́sá, ìju máa ń farahàn lára àwọn bíi ìdajì àwọn ènìyàn tí ó máa ń ṣe.
Gẹ́gẹ́bí Alex Ades, onímọ̀ ìlera tó mọ̀ nípa òògùn tí àwọn ènìyàn lè lò fún àwọn àrùn tó ń ṣe àwọn obìnrin tó dàgbà àti àwọn tó kéré, pàápàá òògùn fún ọmọ bíbí àti oyún níní ṣe wí, ìkan nínú àwọn obìnrin márùn-ún máa rí dọkita elétò ìlera nígbà ayé wọn nítorí pé ìju ṣe wọ́n.
Àwọn nǹkan tó maa ń jẹ́ kí a mọ bí wàhálà ìju ṣe máa pọ̀ lára ni bí ó ṣe tóbi tó àti ibi tí ó wà. Ìju lè fà kí ẹ̀jẹ̀ máa dà gidi lára obìnrin àti ìrora. Ìju kò kìí fa kí obìnrin má lè lóyún. Àmọ́, ó máa ń fa kí oyún wá lẹ̀ tàbí kí obìnrin pàdánù oyún.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
Ìkan lára àwọn ọ̀rọ̀ orí X yìí ni pé iṣẹ́ abẹ kò lè ṣiṣẹ́ fún ìju.
Ọ̀rọ̀ yìí sọ pé “lẹ́hìn iṣẹ́ abẹ, ìju tún máa padà sára ẹni tó ń ṣe.”
Fẹhintọla Akintunde, onímọ̀ ìlera tó mọ̀ nípa òògùn tí àwọn ènìyàn lè lò fún àwọn àrùn tó ń ṣe àwọn obìnrin tó dàgbà àti àwọn tó kéré, pàápàá òògùn fún ọmọ bíbí ní ilé ìwòsàn tí a mọ̀ sí Obafemi Awolowo University (OAU) Teaching Hospital sọ pé ìyàtọ̀ wà láàárín “ìtọ́jú” ati “ìwòsàn”.
Dọkita yìí ní pé ìju lè ṣeé tọju, kò lè ṣeé wòsàn. Ìdí ni pé àwọn ohun aisedeedee tí wọ́n máa ń yọ lára tí wọ́n ti yọ lára tẹ́lẹ̀ tí ìju fà nínú ilé ọmọ tún lè yọ padà, onímọ̀ ìlera yìí ló sọ bayii.
Ìtọ́jú tí àwọn elétò ìlera ń pè ní myomectomy yóò yọ ìju náà àti pé wàhálà tó ń fà fún ara yóò dá ọwọ dúró, báyìí ni Akintunde ṣe sọ fún TheCable, ìwé ìròyìn ayélujára.
“Bóyá ọ̀rọ̀ orí X yìí sọ pé ìju tún máa padà ṣe ẹni tí ó se. Níwọ̀n ìgbà tí obìnrin bá ní ìju, àwọn kòkòrò tí a kò lè fi ojú lásán rí tún máa padà yọ lára ẹni tí ó se ni bíi ọdún márùn-ún, mẹ́fà, méje, mẹwa sí ìgbà tó ṣẹlẹ̀.
“Ó tún lè padà yọ. Àmọ́, ètò ìlera lè ṣeé ṣe fún ẹni tí ó se, aisedeedee tó fà fún ara yóò sì dínkù.
AYẸWO ÒÒGÙN ÌBÍLẸ̀
Funso Abdul, olùkọ́ ati profẹsọ (ọjọgbọn) onímọ̀ ìlera tó mọ̀ nípa òògùn tí àwọn ènìyàn lè lò fún àwọn àrùn tó ń ṣe àwọn obìnrin tó dàgbà àti àwọn tó kéré, pàápàá òògùn fún ọmọ bíbí àti oyún níní ti faculty of clinical sciences, University of Ilorin sọ pé àwọn onímọ̀ ìlera sìí ń wá òògùn tó lè wo ìju sàn.
“A kò tíì mọ̀ òògùn kankan bí mo ṣe ń ba yín sọ̀rọ̀ lọ́wọ́,” Abdul ló sọ báyìí. “Mo ti jẹ́ onímọ̀ nípa ìju láti 1994, n kò sì tíì rí òògùn ìbílẹ̀ tó lè wo ìju sàn. Àmọ́, mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrànlọ́wọ́ tí iṣẹ́ abẹ lè ṣe fún ẹni tí ìju ń ṣe,” olùkọ́ yìí ló sọ báyìí.
Akintunde tún jẹ́ olùkọ́ àgbà ní department of obstetrics and gynaecology, College of Health Sciences, OAU. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òògùn ìbílẹ̀ máa dá kún aisedeedee tí ìju máa ń fà.
“Ohun tí òògùn ìbílẹ̀ máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn aisedeedee yìí pọ̀ sí.
Àwọn aisedeedee irú èyí máa di omi, wọ́n sì máa padà lè, á tún sunki. Wọn sì lè fa ìrora. Wọ́n sì tún lè dí oyún níní lọ́wọ́. “Mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí kiní yìí ń ṣe tí wọ́n ní ìrora lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n lo òògùn ìbílẹ̀. Àwọn òògùn ìbílẹ̀ yìí máa ń fa wàhálà síi ni fún àwọn tí ìju ń ṣe. Òògùn ìbílẹ̀ kò leè ṣiṣẹ́ tí òògùn òyìnbó máa ṣe,” Akintunde ló sọ báyìí.
Abdul, ẹni tí ìwádìí rẹ̀ jẹ nípa bí àwọn ènìyàn ṣe ń bímọ, àwọn nǹkan tí ọmọ oyún lè mú lára ìyá rẹ àti ìju sọ pé òògùn, iṣẹ́ abẹ àti dídá bí ẹ̀jẹ̀ ṣe máa ń lọ sí ibi ilé ọmọ níbi tí ìju wà dúró jẹ́ àwọn ọ̀nà tí àwọn onímọ̀ ìlera máa ń lò láti tọju ìju.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan sọ pé iṣẹ́ abẹ kò kìí ṣiṣẹ́ fún ìju kìí ṣe òótọ́. Àwọn ènìyàn lè tọju ìju pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ. Ìju lè padà sí ara ẹni tí ó ń ṣe. Àmọ́, eléyìí kò dá wa lójú.
Ní àfikún, a kò tíì rí àrídájú pé òògùn ìbílẹ̀ nìkan ló lè ṣiṣẹ́ fún ìju. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tíì fi ìdí èyí múlẹ̀ tàbí ríi pé òótọ́ ni.