TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ǹjẹ́ òótọ́ ni gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ ní ọjọ́ ajọyọ òmìnira?
Share
Latest News
REVEALED: The social media accounts using AI videos to amplify pro-Traore propaganda
FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?
FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?
FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria
FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?
Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027
A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba
No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ǹjẹ́ òótọ́ ni gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ ní ọjọ́ ajọyọ òmìnira?

Yemi Michael
By Yemi Michael Published October 11, 2024 12 Min Read
Share

Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, Ààrẹ Bọla Tinubu dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà lati se àjọyọ̀ lórí pé Nàìjíríà ń ṣe àjọyọ̀ ọdún mẹrinlelọgọta tí ó gba òmìnira láti se ìjọba ara rẹ̀.

Eléyìí ní ayẹyẹ òmìnira kejì tí Ààrẹ yóò ṣe láti ìgbà tí ó ti di Ààrẹ ní ọjọ́ kọkandinlọgbọn, oṣù karùn-ún, ọdún 2023.

Tinubu sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ nígbà tí ó ń ka ìfitónilétí nínú èyí tí o ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ètò ìjọba tó ti yọrí sí rere láti ìgbà tí ó ti di adarí ìjọba.

TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára se àyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ohun tí a rí nìyí.

Ọ̀RỌ̀ KÍNNÍ: Tinubu sọ pé ìjọba òun ti mú ọ̀rọ̀ ajé láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn (foreign direct investment) tí owó ẹ ju ọgbọ́n biliọnu dọ́là wá sí Nàìjíríà ní ọdún 2023 nípa àtúnṣe ọ̀rọ̀ ajé tí ìjọba òhun ń se.

“Àtúnṣe ń lọ lọ́wọ́ lórí ètò káràkátà kí nǹkan lè dáa si,” Ààrẹ ló sọ báyìí.

“Tí a kò bá ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí wọ́n bà ìlú jẹ́ tí wọ́n fa ìnira fún àwọn ènìyàn, ohun tí Nàìjíríà yóò fojú rí  yóò burú.

“A dúpẹ́ fún àtúnṣe yìí. Ó ti jẹ́ kí a le mú ọ̀rọ̀ ajé láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí ó owó rẹ̀ ju ọgbọ́n biliọnu dọ́là ní ọdún 2023 wá sí Nàìjíríà.”

AYẸWO

Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, 2024, Doris Uzoka-Anite, mínísítà fún ọrọ̀ ajé sọ pé ọrọ̀ ajé tí owó rẹ̀ ju ọgbọ́n biliọnu náírà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn orisirisi afowóṣòwò. Ó ní àwọn  afowóṣòwò yìí yóò ṣe ohun tí wọ́n sọ pé àwọn yóò se ní àárín ọdún márùn-ún sí ọdún mẹ́jọ.

Àjọ tí ó ń rí sí kíka nǹkan (National Bureau of Statistics-NBS) ṣe àtẹ̀jáde àwọn ohun tí Nàìjíríà kó wọlé láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Lára àtẹ̀jáde yìí ni iye ọrọ̀ ajé tó wá sí Nàìjíríà láti orílẹ̀-èdè mìíràn ní oṣù mẹ́ta-mẹ́ta.

Atẹjade yii pín àwọn ohun tí wọ́n ń wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn yii sí ọ̀nà mẹta, èyí tí ó jẹ́ ọrọ̀ ajé àti àwọn ohun mìíràn.

Gẹ́gẹ́bí àwọn ohun tí NBS sọ, nígbà tí ìjọba Tinubu bẹ̀rẹ̀ àti oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ ọdún 2024, ọrọ̀ ajé tó wá Nàìjíríà láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ́ irínwó ó lé eejidinlaaadọta mílíọ̀nù dọ́là ó lé díẹ̀.

Ní àsìkò kán náà, gbogbo àwọn ọrọ̀ ajé tí ó wọ Nàìjíríà láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ́ biliọnu méjì àti ẹẹdẹgbẹta ó lé ní ọgọrin miliọnu dọ́là.

Àwọn owó tí Nàìjíríà yá, eyi tí ó fi ṣòwò àti àwọn owó mìíràn tí wọ́n fi ṣe àwọn nǹkan ni àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ́ biliọnu mẹ́ta àti ọgọfa mílíọ̀nù dọ́là.

Nígbà tí TheCable Newspaper se àyẹ̀wò ṣíwájú síi, a ríi pé láàrin osù mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 2023, ọrọ̀ ajé tí owó rẹ̀ tó biliọnu mẹ́ta ó díẹ̀ dọ́là ló wọlé sí Nàìjíríà.

Owó yìí dínkù sí ẹgbẹ̀ta àti ẹrinlelaadọta mílíọ̀nù dọ́là ní àárín oṣù mẹsan àkọ́kọ́ ọdún 2023. Ó tún lọ sókè sí. Ó di biliọnu kan ó lè díẹ̀ dọ́là láti oṣù kẹsàn-án sì oṣù Kejìlá, ọdún 2023.

Àmọ́sá, ní bíi oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ ọdún 2024, àwọn owó  ọrọ̀ ajé tó wọlé láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ́ biliọnu mẹ́ta àti mílíọ̀nù irínwó ó dín ní ogún dọ́là.

Gbogbo owó ọrọ̀ ajé tó wọ Nàìjíríà jẹ́ biliọnu mẹ́fà àti ogoje mílíọ̀nù dọ́là láàárín oṣù kẹrin sí oṣù kẹfà, ọdún 2023 àti oṣù kìíní sí oṣù kẹta, ọdún 2024.

BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ 

Atẹsita tí NBS fi síta jẹ́ kó yé wa pé ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ pé ọrọ̀ ajé tí owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ́n biliọnu dọ́là ló wọlé sí Nàìjíríà láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kìí se òótọ́.

Gẹ́gẹ́bí minisita fún ọrọ̀ ajé se wí, owó ọrọ̀ ajé tí Tinubu ní ó wọ Nàìjíríà kìí se owó, ìlérí lásán ni, àwọn tí wọ́n ṣe ìlérí yìí sọ pé àwọn yóò mú ọrọ̀ ajé yìí wá láàárín ọdún márùn-ún sí mẹ́jọ.

Ọ̀RỌ̀ KEJÌ: Tinubu sọ pé nígbà tí òhun dì Ààrẹ, owó tí Nàìjíríà fi pamọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lé ní biliọnu metalelọgbọn dọ́là. Owó yìí sì ti di biliọnu mẹtadinlogoji dọ́là.

“Owó tí wọ́n fi pamọ nígbà tí mo di Ààrẹ lé ní biliọnu mẹtalelogun dọ́là, ní oṣù mẹrindinlogun sẹhin. Láti ìgbà yẹn, a ti san owó tí ó jẹ́ biliọnu méje dọ́là tí  Nàìjíríà jẹ́ sẹhin. A tún san owó kan tí ó lé ní ọgbọ́n triliọnu dọ́là,” Tinubu ló sọ báyìí.

“A ti dín gbèsè owó tí a jẹ kù sí ìdá mejidinlaadọrin. Pẹ̀lú gbogbo eléyìí, a gbìyànjú kí owó tí a fi pamọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn (foreign reserve) sì wà ní biliọnu mẹtadinlogoji dọ́là. A dẹ̀ sìí ń san owó àwọn nǹkan tí ó yẹ kí a ṣe.”

AYẸWO

Nígbà tí a wo nnkan tí banki àpapọ̀ fún Nàìjíríà (Central Bank of Nigeria-CBN) fi síta ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣù karùn-ún, ọdún 2023, ọjọ́ kẹta kí Tinubu tó bẹ̀rẹ̀ ìṣejọba gẹ́gẹ́bí Ààrẹ, a ríi pé owó tí Nàìjíríà fi pamọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ́ biliọnu marundinlogoji ó lé ní ogoje mílíọ̀nù dọ́là. Iye tí owó yìí kò fi tó iye owó tí Tinubu ní Nàìjíríà ní ní ìpamọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ́ biliọnu meji àti ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọ́là.

Àmọ́sá, ọ̀rọ̀ tí CBN fi síta ní bíi ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, ọdún 2024 jẹ́ kí ó ye wa pé owó tó wà ní ìpamọ́ yìí di biliọnu mejidinlogoji àti díẹ̀ ní owó dọ́là.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ 

Owó tí Nàìjíríà fi pamọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ti lé ní ìdá mẹ́jọ. Àmọ́, kìí se gbogbo ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ pé   biliọnu mẹtalelọgbọn dọ́là ni òhun bá ní ìpamọ́ ni òótọ́. Iye owó tí Tinubu bá nígbà tí ó di Ààrẹ jẹ́ biliọnu marundinlogoji àti ogoje mílíọ̀nù dọ́là.

Ọ̀RỌ̀ KẸTA: Tinubu sọ pé ìjọba òun ti ṣe àtúnṣe lórí owó kan tí ó tó biliọnu méje dọ́là tí ó wà lọrun Nàìjíríà, èyí tí a jẹ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

AYẸWO

Gbèsè òkèèrè tí Tinubu sọ yìí jẹ́ àwọn owó ibaraẹnise láàárín Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn (foreign exchange (FX) backlog) tí Nàìjíríà gbọ́dọ̀ se nǹkan nípa ẹ̀.

Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì, ọdún 2024, Olayemi Cardoso, ọga pátápátá ní CBN sọ pé òun bá FX backlog tí owó rẹ̀ jẹ́ biliọnu méje dọ́là nígbà tí Tinubu yan òun gẹ́gẹ́bí ọga pátápátá ní CBN ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2023.

Owó yìí fi hàn pé àwọn afowosowo àti àwọn ẹlòmíràn nílò irú owó báyìí fún àwọn nǹkan tí wọ́n ń kó wọlé láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, gbèsè tàbí àwọn ohun tí a kó  owó lé tí wọ́n lè jẹ́ kí a rí owó síi (foreign investments) tí CBN kò lè se nítorí pé owó tí Nàìjíríà lè fi ṣòwò tàbí se àwọn nǹkan mìíràn pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn (FX) kò tó nígbà yẹn.

Ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2023, Cardoso kéde pé CBN ń se akitiyan láti san owó yìí.

Ní ogunjọ, oṣù kẹta, 2024, Hakama Sidi Ali, adarí ní corporate communications ní CBN sọ pé banki àpapọ̀  tí se atunse ọ̀rọ̀ náà.

Ọjọ́ kejì lẹ́hìn tí Ali sọ ọ̀rọ̀ yìí, Kingsley Nwokeoma, olórí Association of Foreign Airlines and Representatives in Nigeria (AFARN) sọ pé kí Ali mú ẹ̀rí jáde nítorí pé AFARN kò rí ìwé ẹ̀rí owó kankan.

Àmọ́sá, ní ọjọ́ kejì, ọdún 2024, International Air Transport Association (IATA) sọ pé Nàìjíríà tí san ìdá mejidinlọgọrun owó àwọn ilé isẹ ọkọ̀ òfuurufú.

BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ

Tí a bá wo ọ̀rọ̀ tí CBN àti IATA sọ, púpọ̀ nínú ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí ni òótọ́.

Ọ̀RỌ̀ KẸRIN: Tinubu sọ pé ìjọba òun gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nàìjíríà ti san gbèsè tí owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ́n triliọnu náírà ti nǹkan tí wọ́n ń pè ní ways and means.

“A ti san owó nnkan tí a mọ̀ sí ways and means tí owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ́n triliọnu náírà,” Tinubu ló sọ báyìí.

AYẸWO 

Ways and means jẹ́ ohun tí ìjọba gbé kalẹ tí ó jẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ lè yáwó lọ́wọ́ CBN láti lè ṣe àwọn ohun kan tí wọ́n kìí se ọlọjọ gígùn. Ìwúlò owó yìí ni pé ó máa ń jẹ́ kí ìjọba rí owó fi se nǹkan tí ìjọba kò bá lówó lọ́wọ́.

Ní ọjọ́ kẹtalelogun, oṣù karùn-ún, ọdún 2023, ilé igbimọ asòfin Nàìjíríà fọwọ́ sí ohun tí wọ́n pè ní securitisation of N22.7 trillion, èyí tí ó jẹ́ owó tí ìjọba fẹ́ yá fún ways and means. Muhammadu Buhari, Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ ló béèrè fún èyí ní ọjọ́ kejidinlọgbọn, oṣù Kejìlá, ọdún 2022. Buhari ní wí pé kí wọ́n sọ owó náà di ohun tí yóò wúlò fún ìjọba tí a mọ sí government bond.

Ní ọgbọ́n ọjọ́, oṣù Kejìlá, ọdún 2023, ilé igbimọ asòfin fọwọ́ sí ohun kan tí Tinubu bèrè. Ohun níí se pẹ̀lú owó kan tí ó tó triliọnu méje àti biliọnu mẹta náírà fún gbèsè ways and means.

Biotilẹjẹpe Debt Management Office (DMO) kò tíì fi atẹjade síta lórí triliọnu méje àti biliọnu mẹta náírà yìí, ohun kan tí a rí nípa triliọnu méjìlélógún àti biliọnu méje náírà owó tí Buhari yá fi hàn pé Nàìjíríà gbọ́dọ̀ san owó yìí àti èlé orí ẹ (principal and interests) láàárín ogójì ọdún.

Lára àwọn àdéhùn gbèsè yìí ni pé Nàìjíríà kò ní í san owó kankan lórí owó yìí fún ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́.

Ara àdéhùn yìí fi ye wa pé èlé (interest) owó jẹ́ idà mẹsan owó gangan (principal) ní ọdọọdún. Èyí túmọ̀ sí pé ní ọdún kan, ijoba àpapọ̀ yóò san èlé idà mẹsan.

BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ 

Ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ pé òhun san ọgbọ́n triliọnu náírà fún ways and means kì í ṣe òótọ́. Atẹjade láti ọwọ DMO fi ye wa pé ogójì ọdún ni Nàìjíríà yóò fi san owó yìí, kìí se ẹẹkan ni Nàìjíríà yóò san owó yìí.

TAGGED: claims, Fact check in Yoruba, Independence Day speech, News in Yorùbá

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael October 11, 2024 October 11, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

REVEALED: The social media accounts using AI videos to amplify pro-Traore propaganda

Many social media accounts owned by young Africans have touted Ibrahim Traore, Burkina Faso's military…

May 17, 2025

FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?

A viral post claims, based on International Monetary Fund (IMF) projections, that Nigeria ranks fourth…

May 9, 2025

FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?

Peter Obi, Labour Party (LP) presidential candidate in the 2023 elections, sparked a debate with…

May 5, 2025

FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria

On Tuesday, some social media users and blog sites made a post claiming that a…

April 24, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027

Ní ọjọ́ ajé, ọ̀rọ̀ kan to sọ pé Goodluck Jonathan, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ sọ pé Ààrẹ Bọla Tinubu…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba

A ranar Talata ne wani rahoto da ke ikirarin cewa tsohon shugaban kasa Goodluck Jonathan ya yi hasashen nasarar Shugaba…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election

On Tuesday, one report wey claim sey former President Goodluck Jonathan predict President Bola Tinubu victory for di 2027 presidential…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027

N’ubọchị Tuesde, ozi na-ekwu na onye bụburu onye isiala Naijiria, bụ Goodluck Jonathan, gbara àmà na onyeisiala Bola Tinubu ga-emeri…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 19, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?