Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára ti sọ pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà hùwà sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, tí ó mú àdínkù bá bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe lè wọlé sí Amẹ́ríkà, gẹ́gẹ́bí Amẹ́ríkà se se sí Nàìjíríà nípa dídá àjọṣe lórí àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì láàárín àwọn méjèèjì dúró.
Dabreezy, ẹni kan tí ó ń lo Facebook fi fídíò ìṣẹ́jú mọ́kànlélógún kan síta ní ọjọ́ kejì, oṣù keje, ọdún 2025. Ẹni yìí sọ pé Nàìjíríà dí àjọṣe yìí nítorí ohun tí Amẹ́ríkà se yìí.
Àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún àti méjì ẹgbẹ̀rún ló ti wo fídíò yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọọdunrun ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn igba àti marundinlaaadọrin ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Fídíò yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n yọ láti Firstpost Africa, ilé isẹ ìròyìn kan ti ó wà ní Durban, ní orílè èdè South Africa.
Ilé isẹ ìròyìn yìí sọ pé àwọn ló kọ́kọ́ máa ń gbé ìròyìn àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní àgbáyé jáde ní Áfíríkà (Africa).
Ní ìgbà díẹ̀ àkọ́kọ́, Alyson le Grange, ẹni tí ó ń ka ìròyìn, ń ka ìròyìn kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́: “Nàìjíríà se ìkìlọ̀ pé Amẹ́ríkà ma pàdánù àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì tí wọ́n ń rí ní Áfíríkà.”
Ohùn ọkùnrin ló sọ̀rọ̀ nínú ìgbà tí ó kù nínú fídíò yìí.
Ohùn ẹni yìí dàbí ohùn tí wọn dá ọgbọ́n sí, èyí tí ó túmọ̀ sí pé wọ́n lo artificial intelligence (AI) fún ohùn yìí.
OHUN TÍ Ó YẸ KÍ Ẹ KỌ́KỌ́ MỌ̀ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YII
Ní ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹfà, ọdún 2025, Ààrẹ Donald Trump ti Amẹ́ríkà fi ọwọ́ sí ìwé àṣẹ tó sọ pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè méjìlá kò gbọ́dọ̀ wá sí Amẹ́ríkà.
Amẹ́ríkà fi àyè gba àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè méje kan láti wá sí Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n wọn kò fi àyè gbà wọ́n tán.
Lára àwọn orílẹ̀ èdè méjìlá yìí ni Afghanistan, Chad, Congo, Yemen, Eritrea, Haiti, Iran, Sudan, Myanmar, Somalia, Libya àti Equatorial Guinea.
Ọ̀rọ̀ yìí tún kan àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Burundi, Laos, Cuba, Sierra Leone, Togo, Turkmenistan àti Venezuela.
Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹfà, ọdún 2025, ọ̀rọ̀ kan tó sèsì jáde láti ọwọ́ àwọn aláṣẹ Amẹ́ríkà sọ pé Trump ń rò ó pé kí òhun má fi àyè gba àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kan àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn ní Áfíríkà láti wá sí Amẹ́ríkà.
Yusuf Tuggar, minisita ní Nàìjíríà fún àjọṣe Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn sọ pé erongba Amẹ́ríkà yìí kò dáa nítorí pé Nàìjíríà ṣe tán láti ni àjọṣe lórí àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì pẹ̀lú Amẹ́ríkà.
Ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù keje, ọdún 2025, Amẹ́ríkà kéde pé àwọn kò fàyè gba àwọn ọmọ Nàìjíríà àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè kan lati wá sí Amẹ́ríkà dáadáa mọ bíi ti tẹ́lẹ̀.
Amẹ́ríkà sọ pé bí àwọn orílẹ̀ èdè kan sese sí àwọn ló jẹ́ kí Amẹ́ríkà se báyìí. TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára sọ pé kíkọ̀ tí Nàìjíríà kọ̀ láti gbá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn tí wọ́n fẹ́ wá láti Amẹ́ríkà sí Nàìjíríà fún ààbò jẹ́ ara ohun tó fa ohun tí Amẹ́ríkà se yìí. Amẹ́ríkà sọ pé àwọn se nnkan yìí láti lè dáàbò bo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè àwọn ni.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Nàìjíríà sọ pé ohun tí Amẹ́ríkà se yìí kò dára fún àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n bá fẹ́ jẹ́ kí àjọṣe tó dára wà láàárín wọn. Nàìjíríà ní pé kí Amẹ́ríkà ro ọ̀rọ̀ yìí dáadáa.
Ẹ̀ka tó ń rí sí àjọṣe Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn (foreign affairs ministry) rọ Amẹ́ríkà láti se àtúnṣe kí àjọṣe wọn lè máa lọ déédéé. Tuggar sọ pé Nàìjíríà ń bá Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ láti mọ bí ọ̀rọ̀ yìí se rí.
Àmọ́, ó sọ pé Amẹ́ríkà fíná mọ àwọn orílẹ̀ èdè kan láti gbá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Venezuela tí orílẹ̀ èdè kan lé, ó sì fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Nàìjíríà kò ní gba àwọn ènìyàn tí kò yẹ láàyè láti gbé ní Nàìjíríà.
CableCheck kò rí ohun tí ó jọ nnkan bí ohun tí Dabreezy sọ yìí nígbà tí a se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí lórí ayélujára. Tuggar, ẹ̀ka tó ń rí sí àjọṣe Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ijọba àpapọ̀, tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ nípa ìjọba tó àwọn ènìyàn létí àti Amẹ́ríkà kò tíìì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ tí Dabreezy sọ yìí. Irú ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ohun tí àwọn orílẹ̀ èdè méjèèjì yóò fi tó àwọn ènìyàn létí tó bá jẹ́ òótọ́.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ tí Dabreezy sọ yìí kìí se òótọ́.