Vincent Olatunji, ìkan lára àwọn ọga Nigeria Data Protection Commission (NDPC) sọ pé ìmọ̀ ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ jẹ́ ara àwọn ìkan pàtàkì tó ń mú owó tó gbé pẹẹli wọlé fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ọdún 2021, owó yìí sì tó ìdá mẹrindinlogun sí ìdá méjìdínlógún gbogbo owó tí ó wọlé fún Nàìjíríà láti bíi ọdún mẹrin sí márùn-ún sẹhin.
Arákùnrin yìí sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́rú, nígbà tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ wáa lẹ́nu wò lórí ètò kan tí wọ́n ń pè ní the Prime Time Programme lórí tẹlifisọn tí a mọ̀ sí Arise Television.
“Ní ọdún mẹrin tàbí márùn-ún sẹhin, ìmọ̀ ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ jẹ́ ohun tí ó mú owó tó pọ̀ jù lọ wọlé fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, èyí tí ó wà láàárín ìdá mẹrindinlogun sí méjìdínlógún,” Olatunji ló sọ báyìí.
“Ohun tí a ń lé, ní bíi ọdún díẹ̀ sí ìgbà yìí, tí a bá ń wo triliọnu kan dọ́là ọ̀rọ̀ ajé tí Ààrẹ Bọla Tinubu fẹ́ jẹ́ kí ó máa wọlé fún Nàìjíríà, ni bí kí ohun ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sayẹnsi máa mú owó bíi idà ogún wọlé lára gbogbo owó tí ó ń wọlé fún Nàìjíríà.
“Tí àwọn adarí àwọn ohun mìíràn bá ní ètò tó dára tí wọ́n ń mú owó wọlé fún Nàìjíríà, Nàìjíríà yóò dára síi.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ THECABLE NEWSPAPER SE RÈÉ
CableCheck se àyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tí National Bureau of Statistics (NBS), ẹ̀ka ìjọba tí ó máa ń rí sí ohun tí a lè fi mọ bí ìdàgbàsókè se rí fi síta ní ọdún 2021 sí bíi oṣù keje sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024.
Ọ̀rọ̀ yìí fi ye wa pé ní ọdún 2021, iṣẹ́ àgbẹ̀/ọ̀gbìn ló mú owó wọlé fún Nàìjíríà jù. Iye owó tí iṣẹ́ yìí mú wọlé fún Nàìjíríà jẹ́ ìdá bíi mẹrindinlọgbọn gbogbo owó tí ó wọlé fún Nàìjíríà. Ìdá owó tí káràkátà mú wọlé jẹ́ ìdá bíi mẹrindinlogun, owó tí ohun ìmọ̀ ẹ̀rọ tí ó máa ń mú nnkan ṣíṣe yà mú wọlé jẹ́ ìdá mẹrindinlogun.
Ní ọdún 2022, owó tí iṣẹ́ àgbẹ̀ mú wọlé kò dín sí ìdá tó mú wọlé ní ọdún tí a mẹ́nubà lókè.
Ní ọdún 2023, isẹ àgbẹ̀ mú owó ìdá bíi marunlelogun àti díẹ̀ wọlé, ohun ìmọ̀ ẹ̀rọ mú ìdá owó bíi mẹtadinlogun àti díẹ̀ wọlé, káràkátà sì mú ìdá bíi mẹrindinlogun wọlé.
NBS kò tíì fi iye owó tí àwọn nǹkan yìí àti àwọn mìíràn mú wọlé ní ọdún 2024 síta. Àmọ́sá, a rí idà owó tí àwọn nǹkan yìí mú wọlé láàárín oṣù Kínní sí oṣù kẹta, ọdún 2024.
Láàárín oṣù kìíní sí oṣù kẹta, ọdún 2024, a ríi pé ìdá mọkanlelogun àti díẹ̀ ni owó tí iṣẹ́ àgbẹ̀ mú wọlé, iye tí ìmọ̀ ẹ̀rọ mú wọlé jẹ́ ìdá bíi méjìdínlógún, káràkátà sì mú ìdá bíi mẹrindinlogun wọlé.
Ní àárín oṣù kẹrin sí oṣù kẹfà, ọdún 2024, ìdá bíi mẹtalelogun ni iṣẹ́ àgbẹ̀ mú wọlé, ìmọ̀ ẹ̀rọ mú ìdá mọkandinlogun wọlé, káràkátà sì mú ìdá mẹrindinlogun àti díẹ̀ wọlé.
Ní àárín oṣù keje sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024, iṣẹ́ àgbẹ̀ mú ìdá mejidinlọgbọn wọlé, ohun ìmọ̀ ẹ̀rọ mú ìdá bíi mẹtadinlogun wọlé, káràkátà sì mú ìdá bíi mẹẹdogun wọlé.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Bí a bá wo àwọn ìdá owó tí a mẹ́nubà yìí, a máa ríi pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ tí ẹnì yìí sọ pé ohun ìmọ̀ ẹ̀rọ ni ó mú owó tí ìdá rẹ̀ pọ̀ jù wọlé fún Nàìjíríà léraléra ní ọdún mẹrin sẹhin.
Isẹ àgbẹ̀ ni ó mú owó tó jù wọlé fún Nàìjíríà ní àwọn ọdún tí a ṣàyẹ̀wò wọ́n yìí.