Ohanaeze Ndigbo, ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n jẹ́ ígbò, sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ju miliọnu kan àti ọọdunrun ẹgbẹ̀rún ni wọ́n wà nínú àwọn ẹ̀wọ̀n ní orílẹ̀ èdè India.
Okechukwu Isiguzoro, akọ̀wé ẹgbẹ́ yìí ló sọ báyìí nínú ọ̀rọ̀ tí ó sọ nígbà tí Nàìjíríà se ikinikaabọ fún Narendra Mordi, Ààrẹ India sí Nàìjíríà.
Isiguzoro sọ pé ẹ̀rí tó dájú wà fún ọ̀rọ̀ tí òhun sọ yìí. Ó ní iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní India ló pọ̀jù ní gbogbo àgbáyé.
“Ohun kan tí ó kọmilominu ni ipò àti ìyè àwọn ọmọ Nàìjíríà, tí wọ́n ju miliọnu kan àti ọọdunrun ẹgbẹ̀rún tí wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n káàkiri Ìpínlẹ̀ mejidinlọgbọn tó wà ní India, èyí tí iye rẹ̀ pọ̀ jù ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan ní àgbáyé,” Isiguzoro ló sọ báyìí.
Ó ní pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti India gbọ́dọ̀ wá nnkan se nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ó fi ẹ̀sùn kan àwọn olórí ìjọba India pé wọ́n kàn máa ń ti àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò hu ìwà búburú mọ ẹ̀wọ̀n àti pé ọ̀rọ̀ yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ ara àwọn ohun pàtàkì tí Ààrẹ Bọla Tinubu ti Nàìjíríà gbọ́dọ̀ bá Mordi sọ.
“A rọ Tinubu láti se ètò fún bí India yóò ṣe dárí ji àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní India, kí wọ́n sì tú wọn sílẹ̀ kí àjọṣe gidi tó wà láàárín àwa àti India lè máa lọ síwájú síi,” báyìí ni akọ̀wé yìí se wí.
Akọ̀wé yìí sọ pé òhun sọ ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà máa baà di ohun tí àwọn ènìyàn ń tẹ̀ mọ́lẹ̀.
ǸJẸ́ ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ TÍ WỌ́N JU MILIỌNU KÀN ÀTI ỌỌDUNRUN ẸGBẸ̀RÚN NI WỌ́N Ń SE Ẹ̀WỌ̀N NÍ INDIA?
Láti lè se àyẹ̀wò, TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára wo àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n wà lórí National Prisons Information Portal (NPIP) tí India fi kọmputa (computer) ṣe agbekalẹ rẹ̀, eléyìí tí ó ní í se pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀wọ̀n ní gbogbo India.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí a rí lórí ohun ẹ̀rọ ìgbàlódé yìí se wí, wákàtí mẹ́rin-mẹ́rin ni wọ́n máa ń se àtúnse ọ̀rọ̀ orí kọmputa yìí. Ọ̀rọ̀ tí a rí lórí nǹkan yìí fi iye àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n ní gbogbo ẹ̀wọ̀n India ye wa.
Ayẹwo fínnífínní tí a se fi ye wa pé àwọn Ìpínlẹ̀ marunlelogun nínú Ìpínlẹ̀ méjìdínlógún tó wà ní India ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń se ẹ̀wọ̀n.
Ní ogunjọ, oṣù kọkànlá, ọdún 2024, àyẹ̀wò tí a se fi hàn wá pé ẹẹdẹgbẹta àti mẹrindinlọgbọn àti ẹẹdẹgbẹta ó lé ní ọgọ́ta àti mẹsan ènìyàn ni wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní India. Iye àwọn ènìyàn yìí tí wọ́n jẹ́ ọmọ Nàìjíríà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ní mẹtalelọgbọn.
Ìpínlẹ̀ Manipur ní ó ní iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n se ẹ̀wọ̀n tó pọ̀ jù ní India. Iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní Manipur jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti mẹsan. Ọmọ Nàìjíríà kan ló ń se ẹ̀wọ̀n ní Ìpínlẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní Meghalaya, ọmọ Nàìjíríà kan ló ń se ẹ̀wọ̀n ní Andhra Pradesh, ìkan ló ń se ẹ̀wọ̀n ní Assam, ìkan ló ń se ẹ̀wọ̀n ní Puducherry. Iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní India ní ọdún 2015 jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún, eleyii tí ó túmọ̀ sí pé iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní India ti lé síi gẹ́gẹ́bí Ajjampur Ghanashyam, asojú India ní Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ se wí.
Iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí Isiguzoro sọ pé wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní India kéré gan-an sí iye tí a rí lórí komputa àwọn tó ń ṣètò ẹ̀wọ̀n ní India.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí Isiguzoro sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ju miliọnu kan àti ọọdunrun ni wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní India kìí se òótọ́. Ahesọ lásán-làsàn ni.
Ọ̀rọ̀ tí ìjọba India fi ye wa nípa ọ̀rọ̀ yìí sọ pé ọmọ Nàìjíríà ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ní mẹtalelọgbọn ni wọ́n ń se ẹ̀wọ̀n ní India.