Fídíò kan nínú èyí tí Ayuba Elkana, ọ̀gá Ọlọpaa ipinle Zamfara, fi ìdí rẹ múlẹ̀ pe àwọn agbébọn tí kọ lẹ́tà si àwọn ẹlẹsin Kristẹni ni Zamfara wípé kí wọn ti sọọsi pa fún oṣù mẹ́ta ti farahàn l’órí ẹ̀rọ ayélujára.
Fídíò yìí ti wà káàkiri ojú òpó ìtàkurọ̀sọ WhatsApp, ati ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Facebook pẹ̀lú Twitter.
“Ọlọpaa ti fi idi rẹ múlẹ̀ pe àwọn agbébọn kọ lẹta si àwọn sọọsi ni orílè-èdè Nàìjíríà ki wọn wa ni títìpa fún oṣù mẹ́ta,” ènìyàn kan kọ èyí sí Facebook ni ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹfà.
Ojú òpó yìí ní àwọn òntẹ̀lẹ́ bíi 112,000. Àwọn ènìyàn si ti wo fídíò náà ni ọ̀kẹ́ àìmọye ìgbà, èyí tíí ṣe 165,000, pẹlu ọ̀rọ̀ ìwòye 750. Awon ènìyàn lori ayélujára ti pín fídíò yìí ni ọ̀nà 8,200.
Ni ìgbà tí TheCable Check ṣe àyẹ̀wò awọn ọ̀rọ̀ ìwòye yìí, a ríi wipe, ọ̀pọ̀lọpọ̀ eniyan ni fídíò yìí ati ọrọ ifori rẹ ti tàn jẹ.
Iṣamudaju
Ayẹwo TheCable fi hàn pé fídíò ti o ń tàn ràn-ìn lórí ẹ̀rọ ayélujára yìí ti wa lori Youtube láti ọdún 2021.
Fídíò yii tí a gbàsílẹ̀ ní ìgbà tí Elkana n bá àwọn oníròyìn sọrọ ni ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 2021. Ninu ọ̀rọ̀ rẹ, Elkana fi ìdí rẹ̀ múlẹ pé àwọn agbébọn kọ lẹ́tà sí àwọn sọọsi ni Zamfara láti ti ilẹkùn wọn fún oṣù mẹta tabi ki wọn bọ sí ewu ìjàmbá.
“Àwọn ènìyàn aìmọ̀ kan fí lẹta yìí sì enu ònà àbáwọlé ilé iṣẹ ọlọpaa ni ìpínlẹ̀ yìí,” ọga ọlọpaa náà wii.
Ní ìgbà tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ nípa ìgbésẹ̀ ti awọn eleṣọ ààbò yóò gbé láti kí ọwọ irufin náà bọ lẹ̀, ọ̀gá ọlọpaa náà sàlàyé wípé lẹ́tà ìhàlẹ̀ yìí dárúkọ àwọn sọọsi kan ní olú-ìlú ìpínlè náà ti ìjàmbá yóò dé bá ki ọdún 2021 to parí.
TheCable bá Iliya Tsiga, tíí ṣe alága ẹgbẹ́ Christian Association of Nigeria (CAN) ní ilu Zamfara, sọ̀rọ̀, ósì fìdí rẹ̀ mulẹ pe fídíò náà tí pẹ.
“Mo tí rí fídíò náà ti e nsọ̀rọ̀ nípa rẹ. Fídíò náà ti pẹ, lati ọdún 2021 níí. Ọrọ yìí ti ní ìyanjú; ẹnikẹni tí o ba n tán fídíò náà ka, olubi ni onítọ̀ún, o si fẹ dá rògbòdìyàn silẹ ninu ilu ni,” Tsiga wí.
“Awon agbébọn yìí kọ lẹta yìí nígbà náà síi gbogbo Kristẹni ni Zamfara ni. A rọ àwọn èèyàn wá ki wọn ma ṣe kobiarasi fídíò yìí, ki wọn ṣe iṣẹ ojumọ won ni àlàáfíà.”
Àbọ̀ Ìwádìí
Fídíò náà ti pẹ, àwòrán náà ti wa lórí ayélujára lati ọdún 2021.
Irọ́ pọnbele ni ahesọ ọ̀rọ̀ pe àwọn agbébọn sọ laipẹ yìí pé ki sọọsi ni orile-ede Nàìjíríà wa ni títìpa fún oṣù mẹ́ta.