Atẹjade/ìròyìn kan lórí ayélujára tí sọ wí pé wọn yin ìbọn pá ọmokùnrin kan soso tí Nyesom Wike, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Rivers bí ní ìlú California, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Atẹjade tí àwọn ènìyàn ń pín kiri náà sọ wí pé wọn pa ọmọ náà nítorí ipa tí bàbá rẹ̀ kó nínú ìbò Ààrẹ tí a se kọjá ní ọjọ́ Àbámẹ́ta (Satide) ni Nàìjíríà.
“ìfitónilétí ìròyìn tí ó sẹsẹ ṣẹlẹ̀: wọn yínbọn pa ọmọkùnrin kan soso tí Wike bí ní California, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nítorí ipa tí bàbá rẹ̀ kó nínú ìdìbò Ìpínlẹ̀ Rivers,” báyìí ni àkòrí ìkan nínú àwọn atẹjade náà wí.
“A fi yé wa pé ọmọkùnrin kan tí a kò dámọ̀ tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún ni ó yínbọn paá nítorí ipa tí bàbá rẹ̀ kó nínú ìdìbò Ìpínlẹ̀ Rivers.
Èsì ìwádìí tí a se kò ṣeé gbára lé. Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ náà kìí se òótọ́/òtítọ́.
Ayẹwo tí ìwé ìròyìn TheCable se fi yé wa pé kò sí ìwé ìròyìn tí isẹ́ wọn dangajiya/tí ó ṣeé gbé ara lé tí ó sọ ọ̀rọ̀ tí ó ṣeé dimu nípa ọ̀rọ̀ yìí. Irọ́/ahesọ lásán-làsàn ni ọ̀rọ̀ yìí.
Àwọn tí ó gbé ìròyìn náà jáde lo àwòrán Wike pẹ̀lú ọmọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ asekagba/ìparí ẹ̀kọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń wọ (gaun giraduesọn).
Ayẹwo àwòrán náà tí a se ní orí ayélujára fi yé wa pé àwòrán náà kọ́kọ́ jáde ní orí ayélujára nínú osù keje, ọdún 2022.
Jordan Nyesom-Wike, son of the Rivers State Governor, Nyesom Wike has graduated from the University of Exeter, in the United Kingdom… pls can u see why they are not talking about ASUU strike. Well Congratulations pic.twitter.com/tFvFnmmKpQ
— Odinala Ndi IGBO (@enyinnayaibeka) July 11, 2022
Gẹ́gẹ́bí àkòrí àwòrán náà tí ìwé ìròyìn The Nation gbé jáde, wọ́n ya àwòrán náà nígbà tí Gómìnà náà àti àwọn ẹbí rẹ̀ lọ sí ibi ajọyọ ìparí ẹ̀kọ́ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ẹni tí àwọn oniroyin ofege/irọ́ ní orí ayélujára sọ wí pé wọn yinbọn pa ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Nígbà tí o sọ ọ̀rọ̀ nípa atẹjade yìí, Kelvin Ebiri, ẹni tí ó jẹ́ oluranlọwọ fún àwọn ọ̀rọ̀ orí ayélujára fún Gómìnà Wike sọ wí pé ọ̀rọ̀ yìí kìí se òtítọ́. Irọ́ ńlá gbáà ni.