Àwòrán kan tí ó se àfihàn ogunlọgọ ènìyàn tí wọn pé jọ sí ibi àpéjọ ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party ní Ìpínlẹ̀ Ọsun ń tán káàkiri orí ayélujára.
Ni Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìnlá, osù keje, ọdún yìí, ẹgbẹ́ òsèlú PDP se ìwọ́de ní Ìpínlẹ̀ Ọsun ṣáájú ètò ìbò gómìnà tí ó wáyé ni ọjọ́ àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù keje, ọdún yìí.
Abban Atiku, olùmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter), tí ó ń lo ọrọ idanimọ @abbalala3, ṣ’atunpin àwòrán náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìfòrí yìí, “Ìpínlẹ̀ Ọsun kì ń se ẹgbẹ́ yín.”
Àwòrán náà se àfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó wà ní òpópónà kan láàrín igi àti àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Àwọn olùmúlò ojú òpó náà bu ọwọ́ ìfẹ́ lùú ní ọ̀nà ọ̀run-dín-ní-okoo, wọ́n sì se àtúnpín rẹ̀ l’ọ̀nà ẹdẹgbẹta pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìwòyè/èsì Ọgọ́rùn-ún dín ní ẹgbẹ̀ta ó lé àádọ́ta àti méjì.
Osun State no be your mate. pic.twitter.com/46lQ8sdRed
— Abban Atiku (@abbalala3) July 13, 2022
Ìwádìí l’órí ojú òpó abẹ́yẹfò rẹ̀ fihàn pé olùmúlò náà jẹ́ ọmọlẹ́yìn ẹgbẹ́ òsèlú PDP.
Àwòrán tó káàkiri orí ayélujára yìí gbé àhesọ pé àpéjọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP ni Ìpínlẹ̀ Òṣun jẹ àṣeyọrí.
Àwọn olùmúlò ojú òpó náà gbóríyìn fún ẹgbẹ́ òsèlú náà fún ọgọọrọ èrò tó wà níbi àpéjọ náà.
“Inú mi a dùn gaan tí èyí bá jẹ́ ìlú Ọsun nítorí mo fẹ́ràn PDP ní ìlọ́po mẹwàá ju àwọn olè ẹgbẹ́ òsèlú APC. Bí olùdíje ẹgbẹ́ òsèlú Labor Party, ẹgbẹ́ òsèlú àwọn osisẹ kò rí ipò náà gbà, ẹ fún sẹ́nétọ̀ oníjó láàyè. Àwọn ‘Obidients’, ọmọlẹ́yìn tàbí olùfẹ́ràn Peter Obi, Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òsìsẹ́, inú wọn á dùn fún Adeleke.” Olùmúlò ojú òpó kán kọ èyí sí ojú òpó rẹ̀.
“Tikẹẹti ọ̀fẹ́ láti wo Davido, ilumọka olórin àti àwọn eléré míràn yóò wà. Báwo ní àwọn ènìyàn kò se ní péjọ? Sẹ́nétọ̀ oníjó máa fi ijó dá àwọn ènìyàn lára yá. Ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú àwọn osisẹ ni mo jẹ́, ṣùgbọ́n bí mo bá dé Ìpínlẹ̀ Ọsun ní ọla, máa lọ ṣe fàájì,” olùmúlò míràn dahùn báyìí.
Wọ́n se àtúnpín àtẹ̀jáde náà sí orí Facebook, ìkànnì ibaraẹniṣọrẹ.
Isaridaju
TheCable ṣe àyẹ̀wò àwòrán at’ẹyin wá fún àwòrán yìí pẹ̀lú Labnol, oun àmúlò ìgbàlódé láti mọ orísun àwòrán yìí àti àwọn míràn tí ó jọọ́ láti fi ìdí òdodo múlẹ̀.
A ríi wí pé wọ́n ya àwòrán yìí ní Ilọrin, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Kwara. Ahesọ ni àwòrán yìí. Ìwádìí kíkún fihàn pé wọ́n ya àwòrán yìí níbi ìrun iléyá tó wáyé ní Ìpínlẹ̀ Kwara, wọn fi àwòrán náà sí orí ayélujára ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù keje.
Àwòrán náà wà ní ojú òpó ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara lórí ìkànnì abẹ́yẹfò pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìfòrí yìí: “Àwọn olújọ́sìn ni Ilọrin ni ọjọ́ àbámẹ́ta jáde lọ̀pọ̀lọpọ̀ láti kirun iléyá pẹ̀lú Gómìnà AbdulRahman AbdulRasaq, tí ó n jẹ @RealAARahman ni orí abẹ́yẹfò, wọ́n se ètò ilẹ̀ fún àlàáfíà láti jọba ni ìlú nípasẹ̀ ibaṣepọ wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú alátakò #EidMubarak.”
Ìwádìí Ìwé Ìròyìn TheCable fi yé wa pé olùmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò kan ni ó pín oríṣiríṣi àwòrán tí a yà nígbà àdúrà iléyá tó wáyé ní ìlú Ilọrin, èyí tó tún bọ̀ fi ìdí àyẹ̀wò ìwé ìròyìn yìí múlẹ̀ pé àwòrán yìí kò wá láti àpéjọ PDP ni ìlú Ọsun.
https://twitter.com/TheWorldCamera_/status/1546220740487282690?s=20&t=1r9OOyYdTzYBW0-Oip7yVw
Kwara State Eid Prayers today ❤️ pic.twitter.com/lbUldv0RIV
— Mohammed Jammal (@whitenigerian) July 9, 2022
Àbájáde ìwádìí
Àwòrán tí ó ń sini lọ́nà ni àwòrán tí ó kálékáko yii tí ó se àfihàn ogunlọgọ ènìyàn ní ìwọ́de ẹgbẹ́ òsèlú PDP ní ìlú Ọ̀sun.