TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Rárá, Pope Leo kò bẹ Tinubu kó tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ ní àtìmọ́lé
Share
Latest News
Ókwú Badenoch nà ụ́mụ̀ yá ápụ̀ghị̀ ínwétá íkíké ị́bụ ńdị́ Naijiria bụ̀ àsị́
Kemi Badenoch claim sey her children no fit get Nigerian citizenship but she no tok true
Irọ́ ni Kemi Badenoch pa pé òfin kò fààyè gba àwọn ọmọ òhun láti di ọmọ Nàìjíríà
Maganar Kemi Badenoch na cewa ‘ya’yanta ba za su iya samun shaidar zama dan Najeriya ba karya ne
FACT CHECK: Kemi Badenoch’s claim that her children can’t get Nigerian citizenship is false
Naijiria ọ̀ kàgbùrù ńkwékọ́rị́tá àzụ́máhị́á àkụ̀ ọ̀nàtàràchí yá nà US nwèrè n’íhì ḿmáchí visa?
Ǹjẹ́ Nàìjíríà dá àjọṣe lórí àwọn àlùmọ́ọ́nì láàárín òhun àti Amẹ́ríkà dúró nítorí visa?
Nigeria stop ‘mineral deal’ with US afta visa restriction?
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Rárá, Pope Leo kò bẹ Tinubu kó tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ ní àtìmọ́lé

Yemi Michael
By Yemi Michael Published June 10, 2025 4 Min Read
Share

Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ orí ayélujára sọ pé Robert Francis Prevost, Pope Leo XIV àti àwọn bisọọbu kan bẹ Bọla Tinubu, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, pé kí ó tú Nnamdi Kanu, olórí àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ máa se ìjọba ara wọn, tí a mọ̀ sí Indigenous People of Biafra (IPOB), ní gúúsù-orun Nàìjíríà, sílẹ̀ ní àtìmọ́lé tí ìjọba àpapọ̀ fi sí.

Ọ̀rọ̀ yìí tí ẹnì kan tí ó ń jẹ́ @NgoziCommedy fi síta ní fídíò tí ó se àfihàn Ààrẹ Tinubu níbi tí ó ti ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn bisọọbu kan. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ẹẹdẹgbẹrun ló ti rí/wo fídíò yìí, àwọn ènìyàn ọgọ́ta ni wọ́n ni wọ́n fi èrò inú wọn hàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn mẹ́tàlá ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, àwọn ènìyàn mẹrindinlogun ni wọ́n pín ọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ìṣẹ́jú méjì àti ìgbà díẹ̀.

“Pope Leo XIV àti àwọn bisọọbu kan ní Rome bẹ Ààrẹ Tinubu pé kí ó tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ kí wàhálà lè lọ sílẹ̀ ni gúúsù-orun, Nàìjíríà,” báyìí ni ọ̀rọ̀ inú fídíò yìí se wí.

Ẹnì kan lórí ayélujára fi ọ̀rọ̀ tí ó jọ ọ̀rọ̀ yìí síta. Ẹni yìí sọ pé Pope Leo bẹ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà kí wọ́n tú Kanu sílẹ̀ kí wàhálà lè lọ sílẹ̀ ní Nàìjíríà àti Áfíríkà.

Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà kọ́kọ́ mú Kanu ní ọdún 2015, wọ́n sì fi ẹsùn pé ó fẹ́ gba ìjọba/da ojú ìjọba bolẹ̀ kàn án. Wọ́n fi sílẹ̀ ní ọdún 2017. Ó kúrò ní Nàìjíríà lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n fi sílẹ̀ yìí. Wọ́n tún múu/gbée ní ọdún 2021 lai sọ ìdí kan pàtó.

Ó ti wà ní àtìmọ́lé láti ìgbà tó ti pẹ. Eléyìí tí fa ẹjọ́ ni ilé ẹjọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n sì ti ń sọ pé kí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà túu sílẹ̀.

AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ 

CableCheck se àyẹ̀wò fídíò yìí ńipa lílo Google Lens, a ríi pé wọ́n ya fídíò yìí nígbà ètò ìyannisípò fún Pope Leo XIV. Ètò ìyannisípò fún Pope Leo XIV yìí wáyé ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù karùn-ún, ọdún 2025, lẹ́hìn ìgbà ikú Pope tó wà nípò kí wọ́n tó yan Pope Leo sípò. Pope tó wà nípò kí Pope Leo tó di Pope kú ní ọjọ́ kọkànlelogun, oṣù kẹrin, ọdún 2025, lẹ́hìn àìsàn ọjọ́ pipẹ.

Ààrẹ Tinubu jẹ́ ìkan nínú àwọn ènìyàn pàtàkì tí wọ́n lọ sí ibi ètò ìyannisípò yìí. Nígbà tí ètò yìí ń lọ lọ́wọ́, Tinubu se ìpàdé pẹ̀lú àwọn bisọọbu kan. Àwọn bisọọbu yìí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n lọ láti Nàìjíríà láti sojú Nàìjíríà ní Vatican.

Nínú fídíò tí àwọn ènìyàn sọ pé ó jẹ́ gidi, a gbọ ohùn àwọn bisọọbu kan, tí wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Tinubu fún jíjẹ́ tí ó jẹ́ kí wíwá àwọn bisọọbu sí Vatican ṣeése ní ìrọ̀rùn àti bí ó se wá àyè láti wá sí ibi ètò yìí.

Kò sí Pope Leo níbi tí Tinubu ti se ìpàdé pẹ̀lú àwọn bisọọbu yìí, kò sì sí ìgbà kankan tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa pé kí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà tú Kanu sílẹ̀.

CableCheck tún se àkíyèsí pé àwọn tí wọ́n fi fídíò yìí síta jẹ́ àwọn tí wọ́n ń se àtìlẹ́yìn fún Biafra. Kò sí ilé isẹ ìròyìn tí ó ṣeé gbára lé tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí.

BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ

Ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé Pope Leo XIV àti àwọn bisọọbu kan ń bẹ Tinubu kó tú Kanu sílẹ̀ ní àtìmọ́lé tí ìjọba àpapọ̀ fi sí kíi se òótọ́.

TAGGED: factcheck, Factcheck in Yorùbá, News in Yorùbá, Nnamdi Kanu, Pope Leo, Tinubu

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael June 10, 2025 June 10, 2025
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print

POPULAR POSTS

Advertisement

Ókwú Badenoch nà ụ́mụ̀ yá ápụ̀ghị̀ ínwétá íkíké ị́bụ ńdị́ Naijiria bụ̀ àsị́

Kemi Badenoch, onye ndú òtù Conservative Party nke obodo United Kingdom, ekwuola na ọ gaghị…

July 22, 2025

Kemi Badenoch claim sey her children no fit get Nigerian citizenship but she no tok true

Kemi Badenoch, leader of di United Kingdom Conservative Party, claim sey she no fit pass…

July 22, 2025

Irọ́ ni Kemi Badenoch pa pé òfin kò fààyè gba àwọn ọmọ òhun láti di ọmọ Nàìjíríà

Kemi Badenoch, arábìnrin tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òsèlú alátakò tí wọ́n ń pè ní Conservative…

July 22, 2025

Maganar Kemi Badenoch na cewa ‘ya’yanta ba za su iya samun shaidar zama dan Najeriya ba karya ne

Kemi Badenoch, shugabar jam'iyyar masu ra'ayin rikau ta Burtaniya, ta yi ikirarin cewa ba za…

July 22, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Ókwú Badenoch nà ụ́mụ̀ yá ápụ̀ghị̀ ínwétá íkíké ị́bụ ńdị́ Naijiria bụ̀ àsị́

Kemi Badenoch, onye ndú òtù Conservative Party nke obodo United Kingdom, ekwuola na ọ gaghị enyenwu ụmụ ya ikike ịbụ…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 22, 2025

Kemi Badenoch claim sey her children no fit get Nigerian citizenship but she no tok true

Kemi Badenoch, leader of di United Kingdom Conservative Party, claim sey she no fit pass her right of Nigerian citizenship…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 22, 2025

Irọ́ ni Kemi Badenoch pa pé òfin kò fààyè gba àwọn ọmọ òhun láti di ọmọ Nàìjíríà

Kemi Badenoch, arábìnrin tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òsèlú alátakò tí wọ́n ń pè ní Conservative Party ní orílẹ̀ èdè United…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 22, 2025

Maganar Kemi Badenoch na cewa ‘ya’yanta ba za su iya samun shaidar zama dan Najeriya ba karya ne

Kemi Badenoch, shugabar jam'iyyar masu ra'ayin rikau ta Burtaniya, ta yi ikirarin cewa ba za ta iya mika hakkinta na…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 22, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?