Ọ̀rọ̀ kan tí àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára sọ pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní láti ní tax identity number (TIN), nọ́mbà ìdánimọ̀ fún ọmọ Nàìjíríà tó bá ń san owó orí, láti osù kìíní, ọdún 2026, tí wọ́n bá fẹ́ jẹ́ kí ìjọba fún wọn láyè láti lo ibi tí wọ́n máa ń fi owó pamọ́ sí ní banki.
Àwọn ènìyàn ti pín ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn mìíràn sì tún ti tún ọ̀rọ̀ yìí pín lórí Instagram, ibi orí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí tí fídíò nǹkan tàbí ti ara wọn síta kí àwọn ènìyàn lè wòó/ríi, Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára, àti lórí àwọn ohun kan tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi bọ̀rọ̀ síta.
“Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, mo wà ní ilé ìfowópamọ́ (banki) nígbà tí Mama Ngozi, obìnrin kan tó ń tà tòmátì ní ọjà kan ní Ajah, wá láti gba owó,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
“Obìnrin yìí fẹ́ ra àwọn àpò (báàgì) tòmátì láti tun tà. Àmọ́ ẹnì kan tó máa ń fún àwọn ènìyàn lówó ni banki (cashier) sọ fún obìnrin yìí pé: “Ìyáàfin, láti ọjọ́ kìíní, osù kìíní, ọdún 2026, ẹ kò lè lo ibi ìfowópamọ́ yín ní banki yìí tí ẹ kò bá ní Tax Identification Number.”
Ọkàn obìnrin yìí dàrúdàpọ̀. Ó ní: “Owó orí wo? N kò ní ilé isẹ́ kankan. Tòmátì ni mò ń tà. Bí wàhálà àìlèrówóẹninọ se máa ṣẹlẹ̀ sí mílíọ̀nù àwọn ọmọ Nàìjíríà ní ọdún 2026 nìyí tí wọ́n kò bá se ohun tí ó yẹ kí wọ́n se.”
“Láti ọjọ́ kìíní, osù kìíní, ọdún 2026, ẹnikẹ́ni tí kò bá ní TIN (Tax Identification Number) kò ní lè sí tàbí ní ibi ìfowópamọ́ ní banki. Kò sí káràkátà láìsí TIN. O kò lè dunadura tàbí san owó fún nǹkan láì ní TIN. Àwọn abániṣòwò yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní bèrè TIN.”
“Bóyá ó jẹ́ obìnrin tó ń ta nǹkan ní ọjà bíi Mama Ngozi, ọmọ ilé ẹ̀kọ́, òṣìṣẹ́ ìjọba, oníjìbìtì (yahoo boy (fraudster), olówò kékeré, tàbí ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn tó ń gbé ní Nàìjíríà, tí o kò bá ní TIN, o kò ní lè nọ owó rẹ.”
Ọ̀rọ̀ yìí ti fa ìdàrúdápọ̀/ìdààmú/ìrújú fún àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí ayélujára. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà bèrè pé bóyá àwọn banki kò ní jẹ́ kí àwọn lo ibi tí wọ́n ń fowó sí ní banki tí wọ́n kò bá ní TIN láti osù kìíní, ọdún 2026.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
KÍNI TIN?
TIN jẹ́ ohun kan tó ní nọ́mbà mẹ́tàlá tí Federal Inland Revenue Service (FIRS), ẹ̀ka tó máa ń bá ìjọba àpapọ̀ gba owó orí àti owó mìíràn tí ó bá wọlé àti Joint Tax Board (JTB), ẹ̀ka ìjọba àpapọ̀ tó máa ń gba gbogbo owó orí pọ̀.
Fún ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìjọba so TIN pọ̀ mọ́ National Identification Number (NIN), nọ́mbà ìdánimọ̀ fún ọmọ Nàìjíríà kọ̀ọ̀kan. Fún àwọn oníṣòwò, wọ́n so NIN wọn mọ́ nọ́mbà tí Corporate Affairs Commission (CAC), ẹ̀ka ìjọba àpapọ̀ tó máa ń se ètò ìforúkọsílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ máa se káràkátà/ọ̀rọ̀ ajé/òwò máa ń gbà.
Ètò fún àwọn ohun tí ó yẹ kí ẹni tí ó gbọ́dọ̀ san owó orí se kì í se ohun tuntun-ètò òfin kan tí a mọ̀ sí Finance Act, 2019, tí wọ́n se àtúnṣe rẹ̀, èyí tó se àtúnṣe sí owó orí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tí owó bá ti ń wọlé fún gbọ́dọ̀ máa san ló se àgbékalẹ̀ owó orí yìí.
Nígbà tí ènìyàn kan bá sàfihàn NIN rẹ̀, fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ó bá fẹ́ sí ibi ìfowópamọ́ ní banki tàbí nígbà tí banki bá fẹ́ ṣe ìdánimọ̀ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń máa fowó pamọ́ sí banki tàbí se àjọṣepọ̀ pẹ̀lú banki (know your customers-KYC), ohun ẹ̀rọ tí banki yóò lò yóò wòó bóyá NIN ẹni yìí wà nínú ohun ìdánimọ̀ ti Nàìjíríà (national database).
Gẹ́gẹ́bí ara àyẹ̀wò yìí, banki yóò ní àǹfààní láti wá TIN ẹni yìí jáde, wọ́n sì máa fi sí inú nǹkan tí wọ́n kọ sílẹ̀ fún ẹni yìí.
KÍNI ÒFIN SỌ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YÌÍ?
Gẹ́gẹ́bí ètò ìjọba àpapọ̀ fún owó nínọ́ àti àjọ fún àtúnṣe owó orí se sọ, Nigeria Tax Administration Act (NTAA), ètò òfin fún ìṣàkóso owó orí fi òfin kalẹ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá tó tàbí tó yẹ kí o san owó orí gbọ́dọ̀ lọ gba TIN ni osu kìíní, ọdún 2026.
Àjọ tó ń se àtúnṣe fún owó orí yìí se àlàyé pé kìí se gbogbo nǹkan ni àwọn ènìyàn máa san owó orí fún ati wí pé owó orí yìí kìí se tuntun.
Wọ́n tún se àlàyé nípa àwọn tí wọ́n ń se ọ̀rọ̀ ajé/káràkátà tó yẹ kí wọ́n san owó orí.
“Àwọn banki àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń se iṣẹ́ tó nííse pẹ̀lú owó gbọ́dọ̀ bèrè ẹ̀rí pé ènìyàn san owó orí. Àwọn ènìyàn tí owó kò bá ń wọlé fún, tí wọ́n sì jẹ́ àwọn ènìyàn tí kò yẹ kí wọ́n san owó orí kò nílò TIN,” báyìí ni àlàyé tí àjọ yìí se sọ.
Àjọ yìí fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ti ní TIN tẹ́lẹ̀ kò nílò láti fi orúkọ sílẹ̀ mọ́.
“Láì sí TIN, ẹni tí ó yẹ kí o san owó orí lè má lè lo ibi ìfowópamọ́ rẹ̀ ní banki, wọn kò ní lè se àjọṣe pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ mádámidófò (insurance companies), ibi tí àwọn ènìyàn máa ń fi owó fún ìfẹ̀hìntì lẹ́nu iṣẹ́ sí, tàbí nọ owó tí ènìyàn nọ́ láti ní owó síi (investment). Ìjìyà wà lábẹ́ ètò NTAA. Àmọ́sá, ẹni tí kò yẹ kí o san owó orí kò nílò TIN.”
ÀWỌN OLÓYE SE ÌDÁNILÓJÚ FÚN ÀWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ
Nígbà tí ó se àlàyé síwájú sí nípa ọ̀rọ̀ yìí, John Nwokolo, olóye nípa owó orí sọ pé kí ènìyàn ní ibi ìfowópamọ́ ní banki kò túmọ̀ sí pé ó máa máa san owó orí.
“Kìí se gbogbo ènìyàn tí wọ́n bá ní ibi ìfowópamọ́ ní banki ló gbọ́dọ̀ san owó orí. Tí kò bá yẹ kí o san owó orí, ìjọba kò ní gba owó orí lọ́wọ́ rẹ. Síso TIN rẹ mọ́ ibi tí ó máa ń fowó sí ní banki jẹ́ ohun tí a ní láti se láti lè mọ àwọn ènìyàn tí wọ́n tó san owó orí tàbí tí wọ́n yẹ kí wọ́n san owó orí,” báyìí ni Nwokolo se wí.
“Tí kò bá yẹ kí o san owó orí nísìnyí, èyí kò túmọ̀ sí pé o kò ní san owó orí lọ́jọ́ iwájú.”
Akpe Adoh, olórí ibi tí wọ́n ti máa fi ọ̀rọ̀ tó àwọn ènìyàn létí fún JTB (head of corporate communications of JTB), nínú ọ̀rọ̀ kan láìpẹ́ yìí, tún fi ọkàn àwọn ọmọ Nàìjíríà bálẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò ní àǹfààní láti lo ibi tí wọ́n máa ń fowó pamọ́ sí ní banki àti wí pé wọn a lè se ohun tí ó nííse pẹ̀lú owó ju osù kìíní, ọdún 2026 lọ.
“JTB, èyí tí ó jẹ́ agbowó fún ìjọba àpapọ̀ jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn agbowó orí fún ìjọba ìpínlẹ̀ (36 states Internal Revenue Service), FCT IRS, ẹ̀ka ìjọba tó ń gba owó tí Federal Capital Territory (FCT), Abuja, olú ìlú Nàìjíríà bá pa/rí wọlé àti FIRS ń fọwọ́ so ọwọ́ pọ̀ láti ni ohun kan soso tí a lè fi mọ̀ pé ènìyàn jẹ́ ẹni tó lè san owó orí (National Tax Identification System,” báyìí ni Adoh se sọ.
“Ètò yìí yóò lo NIN fún ènìyàn kọ̀ọ̀kan àti nọ́mbà ìdánimọ̀, tí ìjọba fún àwọn ilé isẹ́ nígbà tí wọ́n forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba (Company Registration Number-RC) láti ṣètò owó orí gbígbà.”
“Ètò yìí yóò jẹ́ kí owó orí gbígbà àti fífún àwọn ènìyàn ní TIN rọrùn. Eléyìí sì máa jẹ́ kí ó rọrùn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà láti tẹ́lè òfin owó orí.”
“A rọ àwọn ènìyàn kí wọ́n fara balẹ̀, kí wọ́n sì má fetí sí ọ̀rọ̀ àhesọ.
“Lẹẹkan síi, àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò ní àǹfààní láti lo ibi tí wọ́n ń máa ń fi owó pamọ́ sí ní banki, wọ́n sì máa lè se ohun/àjọṣepọ̀ tó nííse pẹ̀lú owó ju ọjọ́ kìíní, osù kìíní, ọdún 2026 lọ, tí wọ́n kò bá ní TIN.”
BÍ CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò lè lo ibi ìfowópamọ́ wọn ní banki ju osù kìíní, ọdún 2026 lọ, tí wọ́n kò bá ní TIN. Pẹ̀lú NIN rẹ, o ti tẹ́lè òfin owó orí.