Ní ọjọ́ ajé, ọ̀rọ̀ kan to sọ pé Goodluck Jonathan, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ sọ pé Ààrẹ Bọla Tinubu yóò se àṣeyọrí ní ìgbà ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027 ti di ohun tí àwọn ènìyàn ti ń pín kiri lórí ayélujára.
Ọ̀rọ̀ tó lè má jẹ́ òtítọ́ yìí sọ pé ìwé ìròyìn Daily Post ló gbé ọ̀rọ̀ yìí jáde ní ọjọ́ kẹẹdogun, oṣù kẹrin, ọdún 2025. Àwọn ènìyàn ti pín ọ̀rọ̀ yìí lọpọlọpọ ìgbà lórí Facebook, oun ibaraẹnise ìgbàlódé tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń tẹ̀lée. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì tún pín ín lórí Tiktok, ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán síta. Ẹ lè rí ọ̀rọ̀ yìí kà níbí àti níbí.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Nígbà tí CableCheck, ti TheCable Newspaper, se àyẹ̀wò àwọn ìròyìn Daily Post, ìwé ìròyìn tí àwọn ènìyàn ní ó gbé ọ̀rọ̀ yìí jáde, a ríi pé ìwé ìròyìn yìí kò gbé ìròyìn báyìí jáde. Nígbà tí a tún se àyẹ̀wò orí ayélujára ti Daily Post máa ń fi iroyin tó ti pẹ sí, a kò rí ohun tí ó jọ pé Jonathan sọ ọ̀rọ̀ báyìí.
Ní àfikún, àwòrán tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ yìí lórí Facebook yàtọ̀ sí bí lẹ́tà àwọn ọ̀rọ̀ ìròyìn Daily Post ṣe máa ń rí tàbí tó, èyí tí ó túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta lórí Facebook dá ọgbọ́n lọ́nà tí kò yẹ sí ọ̀rọ̀ yìí ní.
A tún ríi pé kò sí ilé isẹ ìròyìn tí ó ṣeé gbára lé tó sọ pé Jonathan sọ irú ọ̀rọ̀ yìí.
CableCheck kàn sí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń bá Jonathan rí sí ọ̀rọ̀ ìròyìn láti lè mọ̀ bóyá òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Ikechukwu Eze, olúrànlọ́wọ́ Jonathan sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́.
Eze sọ pé kò sí ìgbà kankan tí Jonathan bá onisẹ ìròyìn kankan sọ irú ọ̀rọ̀ báyìí lórí ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ni ọdún 2027.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Jonathan kò sọ irú ọ̀rọ̀ báyìí. Irọ ni.