Ẹnì kan tó ń lo ohun ìgbàlódé ibaraẹnise orí ayélujára ti sọ pé International Criminal Court (ICC) sọ pé kí wọ́n mú Godswill Akpabio, Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ní Nàìjíríà.
Àwọn ènìyàn ogóje ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn mejilelaaadọrun ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, àwọn ènìyàn mejilelọgọta ló pín in. Ẹnì kan tí ó ń jẹ́ @VoiceUpNaija ló fi ọ̀rọ̀ yìí sórí Fesibuuku (Facebook), ohun ìgbàlódé ibaraẹnise orí ayélujára. Àwọn ènìyàn ti pín ọ̀rọ̀ yìí lórí Facebook àti LinkedIn.
“KÉRE Ó: ICC ti sọ pé kí wọ́n mú Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nítorí pé wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé ó fẹ́ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni kan lọ́nà tí kò yẹ,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se wí.
“Àwọn ènìyàn ti ní pé ICC sọ pé kí wọ́n mú Godswill Akpabio, Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ní Nàìjíríà, nígbàkigbà tí wọ́n bá ríi ní ibikíbi ní àgbáyé,” ọ̀rọ̀ yìí ló sọ báyìí.
Ọ̀rọ̀ yìí jáde lẹ́hìn èdè àìyedè tó wáyé ní àìpẹ yìí láàárín Akpabio àti Natasha Akpoti-Uduaghan, asòfin àgbà ni/ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà, tó ń sójú agbègbè àárín gbùngbùn Ìpínlẹ̀ Kogi (Kogi central senatorial district), lórí ètò ìjókòó nínú ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà.
Lẹ́hìn èdè àìyedè yìí, ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà sọ pé kí Natasha lọ sọ ti ẹnu ẹ̀ níwájú senate committee on ethics, privileges and public petitions fún ìbániwí.
Ní ọjọ́ kejidinlọgbọn, oṣù kejì, ọdún 2025, Akpoti-Uduaghan, fi ẹ̀sùn kan Akpabio pé ó fi ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lọ òhun ní ọ́fíìsì àti ilé rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.
Ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà dá Natasha dúró fún oṣù mẹ́fà ní ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹta, ọdún 2025, nítorí èdè àìyedè lórí ètò ìjókòó yìí.
Ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹta, ọdún 2025, Natasha fi ẹjọ́ Akpabio sun Inter-Parliamentary Union (IPU).
ǸJẸ́ ICC NÍ KÍ WỌ́N MÚ GODSWILL AKPABIO?
ICC jẹ́ àjọ àgbáyé tí ó ń rí sí ìwà búburú. Wọ́n dáa sílẹ̀ láti máa se ìwádìí àti láti ríi pé òfin fi ìyà jẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n bá hu ìwà tó burú sí àwọn ènìyàn ní àgbáyé (crimes against humanity).
Láti lè mọ̀ bóyá òótọ́ tàbí irọ ni ọ̀rọ̀ yìí, CableCheck se àyẹ̀wò wẹbusaiti (website) ICC láti lè mọ̀ bóyá ICC ti fi ọ̀rọ̀ yìí síta. A kò rí ohun tí ó jọ báyìí.
A tún ríi pé kò sí ilé isẹ ìròyìn tí ó ṣeé gbára lé tàbí tí ó dangajiya tó gbé tàbí fi ọ̀rọ̀ yìí síta.
CableCheck tún kàn sí Fadi El-Abdallah, agbẹnusọ fún ICC láti se ìwádìí ọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé ICC kò sọ báyìí.
El-Abdallah sọ pé ara àwọn ohun tí ICC gbọ́dọ̀ se ni pé kí wọ́n kéde ìwádìí wọn lórí àwọn ohun tí wọ́n ti máa ń fi ọ̀rọ̀ tó àwọn ènìyàn létí kí àwọn tó lè sọ pé kí wọ́n lọ mú ẹni kan.
“ICC kò sọ pé kí wọ́n mú ẹnì kankan ní Nàìjíríà, ibi tí a kò tíì kede ìdájọ́ ìwádìí, èyí tí ó jẹ́ ohun tí ó se kókó láti se kí a tó ní kí wọ́n lọ mú ẹni kan,” El-Abdallah lo fèsì báyìí sí ìwádìí tí CableCheck fi ransẹ síi.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́.