TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Rárá, fídíò yìí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú kíkọlù tí àwọn sójà kọlu Okuama láti gba ẹ̀san
Share
Latest News
FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?
FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?
FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria
FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?
Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027
A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba
No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election
Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Rárá, fídíò yìí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú kíkọlù tí àwọn sójà kọlu Okuama láti gba ẹ̀san

Yemi Michael
By Yemi Michael Published March 31, 2024 5 Min Read
Share
Screenshot

Atẹjade kan lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé (social media) sọ pé àwọn sójà (soldiers) tí kọlu Okuama, ibì kan ní ìpínlẹ̀ Delta láti gba ẹ̀san pípa tí àwọn ará agbègbè náà pa àwọn sójà mẹrindinlogun ní ìpínlẹ̀ náà.

Fídíò yìí, èyí tí àwọn ènìyàn ti pín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn sọ pé fídíò nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni.

Ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kẹta, ọdún 2024, àwọn ọ̀dọ́ ní Okuama pa sójà mẹrindinlogun kan (lieutenant colonel kan, major méjì, captain kan àti àwọn méjìlá mìíràn ). Wọ́n rán àwọn sójà yìí ní iṣẹ́ lọ sí Okuama ni lati lọ yanjú wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

Ikú àwọn sójà yìí fa wahala àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sùn káàkiri Nàìjíríà. Lára àwọn ẹ̀sùn yìí ni èyí tó sọ pé àwọn sójà yìí gba ẹ̀san nípa dídáná sun Okuama láti sọọ́ di ilẹ̀.

“Àwọn sójà ń sọ Okuama di ilẹ̀ ní àárọ̀ yìí. Àwọn òṣìṣẹ́ ológun tí múra láti kọlu agbègbè náà,” @EmekaGift100, lára àwọn tí ó ń lo X (tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀rí) ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń pín fídíò yìí. X jẹ́ ohun ìgbàlódé ibaraẹnise.

Olumulo X yìí sọ pé ajafun ẹtọ àwọn ènìyàn ni òhun, òhun sì tún jẹ́ ẹni tí ó ń tún bí a ṣe mọni sí ní àwùjọ fún àwọn ajija òmìnira tí a mọ̀ sí Indigenous People of Biafra (IPOB) ṣe. Àwọn ènìyàn sọ pé àwọn ohun tí ìjọba kò fi àyè gbà ni àwọn nǹkan tí IPOB ń ṣe.

Àwọn ènìyàn wo Atẹjade tí wọ́n fi síta yìí ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹta, ọdún 2024 ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà aadọrun àti méje ó lé igba, wọ́n pín ín ní ọ̀nà ẹẹdẹgbẹrin àti mẹ́fà, wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀na ẹẹdẹgbẹta àti ọgọ́rin ó lé ọkàn, wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ọ̀nà ọgọsan ó lé ní ìkan.

Nínú fídíò bíi ìṣẹ́jú kan yìí, eruku iná bo ọkọ̀ ojú omi lórí omi nígbà tí eruku dúdú ń fẹ́ kiri ojú òfuurufú.

“Ǹjẹ́ eléyìí dára?” arákùnrin kan ni ó bèrè ọ̀rọ̀ yìí léraléra nínú fídíò yìí nígbà tí iná náà ń jó.

“Wòó, ọ̀pọ̀lọpọ̀ epo ni ó ń jó yìí. Àwọn nǹkan tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa rèé ní ọdọọdún. Àwọn ènìyàn rò pé a máa ń gbádùn. Inú wa kò dùn.”

Gẹ́gẹ́bí @EmekaGift100 ṣe wí, àwọn sójà ni wọ́n dáná yìí láti lè jó àwọn ọmọdé, obìnrin” láàyè.

Somto Okonkwo, ẹlòmíràn tí ó ń lo X tún sọ ọ̀rọ̀ naa. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn sójà máa ń mọọmọ ṣe ohun tí kò yẹ sí àwọn ará gúúsù Nàìjíríà, wọ́n sì máa ń dá ààbò bo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní àríwá Nàìjíríà.

Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún àti mẹtalelọgbọn àti ẹgbẹ̀ta ló ti wo fídíò yìí. Àwọn ènìyàn ẹgbẹfa  ló fẹ́ràn ẹ, àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún mẹta ó dín ní mẹrindinlọgọta ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ. Àwọn ènìyàn mẹrindinlaadọọrun ló fi àmì idankanmọ sí ojú skirini ẹ̀rọ alagbeka wọn kì wọ́n lè ríi ká nígbà miran.

ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YII

TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò fídíò yìí láti lè mọ bóyá òótọ́ ni. A ríi pé àwọn ènìyàn tí fi fídíò yìí sórí Tiktok, eléyìí tí ó jẹ́ ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti ń pín àwòrán nkan láti mú inú àwọn ènìyàn dùn ní oṣù kìíní, ọdún 2024, eléyìí tí ó jẹ́ bíi oṣù méjì kí wọ́n tó pá àwọn sójà ní ìpínlẹ̀ Delta.

Nígbà tí wọ́n fi fídíò yìí síta, àwọn ènìyàn sọ pé ìjàmbá iná tí ó ṣẹlẹ̀ ní Nembe Waterside, ní Port-Harcourt, olú ìlú ìpínlẹ̀ Rivers, ni ó fà á.

“Ìjàmbá iná mìíràn ní Nembe Waterside, tí kò jìnnà sí creek road ní Port-Harcourt, tún ti ṣẹlẹ̀,” àkòrí fídíò yìí ló wí báyìí.

Fídíò yìí ní àwọn nǹkan bíi ọ̀rọ̀ abẹlẹ àti àwọn nǹkan tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀. Àwọn nǹkan yìí náà wà nínú fidio tí wọ́n fi síta lórí Twitter lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n pa àwọn sójà ní Delta.

Àyẹ̀wò tí a tún ṣe síwájú gbé ìròyìn kan jáde tí ó fi yé wa pé fídíò yìí jẹ́ fídíò ìjàmbá iná tí ó ṣẹlẹ̀ nínú oṣù kìíní, ọdún 2024, tí ó ba àwọn nǹkan kan àti àwọn dúkìá jẹ́ ní ìpínlẹ̀ Rivers.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Irọ́ ni fídíò tí ó sọ pé iná ń jó Okuama.

TAGGED: army personnel killings, Delta state, Okuama community

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael April 8, 2024 March 31, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?

A viral post claims, based on International Monetary Fund (IMF) projections, that Nigeria ranks fourth…

May 9, 2025

FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?

Peter Obi, Labour Party (LP) presidential candidate in the 2023 elections, sparked a debate with…

May 5, 2025

FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria

On Tuesday, some social media users and blog sites made a post claiming that a…

April 24, 2025

FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?

A social media user has claimed that Francis Arinze, a Roman Catholic cardinal, is the…

April 21, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027

Ní ọjọ́ ajé, ọ̀rọ̀ kan to sọ pé Goodluck Jonathan, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ sọ pé Ààrẹ Bọla Tinubu…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba

A ranar Talata ne wani rahoto da ke ikirarin cewa tsohon shugaban kasa Goodluck Jonathan ya yi hasashen nasarar Shugaba…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election

On Tuesday, one report wey claim sey former President Goodluck Jonathan predict President Bola Tinubu victory for di 2027 presidential…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027

N’ubọchị Tuesde, ozi na-ekwu na onye bụburu onye isiala Naijiria, bụ Goodluck Jonathan, gbara àmà na onyeisiala Bola Tinubu ga-emeri…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 19, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?