Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ti ń pín lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára, tí ó ṣe àfihàn ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ, sọ pé Godwin Emefiele, ọga pátápátá tẹ́lẹ̀ fún Central Bank of Nigeria (CBN), ilé ifowopamọ ti ìjọba àpapọ̀, dá triliọnu mẹrin náírà padà fún ijọba àpapọ̀.
Nínú fídíò yìí, tí ó tó ìṣẹ́jú kan àti díẹ̀, ẹni kan sọ pé ibi tí òun ti rí ọ̀rọ̀ yìí ni wọn ń pè ní “the news”
“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kàá nínú ìròyìn pé Emefiele ti dá triliọnu mẹrin padà. Owó yìí kìí se mílíọ̀nù mẹ́rin náírà, kìí se ogójì mílíọ̀nù náírà tàbí irínwó mílíọ̀nù náírà, kìí se biliọnu kan náírà, biliọnu mẹrin náírà, ogójì biliọnu naira, ẹẹdẹgbẹrun biliọnu naira, triliọnu kan tàbí triliọnu méjì naira,” báyìí ni ẹni yìí ṣe sọ. “Ẹni kan soso, gẹ́gẹ́bí Aláṣẹ pátápátá fún banki àpapọ̀ dá aduru irú owó yìí padà fún ijọba àpapọ̀, irú ẹni yìí dẹ ń lọ ilé ìjọsìn àwọn ẹlẹ́ṣin ìgbàgbọ́.” Ó bèrè bóyá wọ́n ti pín irú owó yìí fún àwọn ọmọ Nàìjíríà, ó ní pé, “ǹjẹ́ o mọ iye tí kálukú yóò gbà?”
Ẹni yìí sọ pé ìjọba “rí” owó yìí àti wí pé owó yìí kò pẹ̀lú “àwọn owó tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn.” CableCheck ríi pé ẹni kan tí a mọ̀ sí Gio Tv, tí ó ń lo Facebook ló fi fídíò yìí síta ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹfà, ọdún 2025.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹsan ló ti rí fídíò yìí, àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún kan àti méjìlá ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn mọkandinlọgbọn ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ. Àwọn kan sì sọ pé ọ̀rọ̀ yìí lè má jẹ òótọ́.
ÀWỌN OHUN TÍ Ó YẸ KÍ Ẹ KỌ́KỌ́ MỌ̀ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YII
Emefiele ń fojú ba ilé ẹjọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Lára àwọn ẹ̀sùn yìí ni pé ó fi ipò rẹ̀ kò dúkìá jọ lọ́nà tí kò bá òfin mu, wọ́n ni ó sì ń darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn owó lọ́nà tí kò yẹ.
Ní ọjọ́ kini, oṣù kọkànlá, ọdún 2025, Deinde Dipeolu, adajọ Ile ẹjọ́ federal high court, ni ìpínlẹ̀ Èkó, pàṣẹ pé kí àwọn ohun kan tí wọ́n jẹ́ ti Emefiele kan, lára àwọn tí ó jẹ́ mílíọ̀nù méjì àti díẹ̀ dọla, áwon ilẹ̀ àti àwọn ohun kan tí wọ́n jẹ́ ti Queensdorf Global Fund Limited Trust, ile isẹ ti o jẹ ti Emefiele, di ti ìjọba àpapọ̀. Wọ́n ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu ló fi kó àwọn nǹkan yìí jọ.
Àwọn ohun yìí tí ìjọba ti gbà nínú wọn ni ilé méjì tí wọ́n wà ní 17b, Hakeem Odumosu Street, Lekki Phase 1, Lagos, ilẹ̀ tí kò tíì sí nkankan lórí ẹ, tí ó wà ní Oyinkan Abayomi Drive, Ikoyi, Lagos, ilé onilẹ̀ kan tí ó wà ní 65a, Oyinkan Abayomi Drive (ti wọn ń pè tẹ́lẹ̀ ní Queens Drive), Ikoyi, Lagos, àti ilé tí ó ní yàrá mẹrin kan ní 12a, Probyn Road, Ikoyi.
Àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ní ìjọba gbà lọ́wọ́ rẹ̀ ni ibi kan tí wọ́n ń kọ ilé isẹ sórí rẹ̀. Ilẹ̀ ilé isẹ yìí jẹ pulọọti méjìlélógún, ní Agbor, ní ìpínlẹ̀ Delta, àwọn ilé mẹjọ kan tí wọ́n kò tíì parí wọn lórí pulọọti kan tó wà ní 8a, Adekunle Lawal Road, Ikoyi, àti ilé onílẹ̀ kan tí ó wà lórí pulọọti kan ní 2a, Bank Road, Ikoyi.
Àmọ́sá, ilé ẹjọ́ kotẹmilọrun (court of appeal) ní ìlú Èkó yí àṣẹ tí ó sọ pé ìjọba gbé ẹsẹ̀ lè àwọn nǹkan Emefiele yìí padà.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí nípa ṣíṣe reverse image search. A rii pé ọ̀rọ̀ yìí tí wà lórí ayélujára láti ọdún 2023.
Wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí ní oṣù kọkànlá, ọdún 2023, nígbà tí ẹnì kan tí ó ń jẹ́ @Gen_Buhar lórí X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise àlámì krọọsi, tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí Twitter, fi ọ̀rọ̀ kan síta tó sọ nípa triliọnu mẹrin tí Emefiele dá padà fún ìjọba àpapọ̀.
Ọ̀rọ̀ yìí tún jáde ní oṣù kìíní, ọdún 2024, oṣù karùn-ún, ọdún 2024, àti oṣù kẹfà, ọdún 2024.
CableCheck tún se àyẹ̀wò àwọn ìròyìn ilé ẹjọ́ tí àwọn ilé isẹ ìròyìn tí wọ́n ṣeé gbára lé fi síta, a ríi pé àwọn ilé isẹ ìròyìn yìí kò sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ owó tí ẹni yìí ní Emefiele dá padà.
A tún ṣe ayẹwo ọ̀rọ̀ yìí lórí Google, a sì tún ríi pé ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe òótọ́.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́.