Àwọn ènìyàn ti ń pín àwòrán kan kiri lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise orí ayélujára, tí ó se àfihàn Peter Obi, Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party (LP), ní ọdún 2023, níbi tí ó ti kúnlẹ̀ láti kí Bọla Tinubu, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń lo ohun ìgbàlódé ibaraẹnise yìí sọ pé Obi kúnlẹ̀ láti kí Tinubu nígbà tí wọ́n ń se ètò lati fi Pope Leo XIV, olórí ni gbogbo àgbáyé fún àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì (catholic church adherents) ní Rome, olú ìlú orílẹ̀ èdè Italy.
Ní ogunjọ, oṣù karùn-ún, ọdún 2025, Atu Lazarus, ẹni kan tó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ lórí ayélujára, fi aworan yìí síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé “Peter Obi ṣe ohun tí mo fẹ́ràn. Ó kúnlẹ̀ fún bàbá mi. Kó gba ti Tinubu. Kó so ọwọ pọ̀ pẹ̀lú Tinubu láti tún Nàìjíríà ṣe.”
Ẹni kan tí ó ń jẹ́ Pankwaye Bulus Kanam tí ohun náà ń lo Facebook, fi àwòrán yìí síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “Peter Obi kúnlẹ̀ síwájú Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ní àjọ ìjọsìn ti Vatican. Obi yìí kan náà ló ń pariwo, tó sì í ń tiraka láti kó àwọn ẹgbẹ́ alátakò jọ láti yọ Tinubu kúrò ní ipò Ààrẹ.”
Ẹ lè rí àwòrán yìí wò níbí, níbí àti níbí.
OHUN TÍ Ó YẸ KÍ Ẹ KỌ́KỌ́ MỌ̀ KÍ Ọ̀RỌ̀ ÌKÚNLẸ̀ YÌÍ TÓ WÁYÉ
Ètò yíyan Pope Leo XIV (Pope kẹrìnlá) wáyé ní Saint Peter’s Square, ní Vatican City, ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2025.
Àwọn tí wọ́n wà nípò àti yàn Pope sí ipò gẹ́gẹ́bí olórí ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ ti àwọn Catholic yàn án sípò Pope, ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù karùn-ún, ọdún 2025, lẹ́hìn ìgbà tí Pope kẹtàlá kú. Tinubu àti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórí ní àgbáyé ni wọ́n wà níbi tí wọ́n ti se ètò ìyannisípò fún Pope Leo yìí.
Nígbà ètò ìsìn fún ìyannisípò fún Pope Leo, Tinubu kí Káyọ̀dé Fayemi, gómìnà tẹ́lẹ̀ fún Ìpínlẹ̀ Èkìtì àti Obi, àwọn méjèèjì jẹ́ ẹlẹ́sìn Catholic pọnbele. Bayo Onanuga, ẹni tí ó máa ń gba Tinubu ní àmọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ìjọba fi tó àwọn ọmọ Nàìjíríà létí àti ètò, fi ọ̀rọ̀ kan síta, ó sì se àlàyé bí Tinubu se bá Obi àti Fayẹmi sọ̀rọ̀ níbi ètò ìyannisípò náà.
Onanuga sọ pé Fayẹmi rí Tinubu níbi tí ó jókòó sí, ó sì sọ fún Obi kó tẹ̀lé ohun láti lọ bọ̀wọ̀ fún Tinubu.
“Nígbà tí Fayẹmi àti Obi dé ibi tí Tinubu wà, Fayẹmi sọ pé: “Ààrẹ, ẹ kaabọ sí ìjọ wá, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún yiyẹ Pope sí nípa wíwá sí ibi ètò yìí.”
Tinubu dáhùn, ó sọ pé: “Èmi ni ó yẹ kí n kí ìwọ Fayẹmi àti Obi kaabọ. Èmi ni olórí àwọn tó wá ṣojú àwọn ènìyàn láti Nàìjíríà.” Èsì Tinubu pa Obi ní ẹ̀rín, Obi sì gbà pè lóòótọ́ ni nnkan tí Tinubu sọ,” báyìí ni ọ̀rọ̀ tí Onanuga fi síta lórí X (formerly Twitter), ohun ìgbàlódé ibaraẹnise alámì krọọsi se wí.
Onanuga tún fi àwòrán bí Tinubu se kí Obi àti Fayẹmi níbi ètò ìyannisípò náà sórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise orí ayélujára (social media). Obi fi ọ̀rọ̀ tó sọ pé òhun kí Tinubu àti Fayẹmi níbi ètò ìyannisípò yìí síta lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise. Àwòrán àti fídíò àwọn olórí ẹ̀sìn àti ìjọba ni àgbáyé tí wọ́n wà ní ibi ètò náà jáde ní orí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media) lórí ayélujára (the internet). Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí níí se àríyànjiyàn nípa bí ipò Tinubu àti Obi se tó ní àgbáyé. Àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti jáde káàkiri orí àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise orí ayélujára.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Nígbà tí CableCheck se àyẹ̀wò àwòrán yìí, a ríi pé àwọn ènìyàn dá ọgbọ́n síi ní láti lè jẹ́ kí ó rí bí ó se rí. Wọn gbé àwọn àwòrán yìí lórí ara wọn ni.
Nínú àwòrán yìí, Ọwọ́ (hands) Obi níbi tí wọ́n ní ó ti kúnlẹ̀ yìí kò dà bí Ọwọ́ gidi. Ọwọ́ yìí dàbí Ọwọ́ tí wọ́n dá ọgbọ́n sí láti gbé lórí nǹkan.
Ayẹwo tí a tún se síi fi yé wa pé Olusegun Dada, oluranlọwọ lórí ọ̀rọ̀ ohun ìgbàlódé ibaraẹnise fún Tinubu (special assistant to Tinubu on social media) fi àwòrán yìí to jẹ́ gidi síta lórí X, ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2025. Nínú àwòrán tí Dada fi síta yìí, Tinubu dá jókòó níwájú níbi ètò ìyannisípò yìí nígbà tí Fayẹmi àti Obi ń bọ̀ lẹ́hìn láti rí Tinubu.
Ọ̀rọ̀ kan tí Valentine Obienyem, ẹni tí ó máa ń gba Obi ni àmọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn fi sita sọ pé wọn dá ọgbọ́n sí àwòrán yìí ni kí ó ba lè rí bí ó se rí.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Àwòrán tó ṣe àfihàn Obi níbi tí ó ti kúnlẹ̀ sí iwájú Tinubu kìí se àwòrán ohùn tó jẹ́ òótọ́.