Ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ní George Weah, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Liberia sọ ni àwọn ènìyàn ti se atunpin rẹ̀ lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise.
Lára àwọn atẹsita náà lórí ohun ibaraẹnise ẹlẹyẹ (twitter, now called X), ọ̀rọ̀ náà wà nínú ohun kan tí wọ́n yà tí ó ní àwòrán Ààrẹ náà ní abẹlẹ.
“Ǹjẹ́ òótọ́ ni pé Ààrẹ George Weah sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí @OfficialABAT (Asiwaju Bola Ahmed Tinubu)? Mo fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí”, báyìí ni àkòrí ọ̀rọ̀ yìí ṣe wí.
Àwọn ènìyàn ti wo àwòrán náà ní ọ̀nà ẹgbẹrin mẹrindinlọgọta láti ọjọ́ kẹta, oṣù kẹjọ tí wọ́n ti fi sórí àwọn ohun ibaraẹnise.
Is this true @officialABAT was slammed by Liberian President 🤣😂😂
I love this quote
Augmentin | RCCG | Transcorp Hilton Hotel | David Hundeyin | GOLIATH HAS FALLEN | Niger pic.twitter.com/VFtLyw99mb
— Work ethics (@workethicsng) August 3, 2023
“As long as ECOWAS tolerates institutional coups that allow lifetime presidencies, there will always be military coups.
And we cannot condemn military coups when we do not condemn those who carry out institutional coups."~George Weah.
The President of Liberia 🇱🇷 pic.twitter.com/jusGWQIENZ
— Charly Boy Area Fada 1 (@AreaFada1) August 4, 2023
“Níwọ̀n ìgbà tí ẸKOWAASI (Economic Community of West African States) fi ara mọ́ ifipagba ìjọba tí ènìyàn kan fi lè ṣe Ààrẹ títí di ìgbà tí yóò fi kú, ifipagba ìjọba yóò máa ṣẹlẹ̀”, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Weah sọ nìyí.
IFIPAGBA ÌJỌBA TÍ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ OLÓGUN ṢE NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NIJE
Ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, ọdún 2023, àwọn òṣìṣẹ́ ológun orílẹ̀-èdè Nije fipá yọ Mohamed Bazoum, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nije kúrò ní ipò Ààrẹ. Wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé. Orúkọ asiwaju àwọn tí ó ṣe nkan yìí ni Abdourahamane Tchiani.
Wákàtí díẹ̀ lẹ́hìn ifipagba ìjọba yìí, Amadou Abdramane, agbẹnusọ àwọn òṣìṣẹ́ ológun ní Nije kéde pé “àwọn òṣìṣẹ́ alaabo ti fi òpin sí ìjọba tí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa rẹ̀.”
Ọjọ́ méjì lẹhin èyí, Tchiani sọ pé ohùn ni Ààrẹ báyìí fún àwọn tí ó pè ní the National Council for the Safeguard of the Homeland (CNSP).
Nije, orílẹ̀-èdè tí ó ní uranium, godi (gold) gba òmìnira ní ọjọ́ kẹta, oṣù kẹjọ, ọdún 1960 ní ọwọ́ orílẹ̀-èdè Faransé (France).
Láti ìgbà yìí, ifipagba ìjọba márùn-ún ló ti ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Èyí tí kò pẹ́ lára ifipagba ìjọba yìí ló ṣẹlẹ̀ ní oṣù keje, ọdún 2023.
Ifipagba ìjọba àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1974. Àwọn yòókù ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1996, 1999 àti 2010.
Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó sún mọ́ Nije ni Mali, Burkina Faso àti Guinea tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẸKOWAASI. Àwọn ológun ni wọ́n ń ṣe ìjọba ni àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí lọ́wọ́lọ́wọ́.
Ní ọgbọ́n ọjọ́, oṣù keje, ní ìdáhùn sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Bọla Tinubu, Ààrẹ Nàìjíríà, ẹni tí ó tún jẹ́ alága ẸKOWAASI pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẸKOWAASI ṣe ìpàdé ní Abuja, olú ìlú Nàìjíríà. Kókó ìpàdé náà ni bí wọ́n yóò ṣe yanjú rògbòdìyàn tí ifipagba ìjọba fà ní Nije.
Lẹ́hìn ìpàdé náà, ẸKOWAASI fún àwọn òṣìṣẹ́ ológun tí wọ́n fi ipá gba ìjọba ni Nije ní ọjọ́ méje láti dá Bazoum sí ipò rẹ̀, kí wọ́n sì gbé ìjọba fún àwọn tí ará ìlú dìbò yàn tàbí kí wọ́n kabamọ.
Láfikún, ní ọgbọ́n ọjọ́, oṣù keje, ẹgbẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè adúláwọ̀/Áfíríkà (African Union-AU) sọ fún àwọn olórí ológun kí wọ́n dá Bazoum padà sí ipò Ààrẹ láàárín ọjọ́ mẹẹdogun.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀sẹ̀ kan tí ẸKOWAASI fún àwọn afipagba ìjọba yìí, Abdramane sọ pé “a fẹ́ rán ẸKOWAASI tàbí ẹnikẹ́ni létí pé mìmì kan kò lè mi ìlérí wa láti dá ààbò bo ilẹ̀ wa.”
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Weah, ẹni tí ó jẹ́ agbabọọlu tẹ́lẹ̀rí ní ìdáhùn sí nkan tí ẸKOWAASI fẹ́ ṣe ní Nije sọ pé “A kò lè sọ pé ifipagba ìjọba kò dára nígbà tí a kò sọ wí pé àwọn tí wọ́n sọ ìjọba di nibinimakusi, oyè ìdílé kò ṣe dáadáa.”
Ǹjẹ́ Weah sọ báyìí? Níbo ló ti sọ?
ÀBÁJÁDE ÀYẸ̀WÒ WA RÈÉ
Agbeyẹwo wa fi yé wa pé biotilẹjẹpe ọ̀rọ̀ yìí ti ń tàn rànyìn lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise láti oṣù kẹjọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti ìròyìn kò sọ ìgbà tàbí ibi tí Weah ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
Ayẹwo tí a tún ṣe sí jẹ́ kí a rí atẹjade kan tí ìwé ìròyìn Sierra Leone Telegraph gbé tí ó ní àkọ́lé: “Àwọn olórí orílẹ̀-èdè ẸKOWAASI dá ìjọba Guinea dúró. Wọ́n sì dá àwọn afipagba ìjọba lẹ́bi nípa ààbò Conde.”
He made the statement 2021, it’s still valid.
— Bethel Anunihu (@Bethel_Anun) August 4, 2023
Wọ́n gbé ìròyìn yìí jáde ní ọjọ́ Kẹwa, oṣù kẹsàn-án, Ọdún 2021. Ọ̀rọ̀ yìí sì jọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Weah sọ yìí nígbà ìpàdé onifidio tí àwọn olórí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẸKOWAASI ṣe.
Ìjíròrò níbi ìpàdé náà dá lórí ifipagba ìjọba tí wọ́n fi yọ Alpha Conde, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Guinea, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹtalelọgọrin nígbà tí ifipagba ìjọba yìí ṣẹlẹ̀.
Nígbà ìpàdé yìí, Weah sọ pé ifipagba ìjọba ní Guinea wá yé nítorí pé Conde fẹ́ yí ìwé òfin iselu láti lè ṣe ìjọba ẹkẹta.
“Biotilẹjẹpe a kò fẹ́ràn ìwà yìí, a gbọ́dọ̀ wo ohun tí ó fa àwọn ifipagba ìjọba yìí. Ṣé kìí se pé a kò tẹ́lẹ̀ ìlànà ìjọba tí ó ṣe agbekalẹ iye ìgbà tí ènìyàn gbọ́dọ̀ lò lórí ìjọba ni? Weah ló sọ bayii fún àwọn olórí orílẹ̀-èdè Áfíríkà ní ọdún 2021.
Biotilẹjẹpe ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Weah sọ kìí ṣe ohun tí ó sọ ní ìpàdé ẸKOWAASI ní ọdún méjì sẹhin, ohun kan náà ni ó fẹ́ jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀.
Ledgerhood Renni, minisita fún ifiọrọtonileti sọ fún TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Weah sọ yìí nípa ifipagba ìjọba ní Nije kìí se òtítọ́.
Ní ọjọ́ kejìdínlọgbọn, oṣù keje, ọdún 2023, ìjọba Liberia sọ pé ifipagba ìjọba ní Nije kò dára.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Weah sọ pé òun fi ara mọ́ ifipagba ìjọba ní Nije kìí se òótọ́. Irọ́ gbáà ni.