Ní ọjọ́ ìsinmi, Politics Nigeria, wẹbusaiti kan fi fídíò tí kò pé ìṣẹ́jú kan síta lórí Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára, ó sì sọ pé Ààrẹ Tinubu sọ pé “ẹ̀rù kankan kò bà wá lórí ohunkóhun tí Trump bá ń se.”
Àwọn ènìyàn igba ló ti sọ̀rọ̀ nípa fídíò yìí, àwọn ènìyàn ọtalelẹgbẹta ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn marundinlọgọrun ló tún ọ̀rọ̀ yìí pín.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń lo Facebook tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí sọ pé ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Donald Trump ti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sọ nípa àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n ń pa ní Nàìjíríà ló jẹ́ kí Tinubu sọ ọ̀rọ̀ yìí.
“Ẹ jọ̀wọ́, ń jẹ́ ẹnì kan lè fi orúkọ Trump sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí tàbí kí n fi orúkọ mi sínú ọ̀rọ̀ yìí,” báyìí ni ẹni kan tó ń lo Facebook se sọ.
“Ara èyí tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gan ń gbọ̀n nítorí pé ó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ara ló máa sọ fún un,” ẹlòmíràn tó ń lo Facebook ló sọ báyìí.
“Ẹ̀rù kò bà yín, ẹ̀rù ń ba èmi nítorí pé mo mọ ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà lè se tó bá di ọ̀rọ̀ ogun,” ẹlòmíràn kan tí ó ń lo Facebook ló sọ báyìí.
Ní ọjọ́ ẹtí tó kọjá, Donald Trump, Ààrẹ Amẹ́ríkà sọ pé Nàìjíríà jẹ́ “orílẹ̀ èdè tí ìse wọn ń kọ ènìyàn lóminú” (Country of Particular Concern (CPC)” nítorí àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n ń pa ní Nàìjíríà.
Trump kìlọ̀ fún ìjọba Nàìjíríà kí wọ́n “gbé ìgbésẹ̀ kíákíá”, ó ní pé ohun yóò dá ìrànlọ́wọ́ tí Amẹ́ríkà máa ń se fún Nàìjíríà dúró.
Lẹ́hìn èyí, Trump halẹ̀ pé òhun yóò rán àwọn òṣìṣẹ́ ológun sí Nàìjíríà láti dojú ìjà kọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ‘kọlu àwọn onígbàgbọ́.”
Ọ̀rọ̀ Trump yìí jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, pàápàá jù lọ lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tí Trump bá rán àwọn òṣìṣẹ́ ológun sí Nàìjíríà.
Ní ọjọ́ kejì, osù kọkànlá, ọdún 2025, Daniel Bwala, oluranlọwọ fun Tinubu tí ó máa ń fi ọ̀rọ̀ tó àwọn ènìyàn létí sọ pé Tinubu àti Trump yóò se ìpàdé “ní àìpẹ́ yìí” láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní wọ́n ń pa ní Nàìjíríà.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Wọ́n kọ “Viable TV” sórí ọ̀rọ̀ yìí tí Politics Nigeria fi síta. Viable Tv máa ń fi àwọn fídíò ìṣẹ́jú díẹ̀díẹ̀ sórí YouTube, ibi kan lórí ayélujára tí áwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta.
Nígbà tí Cablecheck ṣàyẹ̀wò ibi tí Viable Tv máa ń fi àwòrán tàbí fídíò si lórí YouTube, a ríi pé ọjọ́ kejì, osù kẹsàn-án, ọdún 2025 ni wọ́n fi fídíò yìí síta.
Àwọn ìròyìn fi yé wa pé wọ́n se fídíò yìí nígbà tí Tinubu gba àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń pè ní The Buhari Organisation (TBO), tí Tanko Almakura, gómìnà ìpínlẹ̀ Nasarawa tẹ́lẹ̀ se asiwaju wọn ní àlejò ní ibùgbé Ààrẹ Tinubu ní Abuja ní ọjọ́ kejì, osù kẹsàn-án, ọdún 2025.
Nígbà ìpàdé yìí, Tinubu sọ pé ìjọba Nàìjíríà ti se áwọn ohun tí ó yẹ kí o ṣe láti fi ẹsẹ̀ Nàìjíríà múlẹ̀, ó sì sọ pé àwọn ohun tí Trump bá se kó sì lè mi Nàìjíríà.
“A ti rí ìyè owó tí a ní láti rí ní osù kẹjọ, ọdún 2025. A kò bẹ̀rù fún nǹkankan tí epo rọ̀bì kò bá mú owó wọlé, ohunkóhun tí Trump bá se kò bà wá lẹ́rù,” báyìí ni Tinubu se sọ.
Tinubu sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí Organisation of Petroleum Exporting Countries (OPEC) pinnu pé àwọn yóò fún àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ OPEC láyé sii láti se epo rọ̀bì láti lè dín owó tí wọ́n ń ta epo rọ̀bì kù ní àgbáyé.
Trump tún fi owó orí lé àwọn káràkátà ni agbaye, owó orí yìí sì kan àwọn ohun tí Nàìjíríà ń kó lọ sí Amẹ́ríkà láti tà. Tinubu sọ ọ̀rọ̀ yii lórí ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà ni.
Àwọn ilé iṣẹ́ amohunmaworan tí a mọ̀ sí Arise Television àti Channels Television gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ Tinubu yìí jáde.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Fídíò yìí kì í se fídíò ọ̀rọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ, kìí sì se ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ lórí àwọn orílẹ̀ èdè tí Amẹ́ríkà ń sọ.