Atẹjade kan lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé (social media) sọ pé àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọn jẹ́ insipẹkitọ (inspector) ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ń fi ẹhọnu hàn nítorí owó oṣù mọ́kànlá tí ìjọba jẹ wọ́n.
Ọ̀rọ̀ yìí, tí ẹnì kan fi sí orí X (ohun ìgbàlódé ibaraẹnise alámì krọọsi) tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀ ní àwòrán tí ó se àfihàn àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n gbé àwọn nǹkan tí wọ́n kọ nǹkan bíi “ÀWỌN KAN TI KÚ” sí dání.
Àwọn ènìyàn ti pín àwòrán yìí lórí orisirisi ohun ìgbàlódé ibaraẹnise bíi fesibuuku (facebook), èyí tí ó jẹ ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ. Àwọn ènìyàn fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí nígbà ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí gẹ́gẹ́bi ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó nínú ọ̀rọ̀ mìíràn ní ọ̀na mẹrinlelaadọta, wọ́n pín ín ní ọ̀nà ẹgbẹ̀ta àti méjìlelọgọta. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọ̀nà igbá àti mejidinlogoji.
Àwọn ènìyàn fi ọ̀rọ̀ yìí síta lẹ́hìn ọjọ́ díẹ̀ tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fi ẹhọnu hàn, èyí tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní #EndBadGovernance ní Nàìjíríà. Ìròyìn sọ pé Ifiẹhọnuhan yìí fa ìbanǹkanjẹ́. Ìròyìn yìí sọ pé àwọn ọlọ́pàá lo tajútajú láti lè lé àwọn tó ń fi ẹhọnu hàn yìí.
“NǸKAN TÍ WỌ́N Ń PÈ NÍ ÌGBÀ YÍYÍ KÀN!! ÌLÚ LE, ÀWỌN NǸKAN WỌ́N GÓGÓ, èyí ń mú ara ni àwọn ènìyàn-Àwọn ọlọ́pàá ń fi ẹhọnu hàn nítorí pé ìjọba kò san owó oṣù mọ́kànlá fún wọ́n,” báyìí ni ara àtẹ̀síta yìí ṣe wí.
“Àwọn ọlọ́pàá kan tí wọ́n pe ara wọn ní Concerned Police Inspectors in Nigeria (CPIN) fi ẹhọnu hàn láì fa wàhálà ní Uyo, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom nítorí pé ìjọba kò san owó oṣù mọ́kànlá fún wọ́n.
“Àwọn ọlọ́pàá yìí tí ìjọba gbé ga láti ipò insipẹkitọ kejì sí insipẹkitọ Kínní tó ẹgbẹ̀rún kan àti ẹẹdẹgbẹta láti oríṣirísi ibi ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.
“Wọ́n ké pe Káyọ̀dé Ẹgbẹ́tókun, ọga pátápátá fún àwọn ọlọ́pàá tí a mọ sí inspector-general of police (IGP) ní èdè òyìnbó kí ó dá sí ọ̀rọ̀ yìí, kí ó sì bá wọn ṣe kí wọ́n rí owó tí ìjọba jẹ wọ́n gbà kí wọ́n lè rí owó fi jẹun.”
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
Láti ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára lo Google reverse image search, a ríi pé àwọn ènìyàn ti kọkọ rí àwòrán yìí ní orí ayélujára ní ọjọ́ keje, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2022 nígbà tí àwọn ọlọ́pàá tí ipò wọn kéré fi ẹhọnu hàn ní Osogbo, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun nítorí pé ìjọba jẹ wọ́n ní owó oṣù méjìdínlógún.
Ní àfikún, kò sí ilé iṣẹ́ tí ó ń gbé ìròyìn jáde kankan tí ó sọ ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
TheCable ṣe àkíyèsí pé ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ yìí síta jẹ́ ìkan lára àwọn alátilẹ́yìn àwọn tí a mọ̀ sí Indigenous People of Biafra (IPOB).
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, Olumuyiwa Adejọbi, agbẹnusọ fún àwọn ọlọ́pàá sọ pé “ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́, wọ́n fẹ́ fi ba àwọn ọlọ́pàá lórúkọ jẹ́ ní.”
Ó sọ pé àwọn adarí ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá kò fi ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá ṣeré. Ó ní wọ́n ń sapá láti jẹ́ kí ayé wọ́n lè dára si. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n lọ fi ọ̀rọ̀ yìí sun àwọn tó ń rí sí irú ọ̀rọ̀ yìí.
Ó ṣàlàyé pé ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí owó ninọ ló máa ń san owó àwọn ọlọ́pàá. Ó ní wọ́n máa ń lo Integrated Personnel Payroll System (IPPIS) láti san owó wọ́n. Ó ní kìí se IGP tàbí àwọn àjọ ọlọ́pàá (Nigeria Police Force-NPF) ló ń ṣàn owó wọ́n.
“Àjọ àwọn ọlọ́pàá ti sọ pé ọ̀rọ̀ rádaràda ni ọ̀rọ̀ tí àwọn onisẹ ìròyìn kan fi síta. Wọ́n ní àwọn insipẹkitọ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ní Uyo láti fi ẹhọnu hàn nítorí pé ìjọba kò san owó tí wọ́n fi lé owó oṣù àwọn ọlọ́pàá fún ìgbà kan. Àwọn àjọ ọlọ́pàá náà ní pé ìwà tí kò dára ni. Wọ́n ni wọ́n fẹ́ fi ọ̀rọ̀ yìí ba àwọn ọlọ́pàá lórúkọ jẹ́ ní,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe wí.
Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá yìí tún sọ pé “Láfikún, ó yé wa yékéyéké pé ọga ọlọ́pàá pátápátá àti Nigeria Police Force kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú owó oṣù àwọn ọlọ́pàá, ẹ̀ka ìjọba lábẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń rí sí ètò owó ninọ ló máa ń lo Integrated Personnel Payroll System (IPPIS) láti san owó oṣù.
“Ọga ọlọ́pàá pàtápàtá rọ àwọn tí ọ̀rọ̀ yìí kàn kí wọ́n bá àwọn tí wọ́n ń ṣàkóso ọ̀rọ̀ yìí sọ̀rọ̀ ní agbègbè wọ́n, èyí tí kò nii jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ àwọn ọlọ́pàá jẹ́.”
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan sọ pé àwọn insipẹkitọ ọlọ́pàá ń fi ẹhọnu hàn nítorí pé ìjọba jẹ wọ́n ní owó oṣù méjìdínlógún kì í ṣe òótọ́. Irọ gbáà ni.
Àwòrán tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ àwòrán àwọn ọlọ́pàá tó ń fi ẹhọnu hàn ní Ìpínlẹ̀ Ọsun ní ọdún 2022.