Ní ọjọ́ ajé, ilé ìgbìmọ̀ asòfin méjèèjì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ ìwé ìjíròrò lórí iye owó tí ó kéré jù tí àwọn agbanisisẹ gbọ́dọ̀ san fún òṣìṣẹ́ di òfin.
Ìgbà mẹ́ta ni àwọn asòfin máa ń jíròrò lórí ìwé tó lè di òfin. Wọ́n bu ọwọ́ lu ìwé yìí láti sọ di òfin láàárín wákàtí kan.
Òfin yìí mú àyípadà bá nǹkan pàtàkì méjì nínú òfin tí a mọ̀ sí National Minimum Wage Act, 2019, ó jẹ́ kí ọgbọ̀n ẹgbẹ̀rún náírà, èyí tí ó jẹ́ owó oṣù tó kéré jù tẹ́lẹ̀ tí àwọn agbanisisẹ gbọ́dọ̀ san fún òṣìṣẹ́ di ẹgbẹ̀rún ní ọ̀na àádọ́rin náírà.
Òfin tuntun fún iye owó òṣìṣẹ́ náà tún sọ pé ọdún mẹ́ta-mẹ́ta dípò ọdún márùn-ún-márùn-ún ni ìjọba gbọ́dọ̀ máa ṣe àyẹ̀wò owó yìí pẹ̀lú iye owó àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn nílò.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lẹyìn ìgbà tí wọ́n bù ọwọ́ lu ìwé yìí, Godswill Akpabio, olórí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà sọ pé owó òṣìṣẹ́ tí ó kéré jù kò gbọ́dọ̀ dín ní ẹgbẹ̀rún ní ọ̀na àádọ́rin náírà.
“Òfin tuntun fún owó tí ó kéré jù tí òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ gbà náà sọ pé tí o bá jẹ́ ránsọránsọ tí o sì gba ọmọ isẹ kan, owó ọmọ isẹ yìí ní oṣù kò gbọ́dọ̀ dín ní àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà. Tí o bá bímọ tuntun tí o sì fẹ́ gba olùrànlọ́wọ́ tó máa máa bá ẹ tọ́jú ọmọ ẹ, owó ọmọ isẹ yìí kò gbọ́dọ̀ dín ní àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà,” Akpabio ló sọ báyìí.
“Èyí kìí se owo oṣù tó pọ̀ jù tí òṣìṣẹ́ kan gbọ́dọ̀ gbà. Gbogbo agbanisisẹ ló gbọ́dọ̀ san àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà yìí. Tí o bá ni aṣọẹnuọnaile, owó oṣù to gbọ́dọ̀ san fún kò gbọ́dọ̀ dín ní àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà. Inú mi dùn pé eléyìí ti di òfin. A máa máa wo bí àwọn agbanisisẹ yóò ṣe ṣe bí òfin ṣe wí.
“Mo kí Nigeria Labor Congress (NLC), ẹgbẹ́ àpapọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà. Mo kí àwọn ọmọ Nàìjíríà, mo sì kí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin méjèèjì fún ètò pàtàkì yìí, èyí tí ó ti dín ìgbà fún àyẹ̀wò owó oṣù tó kéré jù láti ọdún márùn-ún sí ọdún mẹ́ta, nítorí pé eléyìí yóò mù àyípadà rere bá iye owó oúnjẹ tí ó wọ́n. Ó ṣe pàtàkì kí a mojuto àyẹ̀wò yìí.”
Àwọn ènìyàn ti fèsì sí ọ̀rọ̀ Akpabio yìí lórí àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media), pàápàá jù lọ lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí a mọ̀ sí X (alámì krọọsi) tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀. Wọn bií pé irú ọ̀rọ̀ wo lèyí.
“Àwàdà kẹríkẹrì ni èyí. Ó yẹ kí o wo àwọn òfin nípa owo tó kéré jù tí òṣìṣẹ́ ń gbà,” Tohluh Briggs ló sọ báyìí.
“Ní òótọ́? Kí ló ṣẹlẹ̀? Kí ló yí padà?” Philemon Kuza ló béèrè ọ̀rọ̀ báyìí.”
VIDEO: Nigerians can no longer pay domestic workers below N70k monthly, says Akpabio pic.twitter.com/hyZPutu0EY
— TheCable (@thecableng) July 24, 2024
KÍ NI OWÓ OṢÙ TÓ KÉRÉ JÙ?
Owó oṣù tó kéré jù jẹ́ owó oṣù tó kéré jù tí àwọn agbanisisẹ gbọ́dọ̀ san fún òṣìṣẹ́ kan. Òfin tí a mọ̀ sí National Minimum Wage Act ló ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ láti jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ gbé ìgbé ayé rere àti pé kí àwọn agbanisisẹ má baà yàn wọ́n jẹ.
Owó oṣù tó kéré jù fún òṣìṣẹ́ nisinyii jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀na ọgbọ̀n náírà. Ìgbà tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ kẹhin ni ọdún 2019 nígbà ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari.
Ní ọjọ́ kẹta, oṣù kẹfà, ọdún 2024, àwọn ẹgbẹ́ àpapọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ da isẹ silẹ káàkiri gbogbo Nàìjíríà nítorí pé ìjọba kò ṣe bí ó ṣe yẹ lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù yìí.
NLC àti Trade Union Congress (TUC) sọ pé kí ìjọba máa san ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹẹdẹgbẹta ó dín ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà náírà gẹ́gẹ́bí owó oṣù tó kéré jù lọ nítorí pé gbogbo nǹkan tí wọ́n.
Lẹhin ìgbà tí NLC àti TUC sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn asojú ìjọba àpapọ̀, àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yìí dín owó náa kù sí ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ìgbà àti àádọ́ta náírà.
Ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù keje, ọdún 2024, Ààrẹ Bọla Tinubu ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yìí lórí ọ̀rọ̀ náà.
Lẹ́hìn ìjíròrò pẹ̀lú Tinubu ní ọjọ́ kejìdínlógún, ọdún 2024, àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà gbà láti gba ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin náírà tí Ààrẹ ní òhun lè san.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ AKPABIO
Láti lè mọ bóyá òótọ́ tàbí irọ ni ọ̀rọ̀ Akpabio, TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára wo National Minimum Wage Act, 2019 láti mọ agbanisisẹ tí òfin sọ pé ó gbọ́dọ̀ san owó yìí àti agbanisisẹ tí òfin fún láàyè kí ó má san-án.
Abala kẹta, apá kinni Minimum Wage Act sọ pé owó tí ó kéré jù tí agbanisisẹ gbọ́dọ̀ san kò gbọ́dọ̀ kéré jù iye tí ìjọba àpapọ̀ sọ pé ó dára. Òfin yìí lòdì sí iye tí ó kéré sí owó yìí.
Àmọ́sá, òfin yìí fún àwọn agbanisisẹ kan ní àǹfààní.
Abala kẹrin òfin yìí sọ pé kí àwọn agbanisisẹ tí àwọn òṣìṣẹ́ wọn bá dín ní marundinniọgbọn (25) má san owó yìí.
Òfin yìí fún àwọn agbanisisẹ tí iṣẹ́ wọn bá jọ mọ àwọn ohun tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀ yìí tàbí tí iṣẹ́ wọn jẹ́ bí àwọn ohun ìsàlẹ̀ yìí láti má san owó yìí:
- iṣẹ́ tí kìí se pé òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ wá síbi iṣẹ́ ní gbogbo ìgbà ní oṣù.
- iṣẹ́ tí wọn máa kàn fún òṣìṣẹ́ ní owó lórí iye tí ó bá rí tàbí pa.
- Ilé iṣẹ́ tí kò ní tó òṣìṣẹ́ marundinniọgbọn.
- Àwọn iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn kò ní láti ṣe ní gbogbo ìgbà bíi iṣẹ́ àgbẹ̀.
- Àwọn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ nínú ọkọ̀ òfuurufú tàbí ojú omi.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Tí a bá wo àgbékalẹ̀ ofin tí a mọ̀ sí National Minimum Wage Act, 2019, ọ̀rọ̀ tí Akpabio sọ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbanisisẹ tí ó gba aṣọgeeti tàbí ẹni tí ó máa máa dáná oúnjẹ fún un kò lè san owó oṣù tó dín ní àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà gẹ́gẹ́bí òfin ṣe sọ kìí se òótọ́.
Ara ohun tí Òfin yìí sọ ni pé owó oṣù tó kéré jù tí agbanisisẹ tí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ bá lé ní marundinniọgbọn gbọ́dọ̀ san kò gbọ́dọ̀ dín ní àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà.