Fídíò kan tí ó ń se ìkéde ìtọ́jú aarun suga káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti káàkiri orí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára.
Ọ̀rọ̀ yìí sọ pé Ali Pate, minisita fún ètò ìlera ni Nàìjíríà ti se akojade oògùn kan tí ó máa gba gbogbo ènìyàn lọ́wọ́ aarun ìtọ̀ suga, tí wọn yóò lọ fún àwọn ènìyàn nílé wọn.
Wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí bíi pé ó jẹ́ òótọ́ débi pé ẹni tí kò bá ń ronú dáadáa má rò pé òótọ́ ni. Àmọ́, wọn padà wá sọ pé kì í ṣe òótọ́-ó jẹ́ ara àwọn nǹkan tí kìí se òótọ́ tí àwọn ènìyàn ń pín lórí ayélujára tí àwọn elédè òyìnbó ń pè ní deepfakes.
Deepfakes jẹ́ àwọn nǹkan ìròyìn tí àwọn ènìyàn dá ọgbọ́n sí láti lè jẹ́ kí ó dàbí pé ènìyàn kan ló sọ tàbí se nnkan tí ẹni yìí kò sọ tàbí se. Ní aipẹ yìí, àwọn ènìyàn ti ń se tàbí pín irú nnkan báyìí láti lè sọ ọ̀rọ̀ òṣèlú tó jẹ́ irọ́, lu ẹnì kan ní jìbìtì tàbí ba orúkọ ẹlòmíràn jẹ́.
Báwo ni ènìyàn se lè mọ irú nnkan báyìí kí ó tó parọ́ fún ẹ? Nínú àlàyé ìsàlẹ̀ yìí, CableCheck ṣàlàyé ohun méje tí ó lè jẹ́ kí o mọ ọ̀rọ̀ irú nǹkan báyìí tí kìí se òótọ́ tí wọ́n fi AI (Artificial Intelligence) se fídíò rẹ̀ (AI-generated video).
1. Ojú tó rí bákan: Ojú ènìyàn nínú irú fídíò yìí kìí sẹju bó ṣe yẹ, ẹ̀rín irú nnkan báyìí kò ní bójú mú, orí a sì máa mì bakanbakan nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fídíò tí wọ́n fi AI se.
2. Ojú tí kò lọ sí ibí kan: Deepfakes máa ń se afihan ojú tó máa ń tẹjú mọ nnkan fún ìgbà pipẹ, ojú tí kò sẹju bí ó se yẹ, tàbí ojú tó máa ń wo àwọn nǹkan kan tí kò yẹ, nígbà tí ẹni kan bá ń sọ̀rọ̀.
3. Ọ̀rọ kò ní bá ẹnu/ètè mu: Wo ẹnu ẹni tó wà nínú fídíò láti lè mọ fídíò tí kìí se gidi. Ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu jáde kìí bá bi ẹnu ṣe lọ síwájú, lọ sẹhin mú nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn fídíò tí wọ́n fi AI se.
4. Àwọn ìka ọwọ́ tí ènìyàn kò lè rí dáadáa tàbí kí ọwọ́ kankan má hàn: Kò tíì seése fún AI láti se ọwọ́ àti ìka ọwọ́ gidi. Nínú fídíò/ohun tí wọ́n bá fi AI se (deepfakes), wàá rí ọwọ́ tí kò ṣeé rí dáadáa tí ọwọ́ yìí bá ń lọ síbí, sọhun, ọwọ́ yìí kò sì ní lọ bí ó ṣe yẹ kó lọ ní apá kan.
5. Ọ̀rọ̀ inú fídíò báyìí máa rí bákan: Ohùn ẹni tí wọ́n fẹ́ parọ́ nípa ẹ ni wọ́n sáábà máa ń tiraka láti lò. Àmọ́, kìí dà bí ohùn ẹni náà, lílọ àti bíbọ̀ ohùn kò kí ń bá àgbègbè tí wọ́n ti se kiní yìí lọ, wàá rí pé inú ilé ni ohun tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ wà, ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ sì wà níta.
6. Abẹlẹ tí kò bára mu: Fídíò tàbí ohun tí wọ́n bá fi AI se kìí dúró lójú kan náà pẹ̀lú àyíká tí wọ́n ti ṣeé. O lè ríi pé ògiri ń mì, àwọn àga kò dúró dáadáa tàbí kí nkan tí kò yẹ wà níbì kan.
7. Aṣọ àti àwọn ohun isaraloge kò níí hàn dáadáa: Fídíò tàbí ohun tí wọ́n bá fi AI se kì í lè se àfihàn aṣọ bí wọn se rán an sí. Bí wọ́n se rán aṣọ a máa lọ, a máa bọ̀. Wàá tún ríi pé yẹrí etí máa pòórá, á tún hàn tàbí kí ó rí gíláàsì tí kò fi òjìjí tí ó yẹ kí o hàn nínú fídíò náà hàn bó ṣe yẹ.
Ènìyàn kì í lè mọ irú fídíò yìí nígbà mìíràn. O lè lo InViD, Deepware Scanner àti àwọn ohun mìíràn láti mọ bóyá AI ni wọ́n fi se fídíò tàbí ohun kan.