TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ọdún 2019 ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí òṣìṣẹ́ Customs tí sèsì yín ìbọn pa ènìyàn ṣẹlẹ̀
Share
Latest News
Naijiria ọ̀ kàgbùrù ńkwékọ́rị́tá àzụ́máhị́á àkụ̀ ọ̀nàtàràchí yá nà US nwèrè n’íhì ḿmáchí visa?
Ǹjẹ́ Nàìjíríà dá àjọṣe lórí àwọn àlùmọ́ọ́nì láàárín òhun àti Amẹ́ríkà dúró nítorí visa?
Nigeria stop ‘mineral deal’ with US afta visa restriction?
Shin Najeriya ta dakatar da ‘yarjejeniyar ma’adinai’ da Amurka bayan hana biza?
FACT CHECK: Did Nigeria halt ‘mineral deal’ with US after visa restrictions?
FACT CHECK: Viral image depicting ‘Obasanjo prostrating for Ladoja’ photoshopped
Wike tụ̀rụ̀ àsị́. Peter Obi mèrè ńtụ̀líáká ọ̀chị́chị́ ḿpághárá m̀gbè ọ́ bụ̀ gọ́vánọ̀ Anambra
Irọ́ ni Wike pa. Peter Obi ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ọdún 2019 ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí òṣìṣẹ́ Customs tí sèsì yín ìbọn pa ènìyàn ṣẹlẹ̀

Yemi Michael
By Yemi Michael Published June 7, 2025 5 Min Read
Share

Àwọn òṣìṣẹ́ aṣọbode (the Nigerian Customs Service-NCS) ti sọ̀rọ̀ nípa fídíò kan tí àwọn ènìyàn ti pín kiri tí ó se àfihàn òṣìṣẹ́ NCS níbi tí wọ́n ti yin ìbọn fún ènìyàn kan.

Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí níí pin fídíò yìí lórí àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social networking sites) ní ọjọ́ ajé, ọdún 2025, lẹ́hìn ìgbà tí ẹni kan tí ó ń lo ohun ìgbàlódé ibi ibaraẹnisọrẹ fi ọ̀rọ̀ yìí síta, ó sì sọ pé ọjọ́ tí òhun fi ọ̀rọ̀ yìí síta ni ó ṣẹlẹ̀.

“Òṣìṣẹ́ Customs kan ní òpópónà marosẹ ìlú Èkó sí Benin city (Lagos-Benin expressway), yin ìbọn, ó sì pa ẹnì kan tí ó padà dé láti ibi kan nítorí pé ẹni tó padà dé yìí kọ̀ láti fún un ní ẹgbẹ̀rún marun náírà owó rìbá,” báyìí ni àkòrí fídíò yìí se wí. “Àwọn ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí ń padà bọ̀ láti orílẹ̀ èdè US àti UK, wọ́n sì ń lọ sí Benin.

“Eléyìí ṣẹlẹ̀ lónìí, ọjọ́ kẹta, oṣù kẹfà, ọdún 2025. Ẹ jọ̀wọ́ pin in títí tí yóò fi dé ọ̀dọ àwọn aláṣẹ ìjọba tí wọ́n jẹ́ ọga pátápátá. Kí ni Orílẹ̀ èdè yìí fẹ́ yìí padà sí báyìí??????”

Nínú fídíò yìí, obìnrin kan ń sọ̀rọ̀ ní abẹlẹ, ó sì ń pariwo, ó ń fi ẹ̀sùn kan òṣìṣẹ́ Customs pé ó pa ọkùnrin kan nítorí pé ọkùnrin yìí kò fún òṣìṣẹ́ Customs yìí ní ẹgbẹ̀rún marun náírà owó rìbá. Èdè oyinbo amulumala ni obìnrin yìí fi sọ̀rọ̀.

CableCheck rí àwọn èrò inu fídíò yìí níbí tí wọ́n ti ń ńọ òṣìṣẹ́ Customs yìí, òkú ènìyàn tí wọ́n ní òṣìṣẹ́ Customs yìí pa wà nílẹ̀.

ÀWỌN CUSTOMS SỌ PÉ FÍDÍÒ YÌÍ KÌÍ SE FÍDÍÒ TÍ WỌ́N ṢẸ̀ṢẸ̀ FI SÍTA 

Ọ̀rọ̀ kan tí Abdullahi Maiwada, agbẹnusọ fún NCS sọ, sọ pé ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kejì, ọdún 2019, kìí se ọ̀rọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Maiwada fi síta yìí jẹ́ ìgbàẹnusọ fún Bashir Adeniyi, ẹni tí ó jẹ́ ọga pátápátá (Comptroller General) fún NCS.

Maiwada sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní Shagamu interchange, ní Ìpínlẹ̀ Ogun, ó sọ pé Customs gbé ìgbésẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti se nnkan nípa ọ̀rọ̀ yìí. 

“Customs fi ọ̀rọ̀ yìí tó àwọn ènìyàn létí nígbà yẹn, a sì se agbekalẹ ìwádìí gidi láti se ohun tí ó yẹ,” Maiwada ló sọ báyìí.

“Lẹ́hìn ìwádìí yìí, Customs fi ìyà tó tọ́ jẹ àwọn òṣìṣẹ́ NCS tí àwọn ènìyàn fi ẹ̀sùn kàn yìí tí wọ́n sì jẹ ẹ̀bi ẹ̀sùn yìí, a sì lé wọn kúrò nìdí isẹ Customs,” Maiwada ló tún sọ báyìí.

“Ó se kókó pé kí a sọ pé NCS jẹ́ ẹ̀ka isẹ ìjọba tí òfin gbé kalẹ̀, tí òfin sì tì lẹ́yìn dáadáa, a sì mọ ohun tí ó tọ́. Nípa ìdí èyí, NCS kò ní gba òṣìṣẹ́ wọn kankan láyè láti hu ìwà tí kò bá òfin mu,” Customs ló sọ báyìí.  

“Biotilẹjẹpe fídíò yìí jáde laimọ wa, a ti se ohun tó yẹ nípa ọ̀rọ̀ yìí gẹ́gẹ́bí ìlànà àti òfin tí wọ́n fi gbé NCS kalẹ̀ ṣe wí. Maiwada sọ pé kí àwọn ènìyàn máa se ìwádìí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ dáadáa lọ́wọ́ NCS kí wọ́n má baà si àwọn ènìyàn lọ́nà.

TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára, rí àwọn ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2019.

Gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ yìí se wí, NCS sọ pé òṣìṣẹ́ àwọn kankan kò bèrè ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà yìí. NCS sọ pé ẹni tí àwọn ènìyàn  ní wọ́n yin ìbọn fún yìí jẹ́ ẹni tí àwọn òṣìṣẹ́ Customs máa ń rán kó bá wọn se nnkan, ẹni yìí kìí se èrò ọkọ̀ náà bí fídíò náà se sọ.

Nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀, NCS sọ pé ìkan nínú àwọn òṣìṣẹ́ wọn ló se àṣìṣe, tí ó yín ìbọn tí ó pa ẹni yìí nígbà àríyànjiyàn kan.

TAGGED: Customs, customs officer, factcheck, Factcheck in Yorùbá, NCS, News in Yorùbá, Shooting

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael June 7, 2025 June 7, 2025
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print

POPULAR POSTS

Advertisement

Naijiria ọ̀ kàgbùrù ńkwékọ́rị́tá àzụ́máhị́á àkụ̀ ọ̀nàtàràchí yá nà US nwèrè n’íhì ḿmáchí visa?

Ótù onye nà Facebook ekwuola na Naijiria emegwarụla mgbachibido visa nke mba US site n'ịkwụsị…

July 18, 2025

Ǹjẹ́ Nàìjíríà dá àjọṣe lórí àwọn àlùmọ́ọ́nì láàárín òhun àti Amẹ́ríkà dúró nítorí visa?

Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára ti sọ pé…

July 18, 2025

Nigeria stop ‘mineral deal’ with US afta visa restriction?

One Facebook user claim sey Nigeria revenge against di recent United States visa restriction by…

July 18, 2025

Shin Najeriya ta dakatar da ‘yarjejeniyar ma’adinai’ da Amurka bayan hana biza?

Wani ma’abocin amfani da shafin Facebook ya yi ikirarin cewa Najeriya ta mayar da martani…

July 18, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Naijiria ọ̀ kàgbùrù ńkwékọ́rị́tá àzụ́máhị́á àkụ̀ ọ̀nàtàràchí yá nà US nwèrè n’íhì ḿmáchí visa?

Ótù onye nà Facebook ekwuola na Naijiria emegwarụla mgbachibido visa nke mba US site n'ịkwụsị nkwekọrịta azụmahịa akụ ọnatarachi dị…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 18, 2025

Ǹjẹ́ Nàìjíríà dá àjọṣe lórí àwọn àlùmọ́ọ́nì láàárín òhun àti Amẹ́ríkà dúró nítorí visa?

Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára ti sọ pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà hùwà sí…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 18, 2025

Nigeria stop ‘mineral deal’ with US afta visa restriction?

One Facebook user claim sey Nigeria revenge against di recent United States visa restriction by stopping one alleged mineral deal…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 18, 2025

Shin Najeriya ta dakatar da ‘yarjejeniyar ma’adinai’ da Amurka bayan hana biza?

Wani ma’abocin amfani da shafin Facebook ya yi ikirarin cewa Najeriya ta mayar da martani ne kan takunkumin da Amurka…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 18, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?