Ẹni kan tí ó ń lo ohun ìgbàlódé ibaraẹnise orí ayélujára ti sọ pé Olùṣẹ̀gun Ọbásanjọ́, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, ti dá sí rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Rivers.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe wí, Ọbásanjọ́ lọ rí Siminalayi Fubara, gómìnà Ìpínlẹ̀ Rivers, ó sì sọ fún un pé kí ó ti ilé ìgbìmọ̀ asòfin Ìpínlẹ̀ náà, kí ó sì kó àwọn agbófinró tí wọ́n ń sọ àwọn asòfin náà kúrò lẹ́hìn wọn.
Ọ̀rọ̀ yìí tún sọ pé Ọbásanjọ́ gba Fubara ní àmọ̀ràn pé kí ó pàṣẹ pé kí wọ́n ti Nigeria National Petroleum Company (NNPC) àti Niger Delta Development Commission (NDDC) àti pé kí wọ́n wó ibikíbi tí àwọn ènìyàn fẹ́ lò láti fi yọọ kúrò nípò gómìnà.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti ọọdunrun lò fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ẹẹdẹgbẹta lò ti pín ín, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀ta àti ogún ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, tí wọ́n fi sórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise àlámì krọọsi (X), tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀.
“OBJ TU ITỌ SÓKÈ, Ó FOJÚ GBÀÁ-Ti ilé ìgbìmọ̀ asòfin Ìpínlẹ̀ Rivers, kéde eto ipò pajawiri ní Ìpínlẹ̀ Rivers-Ọbásanjọ́ lọ rí Sim Fubara,” báyìí ni atẹsita kan se sọ pé Ọbásanjọ́ sọ.
“Kó àwọn agbófinró tí wọ́n ń sọ àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin Ìpínlẹ̀ Rivers kúrò lẹ́hìn wọn. Ti NNPC, NDDC, kò sí fi ojú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ di ọ̀tẹ̀ mọ ẹ rí mábo,” ọ̀rọ̀ yìí lò tún sọ báyìí.
“Ìwọ ni gómìnà tí àwọn ènìyàn fi ìbò yàn. Ìwọ ni Aláṣẹ pátápátá fún ètò ààbò ní Ìpínlẹ̀ Rivers. Àṣẹ tó bá pa ní àwọn ènìyàn máa tẹ̀lé. Tinubu àti Wike kọ ló fi ẹ sípò gómìnà. Wó ibikíbi tí wọ́n fẹ́ lò láti yọ ẹ. Tinubu nílò ìbò Ìpínlẹ̀ Rivers láti ṣàṣeyọrí nínú ìbò 2027, o ní agbára láti má jẹ́ kí ó ṣàṣeyọrí.”
RÒGBÒDÌYÀN ÒṢÈLÚ NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS
Rògbòdìyàn òsèlú tí ń ṣẹlẹ̀ láti ìgbà pipẹ láàárín Fubara àti Nyesom Wike, minisita fún Federal Capital Territory (FCT), ẹni tí ó fi ipò gómìnà Ìpínlẹ̀ Rivers sílẹ̀ kí Fubara tó di gómìnà.
Ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹta, ọdún 2025, ọ̀rọ̀ yìí di wàhálà gan-an, àwọn asòfin Ìpínlẹ̀ náà sì bẹ̀rẹ̀ ètò àti yọ Fubara kúrò nípò gómìnà àti yíyọ Ngozi Odu, igbakeji Fubara, kúrò nípò, nítorí pé “àwọn méjèèjì hu ìwà tí kò dára.”
Ní ọjọ́ kejidinlọgbọn, oṣù kejì, ọdún 2025, ilé ẹjọ́ tó láṣẹ jù ní Nàìjíríà, sọ pé wọ́n kò gbọ́dọ̀ yìí ìdájọ́ federal high court tó sọ pé Central Bank of Nigeria (CBN), ilé ifowopamọ ìjọba àpapọ̀ àti accountant-general of the federation, ẹni tí ó ń ṣètò owó ìjọba àpapọ̀, kò gbọ́dọ̀ fi owó tí ìjọba àpapọ̀ máa ń fún Ìpínlẹ̀ Rivers ní osoosu sílẹ̀ padà.
Ilé ẹjọ́ tó ga jù yìí tún sọ pé ìdìbò fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n se ni Ìpínlẹ̀ náà ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹwàá, ọdún 2024, kò dára tó. Fubara sọ pé òhun yóò tẹle ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jù yìí láti lè dá rògbòdìyàn yìí dúró.
Ilé ìgbìmọ̀ asòfin Ìpínlẹ̀ náà sún gbigbọ ọ̀rọ̀ yìí síwájú, lẹ́hìn ìgbà tí Fubara kọwé sì ilé ìgbìmọ̀ asòfin Ìpínlẹ̀ náà ní ẹ̀keji, láti bere ọjọ́ tí òhun lè gbé ètò isuna (appropriation bill), ọdún 2025, wá síwájú wọn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n fẹ́ kí rògbòdìyàn yìí wá sópin.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ THECABLE NEWSPAPER SE RÈÉ
CableCheck bá Kehinde Akinyemi, oluranlọwọ fún Ọbásanjọ́, fún ọ̀rọ̀ àwùjọ, sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ó ní pé ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́.
Ó sọ pé Ọbásanjọ́ kò lọ rí Fubara, kò sì sọ fún un pé kí ó se àwọn nǹkan ta mẹ́nuba yìí.
“Gẹ́gẹ́bí ẹ se mọ̀, Ọbásanjọ́ kò kí ń lo ohun ìgbàlódé ibaraẹnise orí ayélujára (social media), kò sì lọ rí gómìnà náà tàbí sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí,” Akinyemi ló sọ báyìí.
A tún ríi pé kò sí ilé isẹ ètò ìròyìn kankan tó ṣeé gbára lé tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí.
Ijoba Ìpínlẹ̀ Rivers sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́. Wọ́n sọ pé ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ “ọ̀nà láti dá wàhálà sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Rivers.”
Ọ̀rọ̀ kan tí Nelson Chukwudi, agbẹnusọ fún Fubara fi síta ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, sọ pé Ọbásanjọ́ tàbí àwọn ènìyàn kankan kò wá rí Fubara lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Chukwudi fi kún ọ̀rọ̀ ẹ pé Fubara ti gbà láti tẹle ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jù.
“A fẹ́ jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ pé àwọn tí a mọ̀ sí PANDEF kò wá rí Fubara ní ọjọ́ tí wọ́n sọ yìí. Ọbásanjọ́ kò sì wá.”
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Ọbásanjọ́ sọ yìí nípa rògbòdìyàn Ìpínlẹ̀ Rivers kìí se òótọ́. Ọbásanjọ́ kò sọ pé kí Fubara ti NDDC àti NNPC.