TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Nwifuru kò dá àwọn òṣìṣẹ́ dúró lẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé wọ́n kò wá sí ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ̀
Share
Latest News
È nwélá ọ́nwụ́ ńdị́ ụ́kà nà Naijiria n’áfọ̀ 2025 kárị́á ọ́nụ́ ọ́gụ́gụ́ ndị́ Palestinian é gbụ́rụ́ na Gaza?
Na true sey dem kill Christians for Nigeria dis year pass Palestinians for Gaza?
Ǹjẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n pa ní Nàìjíríà ju àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n pa ní Gaza lọ ní 2025?
Yi Kiristoci da aka kashe a Nijeriya a 2025 sunfi na faltunawan dake Gaza?
FAKE NEWS ALERT: We didn’t declare Iyabo Ojo wanted, say police
MISINFO ALERT: Viral video of clash between tricycle rider, our officers from 2020, says FRSC
DISINFO ALERT: Photo showing European leaders ‘sitting outside Trump’s office’ is doctored
MISINFO ALERT: No evidence Shettima said ‘N8,000 can change the life of a youth’
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Nwifuru kò dá àwọn òṣìṣẹ́ dúró lẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé wọ́n kò wá sí ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ̀

Yemi Michael
By Yemi Michael Published August 1, 2025 5 Min Read
Share
Francis Nwifuru

Ọ̀rọ̀ kan lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára sọ pé Francis Nwifuru, gómìnà Ìpínlẹ̀ Ebonyi dá àwọn kọmisọnna marundinlọgbọn àti àwọn mìíràn tó yàn sípò dúró lẹ́nu iṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nítorí pé wọ́n kò wá sí ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ ọkùnrin gómìnà.

Ọ̀rọ̀ yìí, èyí tí IgboHistory&Facts fi síta lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi (X), tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, ti ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹtadinlọgọfa tí wọ́n ti ríi. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ọọdunrun ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́tàlá ló pín in, àwọn ènìyàn marunlelẹẹdẹgbẹta ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ.

Ọ̀rọ̀ yìí ní àwòrán Nwifuru pẹ̀lú ìyàwó àti ọmọ rẹ̀. Àwọn ènìyàn mìíràn tí wọ́n ń lo ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media) fi ọ̀rọ̀ yìí sórí ayélujára níbí, níbí, àti níbí.

Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, Nwifuru dá àwọn  kọmisọnna marundinlọgbọn, àwọn olùrànlọ́wọ́ àgbà mẹ́rìnlá fún gómìnà yìí, àwọn olùrànlọ́wọ́ mẹ́rìnlélógún fun gómìnà yìí tí wọ́n kéré sí àwọn olùrànlọ́wọ́ àgbà àti àwọn ọ̀gá pátápátá ní àwọn ẹ̀ka isẹ ìjọba (permanent secretaries) dúró fún ìgbà díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé wọn kò wá sí ibi ayẹyẹ pàtàkì kan ti ìjọba Ebonyi se.

Gómìnà yìí sọ pé àwọn tí òhun dá dúró yìí  kò gbọ́dọ̀ wá sí ibi iṣẹ́ fún oṣù kan, wọn kò sì ní gba owó oṣù fún oṣù kan yìí àti wí pé wọn kò gbọ́dọ̀ bu ọwọ́ lu ìwé iṣẹ́ ìjọba kankan nígbà tí wọ́n kò nìí fi wá sí ibi iṣẹ́.

ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ

CableCheck se àyẹ̀wò ibi íbaraẹnise orí Facebook tí ó jẹ́ ti gómìnà yìí, a sì ríi pé fọto (àwòrán) tí wọ́n lò fún ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ èyí tí wọ́n lò nígbà ayẹyẹ ìdúpẹ́ ọjọ́ ìbí ọmọ gomina yìí tó jẹ́ obìnrin tó wáyé ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣù keje, ọdún 2025, ọjọ́ méjì kí Ìpínlẹ̀ Ebonyi tó kéde ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ yìí.

CableCheck tún kàn sí Monday Uzor, ọ̀gá àwọn onísẹ́ ìròyìn (chief press secretary) fún gómìnà Ebonyi yìí. Uzor ní ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́.

Uzor sọ pé ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ yìí jẹ́ ohun tí gómìnà náà se láti dá sẹ̀ríyà fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba yìí nítorí pé wọ́n kùnà láti wá sí ibi ìdíje kan (basic school sports competition), tí Universal Basic Education Board sètò ẹ ní Ìpínlẹ̀ náà.

Uzor sọ pé Nwifuru sọ fún Patricia Obila, igbá-kejì gómìnà, kó ṣojú òhun níbi ìdíje yìí, gómìnà yìí sì sọ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba mìíràn lọ síbẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn kò lọ.

“Gómìnà lọ sí ibì kan, ó sì sọ pé kí igbá-kejì òhun lọ ṣojú òhun níbi ìparí ìdíje tí wọ́n pè ní basic school sports competition, tí Universal Basic Education Board (UBEC) ṣètò ẹ. Àmọ́sá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kọmisọnna àti àwọn mìíràn tí gómìnà yàn sípò kò lọ sí ibi ayẹyẹ yìí,” báyìí ni Uzor se sọ fún CableCheck.

“Nígbà tí gómìnà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó gbé ìgbésẹ̀ nítorí pé kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí irú nkan báyìí ṣẹlẹ̀ rèé.” “Oníkatikati ni àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n mọ ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òótọ́.”

“Àwòrán ọ̀rọ̀ yìí kò ní ohunkóhun se pẹ̀lú ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Wọ́n ya àwòrán yìí níbi ayẹyẹ kan tí gómìnà lọ ní oṣù keje, ọdún 2025,” Uzor lo sọ báyìí.

CableCheck tún se àyẹ̀wò ibi íbaraẹnise ti Obila lórí Facebook. A ríi pé ètò tí àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ẹ yìí wáyé ní ọjọ́ ẹtì, ọjọ́ karundinlọgbọn, oṣù keje, ọdún 2025, ọjọ́ méjì kí ọmọ Nwifuru obìnrin tó se ọjọ́ ìbí rẹ̀.

BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ 

Ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan sọ pé Nwifuru dá àwọn kọmisọnna àti àwọn ènìyàn mìíràn tó yàn sípò dúró lẹ́nu iṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nítorí pé wọ́n kò wá sí ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ rẹ̀ obìnrin kìí se òótọ́.

TAGGED: Birthday Party, factcheck, Factcheck in Yorùbá, Francis Nwifuru, News in Yorùbá, officials

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael August 1, 2025 August 1, 2025
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print

POPULAR POSTS

Advertisement

È nwélá ọ́nwụ́ ńdị́ ụ́kà nà Naijiria n’áfọ̀ 2025 kárị́á ọ́nụ́ ọ́gụ́gụ́ ndị́ Palestinian é gbụ́rụ́ na Gaza?

Ótù ozi na soshal midia ekwuola na enwéla ọnwụ ndị ụka na Naijiria karịa ọnụ…

August 21, 2025

Na true sey dem kill Christians for Nigeria dis year pass Palestinians for Gaza?

One social media post don claim sey di Christians wey die for Nigeria pass Palestinians…

August 21, 2025

Ǹjẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n pa ní Nàìjíríà ju àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n pa ní Gaza lọ ní 2025?

Ọ̀rọ̀ kan lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára tí sọ pé iye àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́…

August 21, 2025

Yi Kiristoci da aka kashe a Nijeriya a 2025 sunfi na faltunawan dake Gaza?

Wani rubutu da aka wallafa a dandalin sada zumunta ya yi zargin cewa an kashe…

August 21, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Na true sey dem kill Christians for Nigeria dis year pass Palestinians for Gaza?

One social media post don claim sey di Christians wey die for Nigeria pass Palestinians wey die for Gaza since…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 21, 2025

Ǹjẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n pa ní Nàìjíríà ju àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n pa ní Gaza lọ ní 2025?

Ọ̀rọ̀ kan lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára tí sọ pé iye àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ (àwọn kristẹni) tí wọ́n ti…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 21, 2025

Yi Kiristoci da aka kashe a Nijeriya a 2025 sunfi na faltunawan dake Gaza?

Wani rubutu da aka wallafa a dandalin sada zumunta ya yi zargin cewa an kashe Kiristoci a Najeriya fiye da…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 21, 2025

Ụ́zọ̀ àsáà é jì àmátá íhé ńgósị́ é jìrì AI nwòghárị́á

Íhé ngosị na-ekwupụta nkesa ọgwụ na-agwọ ọrịa diabetes pụtara ìhè na soshal midia Naịjiria. Íhé ńgósị́ ahụ kwuru na Ali…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 19, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?