Uche Rochas, ọkùnrin oníṣòwò kan sọ pé owó tí Alex Otti, gómìnà Ìpínlẹ̀ Abia yá láàrin ọdún kan ju gbogbo owó tí àwọn tí wọ́n ti ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ náà yá nígbà tí wọ́n ṣe ìjọba.
Lórí X rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2024, Rochas sọ pé Otti nọ́ “mílíọ̀nù mẹsan náírà lojoojumọ lórí oúnjẹ láti ara owó orí tí àwọn ará Ìpínlẹ̀ Abia san.”
“Kí ó tó lo ọdún kan nípò gómìnà, ó ti yá owó tí ó ju gbogbo owó tí Orji Kalu, Theodore Orji ati Okezie Ikpeazu yá nígbà tí wọ́n ṣe gómìnà,” Rochas ló sọ báyìí.
“Àwọn ọ̀nà tí kò dára tó ló ń ṣe. Àwọn Farisí tí a mọ̀ sí obidient movement kò rí nǹkan tó burú nípa èyí.”
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀na ọ̀ọ́dúnrún ló rí ọ̀rọ̀ náà, ẹẹdẹgbẹrin àti ọgọ́ta ó lé ìkan ènìyàn ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ọgọ́sàn-án àti ìkan ló pín ín lórí X.
ÀWỌN ÈNÌYÀN WO NI WỌ́N DÁRÚKỌ WỌN NÍNÚ ATẸSITA ORÍ TWITTER?
Kalu jẹ́ olóṣèlú àti oníṣòwò tí ó ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ Abia láti ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún, ọdún 1999 di ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún, ọdún 2007.
Òhun ni asojusofin ní ilé igbimọ asofin àgbà tó ṣe ojú àwọn ará Abia north senatorial district.
Theodore Orji ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ náà láti ọdún 2007 di ọdún 2015, ó ṣì tún ṣe asojusofin (sẹnetọ) tí ó ṣojú Abia central senatorial district láti ọdún 2015 di ọdún 2023.
Ikpeazu ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ náà láti oṣù karùn-ún, ọdún 2015 di oṣù karùn-ún, ọdún 2023.
ÀYẸ̀WÒ OWÓ ÌSÚNÁ
Rochas sọ pé Otti nọ́ mílíọ̀nù mẹsan náírà lórí oúnjẹ. Àmọ́sá, nínú owó ìsúná ọdún 2024, mílíọ̀nù marun-undinlẹdẹgbẹta àti ọgọfa ẹgbẹ̀rún náírà ni ìjọba Otti yà sí ọ̀tọ̀ fún jíjẹ àti mímu fún ọ́fíìsì gómìnà, eléyìí tí ìṣirò rẹ̀ lójúmọ́ jẹ́ mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀ta àti ọgbọ́n náírà.
ÀYẸ̀WÒ OWÓ TÍ ROCHAS NÍ OTTI YÁ
Láti lè mọ̀ bóyá òótọ́ tàbí irọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí, TheCable.ng (TheCable Newspaper), ìwé ìròyìn orí ayélujára kọ́kọ́ wo iye owó tí Abia yá lọ́wọ́ ní Ìpínlẹ̀ náà àti níta nígbà ìjọba Orji Uzor Kalu àti Ikpeazu pẹ̀lú tí Otti, a kò rí àwọn nọ́mbà tó ṣeé gbáralé láti fi ṣe èyí.
Debt Management Office (DMO), ẹ̀ka ìjọba tó máa ń rí sí gbèsè owó tí Nàìjíríà jẹ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkójọ owó tí Abia jẹ ní ọdún 2011. Èyí túmọ̀ sí pé wọn kò sọ iye gbèsè owó tí Ìpínlẹ̀ Abia jẹ láàárín ọdún 1999 sí ọdún 2010.
A kò rí rẹkọọdu tàbí àkọsílẹ̀ gbèsè owó tí Abia jẹ nígbà méjì tí Kalu ṣe gómìnà (1999-2003, 2003-2007) àti ìgbà àkọ́kọ́ (2007-2011) tí Theodore Orji ṣe gómìnà.
Àmọ́sá, rẹkọọdu tí a rí fi hàn pé gbèsè owó Abia jẹ́ bílíọ̀nù méjìlógóje, mílíọ̀nù àádọ́rinléníirínwó, ẹẹdẹgbẹrin ó lé ní ogún ó dín ní mẹta ẹgbẹ̀rún àti díẹ̀ náírà ní oṣù kẹfà, ọdún 2023, oṣù kan lẹ́hìn tí Otti di gómìnà.
Rẹkọọdu yìí fihàn pé gbèsè owó tí Abia yá ní ìpínlẹ̀ náà ti dínkù pẹ̀lú biliọnu mẹ́ta àti ẹgbẹrin àti ọgbọ́n mílíọ̀nù náírà sí mejidinlogoje biliọnu, ẹgbẹ̀ta àti mejidinlogoji mílíọ̀nù àti ẹgbẹ̀rún méje náírà ní oṣù Kejìlá, ọdún 2023, oṣù mẹ́fà lẹ́hìn tí Otti di gómìnà.
Gbèsè owó tí Abia yá lọ́wọ́ àwọn tí kìí se ara Abia dín pẹ̀lú mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rún ìgbà lé ní àádọ́rin dọ́là nígbà ìjọba Otti.
Nígbà ọdún àkọ́kọ́ ìjọba Ikpeazu, gbèsè owó tí Ìjọba Ìpínlẹ̀ náà yá ní Abia jẹ́ biliọnu marundinniọgọrun, mílíọ̀nù igba àti méjìlá àti ẹẹdẹgbẹrin dín ní mẹ́tàlá ẹgbẹ̀rún náírà ní oṣù Kejìlá, ọdún 2021. Gbèsè yìí di biliọnu mẹtalelọgọrun, mílíọ̀nù ẹẹdẹgbẹrin àti mẹwa àti ẹgbẹ̀rún mọkanla náírà ní oṣù Kejìlá, ọdún 2022.
Àmọ́sá, gbèsè náà jẹ́ mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún àti ìkan, aadoje àti méjì pẹ̀lú ẹẹdẹgbẹrin àti ọgọ́ta dín ní mẹ́fà ẹgbẹ̀rún dọ́là. Gbèsè yìí lọ sílẹ̀, ó sì di mílíọ̀nù mẹrinlelaadọọrun, igba àti ọgọrin ó dín ní ìkan dọ́là láàrin oṣù Kejìlá, ọdún 2021 sí oṣù Kejìlá, ọdún 2022.
Gbèsè owó tí Ìjọba Ìpínlẹ̀ náà yá ní Abia ní oṣù Kejìlá, ọdún 2013 nígbà ìjọba Theodore Orji jẹ́ biliọnu mọkanlelọgbọn, ẹẹdẹgbẹrin àti ogójì dín ní mẹ́rin mílíọ̀nù àti ẹẹdẹgbẹrin àti mẹsan náírà. Owó yìí lọ sílẹ̀, ó sì di biliọnu marundinniọgbọn, mílíọ̀nù mẹrindinniaadoje àti àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà ní oṣù Kejìlá, ọdún 2014.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Gẹ́gẹ́bí rẹkọọdu DMO ṣe fi yé wa, a ríi pé gbèsè owó tí Abia jẹ ti dínkù láti ìgbà tí Otti ti di gómìnà.
Eléyìí túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ tí Rochas sọ pé owó tí Otti yá láàrin ọdún kan tí ó di gómìnà ju gbogbo àpapọ̀ owó tí àwọn tí wọ́n ti ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ náà yá kì í ṣe òótọ́.
Ọ̀rọ̀ tí Rochas tún sọ pé mílíọ̀nù mẹsan náírà ni Otti ń nọ́ lórí oúnjẹ lojoojumọ kì í ṣe òtítọ́ tí a bá wo owó ìsúná ọdún 2024.