Fọ́nrán kan tó ṣe àfihàn owó náírà ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rún márùn ni wọ́n ṣ’atunpin ní orí ayélujára.
Nínú fọ́nrán yìí ti wọ́n ṣ’atunpin sí orí ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter) l’ọ́jọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣù kẹwa, a rí obìnrin kan tó ń ṣàfihàn ọ̀pọ̀lopọ̀ owó ti wọ́n tẹ N5,000 (ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà) àti N2,000 (ẹgbẹ̀rún méjì náírà) sí lára.
I hope this is a joke . pic.twitter.com/p8GM6YS1pA
— Dr Penking™🇳🇬🇦🇺 (@drpenking) October 27, 2022
Obìnrin tí a kò mọ orúkọ rẹ̀ yìí, sọ pé ọkùnrin ‘wèrè’ kan ló gbé owó náà wá sí ilé ìfowópamọ́ tí òun tí ń ṣiṣẹ́.
“Mo ní ìgbàgbọ́ pé àwàdà leleyii,” àkòrí yìí ni ènìyàn kan kọ sí ojú òpó rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ṣ’atunpin fídíò náà. Àwọn olùmúlò ojú òpó wo fọ́nrán náà ní ìgbà ẹgbẹ̀rún mẹtalelọgbọn. Wọ́n sì bu ọwọ́ ìfẹ lùú ní ọna ẹgbẹ̀rún lé ní mejidinlọgbọn. Àwọn aṣàmúlò ìkànnì náà ṣ’atunpin fọ́nrán náà ní ìgbà ọdunrun lé ní ẹẹtadinlaadọrin.
Wọ́n ṣ’atunpin fọ́nrán náà sí orí ìkànnì tí àwọn ènìyàn ti lé pín àwòrán ara wọn (Instagram), ó sì wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú òpó l’órí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ (Facebook), ọpọlọpọ àwọn ènìyàn tí kò fura sì ti fi èròngbà wọn hàn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣù kẹwàá, ọdún yii, Godwin Emefiele, Gómìnà banki àpapọ̀ orilẹ-ede Nàìjíríà sọ pé bánkì náà ti kéde pé yóò tẹ owó tuntun.
Emefiele ni owó tí bánkì náà ma tẹjade ni N200 (ìgbà náírà), N500 (ẹẹdẹgbẹta náírà) ati N1000 (ẹgbẹ̀rún náírà). Wọn yóò sì bẹ̀rẹ̀ síí kó owó náà jáde ní oṣù Kejìlá, ọdún yìí.
Gómìnà bánkì àpapọ̀ náà ṣàlàyé pé ìṣòro nípa ìṣàkóso ìṣúná owó orilẹ-ede yìí lo fàá tí bánkì ọ̀ún fi ṣe ìpinnu láti ṣe atuntẹ owó.
Iṣaridaju
TheCable lo Invid, irinṣẹ ìgbàlódé tí a fi ń ṣe ìwòye fọ́nrán lórí ayélujára. Ìwádìí wà fihàn pé fọ́nrán náà ti wà lórí ayélujára pàápàá lórí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ ati ìkànnì tí a ti ń wo àwòrán (YouTube) láti ọdún 2020.
A ríi wí pé àwòrán ọkùnrin kan tí ó wọ fìlà, wà ní apá kan owó pépà N5000 (ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà) ọun, àwòrán obìnrin mẹta wà ní apá kejì.
Ìwádìí wà fihàn pé ni ọdún 2012, bánkì àpapọ̀ orilẹ-ede Nàìjíríà kéde pé wọn yóò gbé owó náírà ẹgbẹ̀rún márùn jáde.
Sanusi Lamido, tí ó jẹ́ gómìnà bánkì àpapọ̀ nígbà náà, sọ pé àwòrán obìnrin mẹ́ta ni wọn yóò tẹ sára owó náírà náà. Àwọn obìnrin náà ni Ajijagbara Margaret Ekpo, olóṣèlú tó ti ṣe aláìsí; Hajia Gambo Sawaba, ajijagbara àti olóṣèlú tó ti ṣe aláìsí àti Funmilayo Kuti, olóṣèlú àti ẹni tí máa n já fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ní ìgbà ayé rẹ̀.
Lamido ṣàlàyé pé àtẹ̀jáde owó pépà náà yóò ṣe iranlọwọ fún owó náírà, a máa ṣe iranlọwọ fún àwọn tí kò riran dáadáa, yóò sì mú idinku ba ìdíyelé ṣíṣe atẹjade, pínpín àti kikokuronilẹ owó náírà.
Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lo tako ìpinnu yìí. Àjọ fún àwọn tí ó mọ nípa ìṣirò owó (Institute of Chartered Accountants of Nigeria-ICAN) sọ nígbà náà pé ṣíṣe àgbéjáde owó pépà ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà yóò mú ifasẹyin bá owó náírà.
Ìjọba àpapọ̀ ṣe ìdádúró ṣíṣe àgbéjáde owó pépà ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà náà láti jẹ́ kí “bánkì àpapọ̀ Nàìjíríà tan imọlẹ si ọrọ náà.”
Ní ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù Kàrún, ọdún 2020, bánkì àpapọ̀ Nàìjíríà kéde lori ìkànnì abẹ́yẹfò pé kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà má ṣe àkíyèsí àwòrán àti fọ́nrán èké tí àwọn ènìyàn kan ń pín káàkiri orí ayélujára nígbà náà.
“Ayédèrú fídíò àti àwòrán owó pépà ẹgbẹ̀rún méjì àti márùn náírà ni àwọn ènìyàn kan pín káàkiri orí ayélujára. Kí àwùjọ ẹ̀dá ma ṣe àkíyèsí àwọn ìròyìn èké yìí. Tí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni tí ó ní owó náà lọ́wọ́, ẹ fi èyí tó àwọn ẹṣọ aláàbò létí,” èyí ní ọ̀rọ̀ ìwòye tí CBN kọ sí ojú òpó abẹ́yẹfò rẹ̀.
Videos and pictures of purported circulation of N2,000:00 and N5,000:00 banknotes are false and fake. Members of the public are advised to disregard such falsehood and to report anyone found in possession of such banknotes to the law enforcement agencies
— Central Bank of Nigeria (@cenbank) May 31, 2020
Fọ́nrán àtijọ́ náà ni àwọn ènìyàn pin káàkiri ayélujára lásìkò yìí ṣáájú àsìkò ti bánkì àpapọ̀ máa gbé owó náírà tuntun jáde ní oṣù Kejìlá, ọdún yìí.
Àmọ̀ṣá, bánkì àpapọ̀ nínú ìkéde rẹ̀ ṣàlàyé pé àwọn owó tí wọn yóò ṣe atuntẹ rẹ̀ ní N200, N500 ati N1000, bánkì àpapọ̀ náà kò kéde owó náírà ẹgbẹ̀rún méjì tàbí márùn kankan.
Àbájáde Ìwádìí
Ayédèrú ni fọ́nrán tí a pín kalekako tí ó gbé àhesọ pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ ṣe àgbéjáde owó pépà ẹgbẹ̀rún méjì àti márùún náírà. Asinilọna ni fídíò náà, ó ti wà lórí ayélujára láti ọdún 2020.