Fídíò kan lórí Tiktok tí sọ pé ìjọba ti dá Orlu, Ìpínlẹ̀ tuntun ṣílẹ̀ ní àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Àwọn ènìyàn ti wo Fídíò ìṣẹ́jú mẹ́rin yìí tí wọ́n ṣe ní èdè ígbò ní ìgbà ookanleniẹgbẹ̀rún. Àwọn ènìyàn ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti mẹ́tadínniọgọ́ta. Àwọn ènìyàn sì pín ọ̀rọ̀ náà ní ìgbà ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín ní mọkanla.
Gẹ́gẹ́bí Fídíò yìí tí @amarachi fi síta ṣe wí, Ìpínlẹ̀ mẹ́tadínniogoji ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní nísìnyí. Ìpínlẹ̀ mẹrindinlogoji ni a ní tẹ́lẹ̀.
Ó sọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn Ìpínlẹ̀ tí wọn yọ Ìpínlẹ̀ Orlu náà ní ara wọn.
“Ǹjẹ́ ẹ̀yin ènìyàn mọ nnkan tó ń lọ? Ìròyìn tí ó sọ pé ìwé òfin kan ti dá Ìpínlẹ̀ kan sílẹ̀ ní ọjọ́ méjì sẹhin sọ pé Ìpínlẹ̀ tó wà ní Nàìjíríà ti di mẹtadinlogoji dípò mẹrindinlogoji tí a ní tẹ́lẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé a ti ní ìpínlẹ̀ tuntun. Fún àwọn tí kò gbọ́ èdè oyinbo, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí fun yín. Wọ́n ti dá Ìpínlẹ̀ tuntun kan tí a mọ̀ sí Ìpínlẹ̀ Orlu ṣílẹ̀,” arábìnrin yìí ló sọ báyìí.
“Wọ́n dáa sílẹ̀ láti ara Ìpínlẹ̀ Abia, Imo àti Anambra, wọ́n sì pèé ní Ìpínlẹ̀ Orlu.
“Tí o bá jẹ́ ọmọ Anambra, wòó bóyá o ti di ọmọ Ìpínlẹ̀ tuntun yìí. Màá dá orúkọ àwọn ibi tí wọ́n kó pọ̀ tí wọ́n sọ di Ìpínlẹ̀ tuntun naa, ẹ kìí ṣe ọmọ Ìpínlẹ̀ Anambra mọ́, ọmọ Ìpínlẹ̀ Orlu ni yín.
Tí o bá jẹ́ ọmọ Ihiala, Uli, Ozubulu, Akokwa, Umuchu, Umunze, Umuaku, Nwangele, Nkwere, New Ideato North, Nwabosi West, Alaoma, Owerrebiri, Oguta, Isu, Arondizuogu, Ideato North, Ideato South, Njaba, Oru East, Orsu, mọ̀ pé o ti di ọmọ Ìpínlẹ̀ Orlu.
Àwọn ènìyàn pín ọ̀rọ̀ yìí lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise alámì krọọsi (X) tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀ àti ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ (Facebook).
ǸJẸ́ WỌ́N TÍ DÁ ÌPÍNLẸ̀ ORLU ṢÍLẸ̀ NÍ SOUTHEAST?
Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà, ọdún 2024, àwọn asojusofin ká ìwé tó lè di òfin ní ìgbà àkọ́kọ́ ní ilé igbimọ asofin (house of representatives).
Ikenga Ugochinyere, ọmọ ilé igbimọ asofin tí o ń sójú agbègbè tí a mọ̀ sí Ideato north àti Ideato south federal constituency ló fẹ́ kí ìjọba dá Ìpínlẹ̀ Orlu náà ṣílẹ̀.
Ó ní ìjọba yóò yọ Ìpínlẹ̀ tuntun náà láti ara Ìpínlẹ̀ Anambra, Imo àti Abia.
Ní àwọn ibi mẹ́fà tí wọ́n pín Nàìjíríà sí, southeast nìkan ni ó ní Ìpínlẹ̀ márùn-ún, àwọn kan ní Ìpínlẹ̀ mẹ́fà, ibi kan tí a mọ̀ sí northwest sì ní Ìpínlẹ̀ méje.
Gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè tí ó ní ilé igbimọ asofin méjì, ìwé tí ó lè di òfin gbọ́dọ̀ dè iwájú ilé igbimọ asofin méjèèjì-senate àti house of representatives tí Nàìjíríà ní, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ síi kí ó tó di òfin.
Ìgbà mẹta ni àwọn ilé asofin méjèèjì gbọ́dọ̀ jíròrò lori Ìwé tí ó lè di òfin, tí àwọn ènìyàn ní àwùjọ sí gbọ́dọ̀ dá síi kí àwọn asofin tó fi ontẹ tẹẹ tàbí sọ pé àwọn kò lọ́wọ́ si.
Lẹ́hìn ìgbà tí ilé asofin méjèèjì bá ti lọ́wọ́ sí, wọ́n yóò fi ránṣẹ́ sí Ààrẹ láti bu ọwọ́ lùú.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Irọ́ ni ọ̀rọ̀ tó sọ pé wọ́n ti dá Ìpínlẹ̀ Orlu ṣílẹ̀ ní southeast.