Àwọn àtẹ̀jáde orí ayélujára gbé aheso kan pé aya olóògbé Temitope Joshua, gbajumọ oniwaasu ati wolii, ṣe ìlérí ìbò mílíọ̀nù mẹjọ fún Peter Obi, olùdíje sí ipò ààrẹ l’abẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn òṣìṣẹ́, Labour Party.
Nínú òun àmúlò ìgbàlódé aláwòrán (YouTube) tí News Express Nigeria TV gbé jáde ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù keje, ọdún 2022, a rí wí pé Arábìnrin Evelyn ṣe àtìlẹ́yìn fún Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ náà nínú ìbò fún Ipò Ààrẹ ni ọdún 2023.
Àgbéjáde tí àkọle rẹ jẹ́: “Ìbò fún Ipò Ààrẹ ti ọdún 2023: Evelyn T.B. Joshua ṣe ìlérí ìbò miliọnu mẹ́jọ fún Peter Obi” ni a wo ni ìgbà ẹẹdẹgbẹta lè ní ogún àti mẹwa.
Àgbéjáde yìí tún wà ní ojú òpó ibaraẹnisọrẹ ẹni kan tí a mọ sí Nolly Roll tí ó ní àwọn alátilẹ́yìn/olùtẹ̀lé miliọnu mẹ́ta.
Àwọn ènìyàn bù ọwọ ìfẹ́ràn tí ó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá lú, wọn si fèsì ni ìgbà egbèje dín ní ọgọ́rùn-ún pẹ̀lú ìṣàtúnpín ní ọ̀nà ẹẹdẹgbẹrin lé ní ogún àti mẹrin.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn òun àmúlò ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ tí wọn ṣe atunpin atẹjade náà ni àpèjúwe/àkòrí tí ó jọ ara wọn pẹ̀lú àwòrán olóògbé T.B. Joshua tàbí ti ìyàwó rẹ tàbí akojọpọ fọ́tò àwọn méjèèjì.
“Èmi yóò jẹ́ kí Peter Obi ní ìbò miliọnu mẹ́jọ ní sọọsi (ìjọ) mi. Èmi kìí se àtìlẹ́yìn àwọn olóṣèlú tàbí fọwọ́sí idije òṣèlú tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, Peter Obi jẹ́ ènìyàn tí a kò gbọdọ̀ kó ìyàn rẹ kéré. Ènìyàn pàtàkì ni. Ìdàgbàsókè yóò débá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó bá di Ààrẹ”, báyìí ni atẹjade tí a rí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú òpó ibaraẹnise ṣe wí.
Isaridaju
Ìwé Ìròyìn TheCable kan sí ìjọ Synagogue láti lè mọ ìdáhùn ojisẹ Ọlọ́run Evelyn tàbí àwọn adarí-ìjọ náà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Wọn kò dá wa lóhùn. A kò rí wọn bá sọ̀rọ̀ lẹ́hìn náà.
A ṣàyẹ̀wò òun àmúlò ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ ti ìjọ náà àti ti oludasilẹ sọọsi yìí lẹ́hìn tí a kàn sí wọn.
Ní ọjọ́ kẹdogun, oṣù keje, ọdún 2022, a rí atẹjade kan ni ojú òun àmúlò ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ àti èyí tí a fí ń pín fọ́tò/àwòrán tí ó ní àmì ibuwọlu ti T.B. Joshua Ministries tí ó sọ wí pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run Evelyn sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ólùdíje fún Ipò òṣèlú kan yóò ṣe aseyege nínú ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2023.
Atẹjade náà sọ pé: “a rí wí pé orisirisi atẹjade òun àmúlò ìgbàlódé ibaraẹnise pa irọ pé Ojisẹ Ọlọ́run Evelyn Joshua tí sọ àsọtẹ́lẹ̀ àṣeyọrí Ólùdíje kan nínú ibo àpapọ̀ ọdún 2023. Ẹ jọ̀wọ́ má ṣe ka ọ̀rọ̀ náà sí nítorí wí pé Pasitọ Evelyn kò sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ báyìí. A tún fẹ́ fi ye yín pé orí ẹ̀rọ amohunmaworan tí a mọ sí Emmanuel Tv àti ojú òpó òun amulo ìgbàlódé ibaraẹnise tí Synagogue ni a ti máa ń ṣe àgbéjáde ọ̀rọ̀ tí ó bá wà láti ọwọ ìjọ wa.
Nínú àyẹ̀wò ojú òpó òun àmúlò ìgbàlódé ibaraẹnise tí T.B. Joshua Ministries, a rí wí pé àwọn ènìyàn pín atẹjade kan náà ní ogunjọ, oṣù kẹfà, ọdún yìí.
Sibẹsibẹ, kò sí esi/ìdáhùn kankan nípa ìbò miliọnu mẹ́jọ fún Obi. TheCable kàn sí Julius Abure, ẹni tí ó jẹ asiwaju fún ẹgbẹ́ òsèlú àwọn osisẹ (Labor Party) ni gbogbo ilẹ̀ Nàìjíríà.
Ó sọ wí pé “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní wọn ń ṣe àtìlẹ́yìn fún Peter Obi ni orisirisi ọ̀nà. A kò lòdì sí iranlọwọ gidi.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fẹ́ àyípadà tí ó dára.”
Ìdáhùn ọ̀rọ̀ rẹ nípa ìlérí ìbò miliọnu mẹ́jọ ni pé “ìjọ Synagogue kò kàn sí/bá ẹgbẹ́ òsèlú àwọn osisẹ tàbí Peter Obi sọ̀rọ̀ ni ọ̀nà kankan.
Esi àyẹ̀wò
Irọ gba ni atẹjade/ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé Ojisẹ Ọlọ́run Evelyn ṣe ìlérí pé òun yóò ṣe ọna bí Peter Obi, Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò ṣe ni ìbò miliọnu mẹ́jọ.
A ṣe àgbéjáde ìròyìn yìí pẹ̀lú ajọṣepọ àjọ tí ó ń ṣe eto ìròyìn agbaye fún àwùjọ.