Àwọn ènìyàn tí ń pín fídíò kan tí ó se àfihàn ibi tí àwọn jàgídíjàgan ti se àfihàn àwọn owó tí wọ́n dì ní beeli, beeli, tí àwọn ènìyàn sọ pé ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Nínú fídíò tí ó kù díẹ̀ kí ó pé ìṣẹ́jú méjì yìí, obìnrin kan ń sọ̀rọ̀ ní abẹlẹ. Ó sọ pé àwọn olórí ní Nàìjíríà mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí. “Ó ti tán fún Nàìjíríà,” obìnrin yìí ló sọ báyìí.
“Àwọn ènìyàn wo ló ń ṣe atilẹyin fún àwọn jàgídíjàgan yìí?” Obìnrin yìí sọ pé àwọn jàgídíjàgan yìí ní àǹfààní ju àwọn ọmọ Nàìjíríà, èyí tí ó jẹ́ kí wọ́n máa dáràn láìsí ohun kankan tí ó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìwà wọn yìí.
“Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, kí ló ń ṣẹlẹ̀? Ìjọba Tinubu, kí ló ń ṣẹlẹ̀? “Níbo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀?”, àwọn ìbéèrè yìí ni obìnrin yìí bèèrè lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise ayélujára (social media). Àwọn ènìyàn pín fídíò yìí lórí WhatsApp, ohun ìgbàlódé ibaraẹnise, tí àwọn ènìyàn fi máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.
CableCheck ríi pé wọ́n fi fídíò yìí sí orí YouTube, ibi ìgbàlódé orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi fídíò tàbí àwòrán síta.
Àwọn ènìyàn fèsì sí ọ̀rọ̀ yìí ní ìgbà mẹtalelogun. Àwọn ènìyàn tí wọ́n ju ìdajì àwọn ènìyàn tí wọ́n fèsì sí ọ̀rọ̀ yìí ni wọn sọ pé Nàìjíríà ni ọ̀rọ̀ yìí tí ṣẹlẹ̀. Àwọn ènìyàn tí wọ́n dá sí ọ̀rọ̀ yìí sì béèrè bóyá àwọn elétò àbò ìjọba àpapọ̀ tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Department of State Services (DSS) mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rin dín ní méjìdínlógún ló ti rí/wo fídíò yìí. Àwọn ènìyàn marunlelaadọta ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí. Nínú fídíò kan míràn tí àwọn ènìyàn fi síta ní orí Instagram, ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán síta, ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù karùn-ún, ọdún 2025, Olamisharp, ọmọ Nàìjíríà kan tí ó máa ń fi nkan síta lórí ayélujára, fi fídíò nípa àwọn jàgídíjàgan yìí síta lórí ayélujára, ó sì sọ pé ìjọba Nàìjíríà kò gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ.
“Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀ èdè tí àwọn ajunilọ ti máa ń se àfihàn ohun ìní wọn láti ṣe karími,” àkòrí ọ̀rọ̀ Olamisharp nìyí fún àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjìlélógún àti irínwó tí wọ́n ń tẹ̀lée lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise ayélujára. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀ta ló ti wo/rí fídíò tí Olamisharp fi síta yìí.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck se àyẹ̀wò fídíò tí Olamisharp fi síta yìí nípa lílo reverse image. A rí fídíò yìí kan náà tí àwọn ènìyàn fi síta lórí Facebook, ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ orí ayélujára, ní ọjọ́ kẹrindinlogun, oṣù Kejìlá, ọdún 2024.
Ninu fídíò yìí, a gbọ ohùn ọkùnrin kan tí ó ń sọ̀rọ̀ ní èdè arabiki (Arabic Language). CableCheck túmọ̀ àkòrí yìí nípa lílo Google Translate. “Wo fídíò tí ó se àkójọ bí àwọn ọmọ afagbara gba nnkan, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn AI-Dagalo, se ń jí nǹkan ní àwọn ilé ifowopamọ àti àwọn ọjà,” báyìí ni àkòrí fídíò yìí tí wọ́n kọ ní èdè arabiki se wí. “A máa ń sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Dagalo máa ń jí nǹkan, wọ́n sì tún máa ń ba nnkan jẹ́,” báyìí ni fídíò yìí tún ṣe wí. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ẹgbẹ̀ta ló ti rí/wo fídíò yìí.
Nínú fídíò yìí, àwọn ènìyàn tí wọ́n wọ aṣọ bíi ti àwọn ọmọ isẹ ológun ń ṣe àfihàn owó tí wọ́n dì ní beeli, beeli (bundles of money) nínú àpò àti ọkọ̀. Ara àwọn owó yìí wà ní ilẹ̀. CableCheck se àkíyèsí pé owó yìí kìí se owó náírà, èyí tí ó jẹ́ owó tí wọ́n ń nọ ní Nàìjíríà.
Gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí ṣe wí, fídíò yìí ṣe àfihàn àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sisẹ fún Sudan’s Rapid Support Forces (RSF), àwọn tí ìsẹ wọn jọ ti àwọn òṣìṣẹ́ ológun, tí inú wọn kò dùn, lẹ́hìn ìgbà tí orílẹ̀ èdè Sudan sọ pé àwọn yóò yí owó tí àwọn ènìyàn ń ńọ ní Sudan pada sì owó/kọrẹnsi (currency) mìíràn.
RSF, èyí tí Mohammed Dagalo jẹ́ olórí wọn, ti ń jà láti gba ìjọba, èyí tí ó jẹ́ kí wọ́n ma dojú ìjà kọ àwọn òṣìṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè náà. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí jẹ́ kí àwọn ènìyàn pàdánù ẹ̀mí àti ibùgbé wọn.
Àwọn ènìyàn ti fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sisẹ pẹ̀lú RSF. Ní oṣù kọkànlá, ọdún 2024, Sudan’s Central Bank, ilé ifowopamọ ìjọba àpapọ̀ Sudan kéde owó titun. Ilé ifowopamọ yìí sọ pé àwọn se nnkan yìí láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn sí akanti tí wọ́n ma máa fi owó pamọ sí (open bank accounts). Wọn tún sọ pé àwọn se nnkan yìí láti dín owó jíjí kù. RSF sọ pé àwọn nnkan yìí kò dára. Ọ̀rọ̀ tí RSF sọ yìí jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa rò pé àwọn nǹkan òsèlú tí kò dára lè máa lọ ní abẹlẹ.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Kìí se Nàìjíríà ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀.