TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Kọ́lá Abiola ní igbimọ fún ààbò ni Nàìjíríà kò jókòó láti 1999. Ṣé òtítọ́ ni?
Share
Latest News
FACT CHECK: Did Nigerian army use old pictures for recent rescue operation?
FACT CHECK: Tinubu’s speech on Trump’s tariff misrepresented as recent comment on US watchlist
Claim wey tok sey FIFA give Kenya $1.2m to build Talanta stadium no correct
Ókwụ́ nà FIFA jị́rị́ $1.2m rụ́ọ́ stadium Talanta nké Kenya bụ̀ ásị́
Irọ́ ni pé mílíọ̀nù kan àti igba dọ́là ni wọ́n fi kọ́ pápá ìṣeré Talanta ní Kenya, FIFA kọ ló sì kọ́ọ
Da’awar cewa filin wasa na Talanta na Kenya ya ci $1.2m, wanda FIFA ta gina karya ne
DISINFO ALERT: Man in viral image NOT chairman of reps’ youth committee
Kebbi deny video wey claim sey ‘secret airport dey Argungu for cocaine trafficking’
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Kọ́lá Abiola ní igbimọ fún ààbò ni Nàìjíríà kò jókòó láti 1999. Ṣé òtítọ́ ni?

Elizabeth Ogunbamowo
By Elizabeth Ogunbamowo Published November 18, 2022 5 Min Read
Share

Kọ́lá Abíọ́lá, olùdíje fún ipò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Redemption Party (PRP), sọ láìpẹ́ yìí pé igbimọ tó ń ṣojú ètò àbò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (National Security Council) kò tíì ní ìpàdé kankan láti ọdún 1999.

Abiola sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ibi ifiọ̀rọ̀wálẹ́nuwò ìta gbangba àwọn Ólùdíje fún ipò ààrẹ tí àjọ kan tó ń polongo ìjọba àwa-ara-wa àti ìdàgbàsókè, Centre for Democracy and Development (CDD), ṣètò pẹ̀lú ajọṣepọ ilé-isẹ iroyin Arise News ní Abuja, olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Abiola jẹ́ ìkan nínú àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ mẹ́rin tí wọn pésẹ̀ sí ibi àpéjọ náà ní ọjọ́ àìkú.

Àwọn olùdíje mẹ́ta míràn tó wà ní ibi ifiọ̀rọ̀wálẹ́nuwo ọ̀ún ni Peter Obi, olùdíje fún ipò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labour Party), Rabiu Kwankwaso, tí ó jẹ ti ẹgbẹ́ ́òṣèlú New Nigeria Peoples Party (NNPP) àti Ifeanyi Okowa, igbá-kejì Atiku Abubakar, tí ó jẹ olùdíje fún ipò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP).

Gbogbo àwọn olùdíje náà ló sọ̀rọ̀ nípa ètò ààbò ati ọrọ ajé tí wọn yóò gbekalẹ ti won bá dé ipò ààrẹ.

Nínú ifọrọwaniẹnuwo náà, Reuben Abati, olóòtú ètò náà bèrè lọ́wọ́ àwọn olùdíje ìgbésẹ tí wọ́n yóò gbé, bí wọ́n bá jẹ ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìgbà tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ akọlu tireni  tí ó rin ní ojú irin Kaduna sí Abuja ní oṣù kẹta, ọdún 2022 bá ṣẹlẹ̀.

Abiola f’èsì pé igbimọ tó ṣojú ètò àbò l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà ò tíì jókòó láti ọdún 1999.

“Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yìí jẹ́ ọ̀kan nínú ìdojúkọ orílẹ̀-èdè yìí ní ti ètò ààbò láti ọdún tó ti pẹ. A ní láti s’agbeyẹwo ètò ààbò wa lórílẹ̀ èdè yìí.

“Bí ọdún ti ń gorí ọdún,  ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ lati sọ nípa ètò ààbò ṣùgbọ́n ṣé oun tó kàn ní èyí? Lati ọdún 1999, igbimọ tó ń ṣojú ètò àbò l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò tíì jókòó láti ọdún 1999,” Abiola ló sọ báyìí.

Isewadi

TheCable ṣe agbeyẹwo abala ẹtalelaadọjọ, apá kẹdọgbọn ti ìwé òfin ọdún 1999 (section 153, subsection 25 of the 1999 constitution) tí ó se agbekalẹ àwọn tí yóò wà ní ìgbìmọ̀ ọ̀ún.

“Igbimọ tó ṣojú ètò àbò l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbọ́dọ̀ ní: (a) ààrẹ orílẹ̀-èdè tí ó jẹ alága ìjókòó náà; (b) igbá-kejì ààrẹ tí yóò jẹ igbá-kejì alága;  (c) ọgagun òṣìṣẹ́ lórí ètò ààbò orílẹ̀-èdè (d) mínísítà nípa ọ̀rọ̀ ìlú (e) mínísítà nípa ètò ààbò (f) Mínísítà fún ọrọ ilẹ òkèèrè (g) oludamọran ààrẹ lórí ètò ààbò (h) ọga pátápátá fún àwọn Ọlọpa àti (i) ẹnikẹ́ni tí ààrẹ bá yàn.”

Apá  kẹrindinlọgbọn f’ikun-un wí pé ètò igbimọ náà ní láti gba ààrẹ ní ìmọ̀ràn lórí ètò ààbò “àti àwọn ọ̀rọ̀ míràn tó nííse pẹ̀lú àwọn Ilé isẹ tí òfin gbé kalẹ̀ fún ètò ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”

Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹwa ọdún yìí, TheCable gbé ìròyìn pé ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe Ìpàdé pẹ̀lú igbimọ tó ń ṣojú ètò ààbò nì ìlú Abuja.

Àwọn míràn tó pesẹ si ibi Ìpàdé náà ni ìgbákeji ààrẹ, Yemi Osinbajo, Boss Mustapha, akọ̀wé àgbà fún ìjọba àpapọ̀, Babagana Monguno, olùdámọ̀ràn ààrẹ Buhari lórí ètò ààbò àti Ibrahim Gambari, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà.

Àwọn mínísítà míràn tí ó wà nibẹ ni Bashir Magashi, mínísítà nípa ètò ààbò, Rauf Aregbesola, mínísítà tó ń rí sí ọrọ abẹle àti Maigari Dingyadi, mínísítà fún ọrọ àwọn ọlọpa. Gbogbo àwọn olórí òṣìṣẹ́ ìjọba àti olórí àwọn ẹṣọ alaabo ló péjú sí ibi àpéjọ náà.

Ní ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù kẹwa ọdún 2022, ìròyìn tàn pé ààrẹ Buhari pe fún ìjokòó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ igbimọ aṣoju ètò ààbò.

Ìpàdé náà wáyé ni ilu Abuja láti ṣe agbeyẹwo lẹkunrẹrẹ àti láti fí okun kún agbára fún àwọn ẹṣọ aláàbò ni Orílẹ̀-èdè yìí.

Àbájáde ìwádìí

Ìrọ́ gbàá ni ọrọ tí Abiola sọ pé igbimọ aṣojú ètò ààbò ní orílẹ̀-èdè yìí ko jókòó/ṣe ìpàdé láti ọdún 1999. Ààrẹ Buhari pe ìpàdé igbimọ náà laipẹ yìí.

TAGGED: Arise Town Hall Meeting, Kola Abiola, PRP

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Elizabeth Ogunbamowo November 18, 2022 November 18, 2022
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

FACT CHECK: Did Nigerian army use old pictures for recent rescue operation?

On Monday, the Nigerian army published a statement alongside some pictures across its official social…

November 4, 2025

FACT CHECK: Tinubu’s speech on Trump’s tariff misrepresented as recent comment on US watchlist

On Sunday, a website — Politics Nigeria — published a 25-second video on Facebook wherein…

November 4, 2025

Claim wey tok sey FIFA give Kenya $1.2m to build Talanta stadium no correct

On October 26, Dino Melaye claim sey FIFA give Nigeria and Kenya $1.2 million to…

October 31, 2025

Ókwụ́ nà FIFA jị́rị́ $1.2m rụ́ọ́ stadium Talanta nké Kenya bụ̀ ásị́

N'ụbọchị iri abụọ n'isii nke ọnwa Ọktoba, Dino Melaye kwụrụ na FIFA nyere Naijiria na…

October 31, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Claim wey tok sey FIFA give Kenya $1.2m to build Talanta stadium no correct

On October 26, Dino Melaye claim sey FIFA give Nigeria and Kenya $1.2 million to build stadiums for dia kontris. …

CHECK AM FOR WAZOBIA
October 31, 2025

Ókwụ́ nà FIFA jị́rị́ $1.2m rụ́ọ́ stadium Talanta nké Kenya bụ̀ ásị́

N'ụbọchị iri abụọ n'isii nke ọnwa Ọktoba, Dino Melaye kwụrụ na FIFA nyere Naijiria na Kenya otu nde Dollar na…

CHECK AM FOR WAZOBIA
October 31, 2025

Irọ́ ni pé mílíọ̀nù kan àti igba dọ́là ni wọ́n fi kọ́ pápá ìṣeré Talanta ní Kenya, FIFA kọ ló sì kọ́ọ

Ní ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, osù kẹwàá, ọdún 2025, Dino Melaye sọ pé FIFA fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Kenya ní mílíọ̀nù…

CHECK AM FOR WAZOBIA
October 31, 2025

Da’awar cewa filin wasa na Talanta na Kenya ya ci $1.2m, wanda FIFA ta gina karya ne

A ranar 26 ga watan Oktoba, Dino Melaye ya yi ikirarin cewa FIFA ta baiwa Najeriya da Kenya dala miliyan…

CHECK AM FOR WAZOBIA
October 31, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?