Àwọn ènìyàn kan ti sọ pé Nàìjíríà ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ni fídíò kan tó se àfihàn òkú àwọn ènìyàn kan tí ó dàbí ẹni pé wọ́n wà nínú kòtò kan náà ti ṣẹlẹ̀.
Ní ọgbọ́n ọjọ́, oṣù kẹjọ, ọdún 2024, ẹni kan tí ó ń jẹ́ @emmasocket tí ó ń lo ohun ìgbàlódé ibaraẹnise alámì krọọsi (X) tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀ fi fídíò kan síta tí ó se àfihàn àwọn ọkùnrin tí wọ́n wọ aṣọ ológun tí wọ́n sì ń yin ìbọn fún àwọn ènìyàn tó ń sá lọ.
Ibi tí wọ́n ti fi fídíò yìí síta ní àwòrán Simon Ekpa, ẹni tí ó ń ṣe àtìlẹ́yìn fún Nnamdi Kanu, ẹni tí ìjọba àpapọ̀ tì mọ́lé nítorí pé ó jẹ́ olórí àwọn ènìyàn kan tí a mọ̀ sí Indigenous People of Biafra (IPOB).
Nínú fídíò yìí, èyí tí ó dàbí pé wọ́n yà ní ibi tí àwọn ènìyàn kò gbé, a rí àwọn ìgò tí àwọn ènìyàn dà sí inú kòtò.
“Ẹ jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ogun abẹle tó ń lọ ní ilẹ̀ Biafra,” báyìí ni ọ̀rọ̀ orí X yìí ṣe wí.
“A kò lè gba èyí mọ. Ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tí ó wà ní pé kí a pín Nàìjíríà. Gbogbo àwọn ọmọ BIAFRA ní gbogbo àgbáyé, @simon_ekpa àti àwọn tí wọ́n ń ṣe ìṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ wà níbí pẹ̀lú wá.”
Nígbà tí à ń kọ ìròyìn yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ló ti wo fídíò yìí, àwọn ènìyàn ti fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí ní ìgbà àádọ́rin ó dín mẹ́rin, àwọn ènìyàn pín in nígbà ọgọ́ta.
Ní ọjọ́ kọkandinlọgbọn, oṣù kẹjọ, ọdún 2024, ènìyàn kan tí a mọ̀ sí @Amadioha0d3671 tí ó ní àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n ń tẹ̀lée fi fídíò náà síta. Ó sọ pé “Kìí se pé wọ́n fẹ́ sọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà di ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́. Ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe gangan ni pé wọ́n fẹ́ gba ilẹ̀ pẹ̀lú tipátipá, wọ́n sì fẹ́ kí àwọn fulani àti àwọn ènìyàn mìíràn láti àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ funfun darí Nàìjíríà pẹ̀lú túláàsì.”
Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀rọ̀ yìí kò sọ ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ń sọ̀rọ̀ nipa ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn fi síta tẹ́lẹ̀ ṣe àfihàn pé ẹ̀sìn Ààrẹ àti igbakeji rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà àtisọ àwọn ọmọ Nàìjíríà di ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí.
Àwọn ènìyàn ti wo/rí fídíò yìí ní ìgba ẹgbẹ̀rún mejidinlaadọta àti ọọdunrun, wọ́n pín ín ní ọ̀nà ẹgbẹrin àti mọkandinlogun, wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀ta àti mẹtadinlọgbọn. Àwọn ènìyàn fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí ní ìgbà ọgọ́rùn-ún. Wọ́n fi pamọ nígbà ọgọ́rùn-ún.
Ṣé Nàìjíríà ni wọ́n ti pa àwọn ènìyàn púpọ̀ yii?
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
Láti lè mọ ìgbà tí fídíò yìí jáde, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára se àyẹ̀wò rẹ̀ pẹ̀lú Google reverse image search.
A ríi pé ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi fídíò yìí síta ni ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣù kẹjọ, ọdún 2024.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tó bá fídíò yìí jáde se wí, Jama’at Nustrat al-Islam wal Muslimeen (JNIM), ẹgbẹ́ kan tí ó ń bá Al-Qaeda se ló pa wọ́n ní orílẹ̀-èdè Burkina Faso.
Ọ̀rọ̀ yìí sọ pé JNIM pa àwọn ènìyàn tí wọ́n lé ní ìgbà, wọ́n sì se àwọn ènìyàn ogóje lése. Àwọn ará abúlé ń bá àwọn òṣìṣẹ́ ológun gbẹ ilẹ̀ tí wọ́n lè sá pamọ sí.
Àwọn nǹkan kan tí kìí se ènìyàn pín fídíò yìí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan náà.
Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹjọ, ọdún 2024, aṣèwádìí kan tí wọ́n ń pè ní War Noir, ẹni tí ó máa ń se ìwádìí nípa ohun idabobo àti rògbòdìyàn fi fídíò náà síta. Ó sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní Burkinabe ní ibì kan tí wọ́n ń pè ní Barsalogho.
Ìròyìn kan sọ àrídájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, ọdún 2024. Àwọn obìnrin àti ọmọdé wà lára àwọn tó ṣẹlẹ̀ sí.
Àjọ àgbáyé tí a mọ̀ sí United Nations (UN) sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí burú gidi. Àjọ yìí bẹ àwọn olórí ìjọba ní Burkina Faso pé kí wọ́n ríi pé ọwọ wọ́n tẹ àwọn ọ̀daràn yìí.
Edward Buba, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìfìròyìntónilétí fún àwọn òṣìṣẹ́ ológun sọ ọ̀rọ̀ ní ọjọ́ ajé pé Nàìjíríà kò mọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
“Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní Burkina Faso, orílẹ̀-èdè kan tí àwọn tó ń kó wàhálà bá ìlú tií ń se àṣemáṣe.”
“Ní àpapọ̀, a rọ àwọn ènìyàn pé kí wọ́n ṣọ́ra fún ìròyìn tí kìí se òótọ́ nítorí pé àwọn tó ń fa wàhálà yìí máa ń lo irú nnkan báyìí. Irú nnkan báyìí máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà ogun,” Buba ló sọ báyìí.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Ọ̀rọ̀ kan tó sọ pé Nàìjíríà ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ní fídíò tó se àfihàn òkú àwọn ènìyàn kan tí wọ́n wà nínú kòtò kan náà ti ṣẹlẹ̀ kì í se òótọ́. Burkina Faso ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀.