Ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹjọ, ọdún 2025, ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára tí ó ń jẹ́ Asare Obed fi fídíò kan tó sàfihàn àwọn ènìyàn kan tó ń lo okùn láti kọjá odò lẹ́hìn ìgbà tí afárá kan já lulẹ̀.
Nínú fídíò yìí, a rí obìnrin kan Kiitó di okùn mú gidi tí ó sì ń tiraka láti kọjá omi, tí àwọn ọmọkùnrin kan wọ inú omi yìí tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti ti irin kan kọjá omi.
Ẹnì kan tó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí sọ pé Nàìjíríà ni ìṣẹ̀lẹ yìí ti ṣẹlẹ̀ láì sọ ibi tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà.
“Níbí yìí, àwọn ènìyàn yìí fẹ́ fi ẹ̀mí wọn ṣòfò nípa titiraka láti kọjá odò,” báyìí ni àkòrí fídíò yìí se sọ.
“Eléyìí kìí se ibi tí àwọn ènìyàn ti ń se fíìmù. Bí nǹkan se rí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà niyii. Ní ojoojumọ, àwọn ènìyàn máa ń gba omi yìí kọjá, wọ́n sì ń fi ẹ̀mí wọn wéwu. Kò sí afárá, okùn kan tí kò nípọn ni wọn lò,”báyìí ni ẹni yìí se sọ nínú fídíò yìí.
“Ohun yìí burú débi pé ténìyàn bá fẹ́ lọ láti abúlé sí ìgboro, ènìyàn gbọ́dọ̀ so mọ́ okùn yìí, èyí tó ma jẹ́ kí ènìyàn wà láàrin ikú àti ìyè. Tó bá jẹ́ nkan onígi tó wúwo, àwọn ènìyàn fún ra wọn ni wọ́n máa bọ́ sódò, tí wọ́n sì máa bá omi yìí wọ ìyá ìjà kómi yìí lè gbé wọn lọ sí òdì-kejì.”
Àwọn ènìyàn tó ju mílíọ̀nù kan ni wọ́n ti wo fídíò yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan ló ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì ló ti pín ọ̀rọ̀ yìí.
Ẹni kan tó ń jẹ́ Halima Kiponda, ẹni kan tó ń lo Facebook, tún fi fídíò yìí síta.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Nígbà tí CableCheck ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí nípa lílo Google Lens, a rí ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan tó ń jẹ́ Gadora media tó ń lo Facebook fi síta. Ẹni yìí fi fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan náà síta ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024. Èdè arabiiki/Lárúbáwá (Arabic language) ni wọ́n fi kọ àkòrí fídíò tí Gadora fi síta yìí. Àmọ́, Facebook túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “Ìjìyà ọmọkùnrin ní #Darfur nígbà irẹdanu ewé.” Darfur jẹ́ ibì kan ní orílẹ̀ èdè Sudan.
CableCheck tún ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí lórí Google láti mọ̀ bóyá afárá kan wó ni Darfur. Àbájáde ìkan nínú àyẹ̀wò wa fi ọ̀rọ̀ kan tí Sudan International Human Rights Organisation (SIHRO) fi síta ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024, nípa afárá kan tó wó níbì kan ní Sudan hàn wá.
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta pẹ̀lú fídíò kan tó sàfihàn àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń gba omi kọjá pẹ̀lú okùn. SIHRO sọ pé afárá yìí jẹ́ afárá kan tó wà ní Morni, èyí tí ó so gúúsù àti àárín Darfur papọ̀ ní Sudan.
Wọ́n ní afárá yìí wó nítorí ẹ̀kún omi tó ṣẹlẹ̀. Àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń pè ní Relief Web sọ pé òótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ Sudan yìí.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Fídíò kan tó sàfihàn àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń fi okùn kọjá omi kì í se ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà. Sudan ni ó ti ṣẹlẹ̀.