Ọ̀rọ̀ kan lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára ti sọ pé àwọn ènìyàn kan tí wọ́n wọ aṣọ tí wọ́n ń pè ní kamoflaagi, èyí tó dàbí aṣọ àwọn òṣìṣẹ́ ológun jẹ́ àwọn Boko Haram, àwọn oníwà jàgídíjàgan kan tí wọ́n gbàgbọ́ pé ẹ̀kọ́ tí àwọn òyìnbó mú wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò dára. Fídíò yìí fihàn pé wọ́n ń se àjọyọ̀ ìsẹ́gun wọn ní Nàìjíríà.
Ẹnì kan tí ó ń jẹ́ @K3lv1nB0B0 tí ó ń lo X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi ti wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀ ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú fídíò bíi ìṣẹ́jú méjì kan tó fi síta lórí X ní ọjọ́ ìsinmi.
“Boko Haram tí gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn bárékè (barracks) áwọn òṣìṣẹ́ ológun Nàìjíríà, wọ́n sìí ń se àjọyọ̀ ìsẹ́gun wọ́n,” báyìí ni àkòrí ọ̀rọ̀ yìí sọ lórí X.
Fídíò yìí se àfihàn àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ tí wọ́n ń gbé àwọn ènìyàn tí wọ́n di àwọn ohun ìjà mọ́ra, tí wọ́n ń lọ ní ilẹ̀ kan tó fẹ̀ gan-an.
Ìró ìbọn ń dún nínú fídíò yìí bí àwọn ènìyàn inú rẹ̀ se ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú èdè tí a kò mọ̀, àwọn kan nínú wọn sìí ń yọ̀ pẹ̀lú ariwo.
Ẹnì kan nínú àwọn ọkùnrin inú fídíò yìí ló se fídíò yìí, ó sì ń kọ ojú kámẹ́rà sí ara rẹ̀ léraléra, ó sì tún kọ ojú kámẹ́rà sí àyíká rẹ̀.
Àwọn ènìyàn mílíọ̀nù kan ló ti wo ọ̀rọ̀ tí ẹni yìí sọ pé àwọn Boko Haram ni wọ́n ń se àjọyọ̀ lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n gba “ọ̀pọ̀lọpọ̀” bárékè àwọn òṣìṣẹ́ ológun Nàìjíríà.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹẹdẹgbẹrun ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹẹdẹgbẹrun ni wọ́n ti pín ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ọọdunrun ló ti fi ọ̀rọ̀ yìí pamọ́.
Sé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí?
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck, tí TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí nípa ṣíṣe ohun tí wọ́n ń pè ní Google reverse image. A ríi pé osù kẹsàn-án, ọdún 2025, ni ẹnì kan fi fídíò yìí síta.
A ríi pé ẹnì kan tí ó ń lo X ní orílẹ̀ èdè Sudan ni ó fi síta nígbà tí a wo ojú ibi tí ó ń lò lórí Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára.
“Wòó, ara yá àwọn ènìyàn yìí, ìsẹ́gun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” báyìí ni èdè òyìnbó tí a túmọ̀ láti èdè arabiiki (Arabic language) se sọ pé ara ọ̀rọ̀ yìí se wí.
Fídíò yìí mìíràn tó seé rí kedere/dáadáa, tí wọ́n fi sórí YouTube, ohun ìgbàlódé orí ayélujára tí àwọn ènìyàn máa ń fi àwòrán tàbí fídíò sí kí àwọn ènìyàn lè ríi/wòó, ní ọjọ́ kìíní, osù kẹwàá, ọdún 2025, se àfihàn àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tó lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn gbà pé òótọ́ ni fídíò yìí.
CableCheck ṣàkíyèsí pé èdè arabiiki ni wọ́n fi kọ ohun tí ó wà lára àwọn ọkọ̀ tí wọ́n ń gbé àwọn ènìyàn tí wọ́n di àwọn nǹkan ìjà mọ́ra yii.
Aṣọ kamoflaagi tí wọ́n wọ̀ ní ohun tí ènìyàn fi lè dá àsíá (flag) Sudan mọ̀.
Rògbòdìyàn tàbí ohun tí a lè pè ní ogun abẹ́lé ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Sudan. Wàhálà yìí tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ìjọba ológun méjì bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù kẹrin, ọdún 2023.
Ó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tí wọ́n ń pè ní Sudanese armed forces, èyí tí Abdel Fattah al-Burhan jẹ́ olórí rẹ̀ àti àwọn kan tí wọ́n kìí se áwọn òṣìṣẹ́ ológun tí wọ́n ń pè ní Rapid Support Forces, tí Mohamed Hamdan Dagalo ń darí rẹ̀.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Ọ̀rọ̀ tí @K3lv1nB0B0 sọ pé àwọn Boko Haram ni wọ́n wà nínú fídíò yìí kì í se òótọ́. Kìí se Nàìjíríà ni wọ́n ti se fídíò yìí.