Ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ìlú Abuja ò jòkó ni ọjọ́bọ̀ lórí ìbò abẹ́nú ti egbé òsèlú All Progressives Congress ní Ìpínlè Èkìtì.
Ìròyìn tán ràn-ìn lórí ayélujára pé ilé ẹjọ́ gíga Abuja fagilé ìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òsèlú APC ní Èkìtì, èyí sí túmọ sí wípé Bíọ́dún Oyèbanji, olùdíje ẹgbẹ́ náà, kò ní kópa nínú ìdìbò òún.
Ọjọ kejìdínlógún oṣù kẹfà ní ìdìbò gómìnà Èkìtì yóò wáyé.
Àyẹwò TheCable fihàn wípé kò sí irúfé ìjòkó bẹẹ ní Ọjọ́bọ̀.
Catherine Oby-Christopher, ẹni tí ó jẹ amugbalẹgbẹ olùdarí fún ìròyìn ní Ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde kàn wípé irọ́ ni èyí.
“Ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti rí ìròyìn tí ó ń tàn ká’lé ká’ko lórí àkòrí yìí pelu suit nọmbà FHC/ABJ/CS/528/22, pé Adájọ́ àgbà Inyang Ekwo ṣe ìdájọ́ wípé Biodun Oyebanji, kòlè kópa nínú ìdìbò gómìnà Èkìtì, ní wákàtí díẹ̀ sí ìdíje náà,” àtẹ̀jáde yìí wí.
“Kò sí oun tó jọ bẹ́ẹ̀. Kódà kò sí ẹjọ́ kan-kan tó tan mọ́ ọ̀rọ̀ náà ní sàkání agbára ilé ẹjọ́ yìí.
“Ilé ẹjọ́ yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé a kò gbé irúfẹ́ ẹjọ́ báyìí wá síwájú Adájọ àgbà I.E. Ekwo.
“Ìròyìn òfégè ni ìròyìn yìí, wọ́n sì fẹ fí tan ará ìlú jẹ ní, kí o sí dá rògbòdìyàn ati àìbalẹ̀ ọkàn.
“Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ yìí burú jái, a sì lòdì síi pẹ̀lú. Arọ àwọn ará ìlú kí wọn má ṣe f’ọkan síi.
Segun Dipe, agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìlú Ekiti sọ pé ìrọ́ tó jìnà sí òtítọ́ ni ìròyìn náà, ofi kun wípé bótilè jẹ́ wípé oríṣi ẹjọ́ ló wà níwájú ilé ẹjọ́ káàkiri, kò sí èyí tí ó ti kọjá ipele àkọ́kọ́.
“Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ náà jẹ ète àwọn ẹgbẹ́ alátakò tí wọ́n kò mọ̀ wípé ète yìí yóò mú àbùkù bá wọn ní inú ìdíje náà.
“Bótilẹ̀ jẹ́ wípé kò yẹ ki ẹnikẹni f’ọkan sí ìròyìn yìí, ojúṣe wa ni láti sọ fún àwọn ènìyàn kí wọn má ṣe kọbiarasi ìròyìn tó jìnà sí òótọ́ yìí.
“Looto, awọn kan fí esun le’lẹ nípa ìdìbò abẹ́lé ti o waye ni oṣù kínní tí Biodun Abayomi Oyebanji sí ṣe Olubori nínú re party, àmọ́, àwọn ẹjọ́ yìí ò kọjá ipele àkọ́kọ́, wọ́n sì ti gbé àwọn ẹjọ́ yìí lọ sí Ekiti fún igbẹ́jọ́.
“Kò sí ilé ẹjọ́ gíga kan-kan ti o jòkó lórí ìdìbò abẹ́lé wa ni Abuja lónìí. Pẹ̀lú pẹ̀lú, ilé ẹjọ́ ti sún gbogbo igbẹ́jọ́ nípa ọ̀rọ̀ ìdìbò abẹ́lé wa sí Ọwẹ́wẹ̀, ọdún yìí. Kò sí ẹ̀yí tí igbẹ́jọ́ rẹ̀ ń wáyé lásìkò yìí. Gbogbo akitiyan ẹgbẹ́ òṣèlú wa ni kí a ṣe àṣeyọrí nínú ìdìbò yìí.
“Wàyí Egbẹ́ òsèlú APC ń sọ fún gbogbo olùdibò ní Ìpínlè Èkìtì kí wọ́n f’ọkàn balẹ̀, kí wọn sì má ṣe ojo nínú ìpinu wọn láti dìbò fún àyànfẹ olùdíje, Oyebanji àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ọjọ́ àbámẹ́ta, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹfà, ọdún 2022.”
A kọ ìròyìn yìí ni ajọṣepọ pẹlu Report for the World, eto agbaye ti o ṣe atilẹyin iṣẹ iroyin tiwa-n-tiwa.