Nyesom Wike, minisita fún Federal Capital Territory (FCT), Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, sọ pé Peter Obi, ẹni tí ó jẹ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ fún Ìpínlẹ̀ Anambra, tí ó ṣì tún jẹ́ adijedupo fún ipò Ààrẹ ní ọdún 2023, nínú ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party, kò ṣètò idibò ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ gómìnà.
Wike sọ ọ̀rọ̀ yìí ni Abuja, ní ọjọ́ ìsinmi ní St. James Anglican Church, ni Asokoro, Abuja, nígbà tí wọ́n ń se ìjọsìn fún ìdúpẹ́ fún “àṣeparí àwọn iṣẹ́ tí ìjọba se fún àwọn ọmọ Nàìjíríà” ní FCT.
Ó dàbí ẹni pé minisita yìí ń fi ọ̀rọ̀ bú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú alátakò, ó sì sọ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀.
“O sọ pé Peter Obi yóò jẹ Ààrẹ. Ààrẹ níbo? Lára yín máa ń se àtilẹyin fún àwọn ènìyàn tí ẹ kò mọ̀, nítorí bí ara se sọ fún yín,” Wike ló sọ báyìí.
“Obi se gómìnà fún ọdún mẹ́jọ. Kò ṣètò idibò ìjọba ìbílẹ̀-rárá. Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò bínú. Inú wọn dùn pé kò ṣètò idibò ìjọba ìbílẹ̀ ní odindi ọdún mẹ́jọ tó fi se gómìnà. Ẹ dẹ̀ pe ìyẹn ní ìjọba tiwantiwa? Ènìyàn kan soso ni ó jẹ́ gómìnà fún Ìpínlẹ̀ kan àti gbogbo àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ibẹ̀,” Wike ló sọ báyìí.
Wike sọ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́hìn ọjọ́ díẹ̀ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú alátakò fi ẹnu kò pé àwọn yóò yan ẹgbẹ́ òsèlú African Democratic Congress (ADC) gẹ́gẹ́bí ẹgbẹ́ òsèlú tí àwọn yóò fi yọ Ààrẹ Bola Tinubu kúrò nípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọdún 2027.
Ọ̀rọ̀ Wike yìí ti fa àríyànjiyàn, tí ó ṣì mú àwọn ènìyàn sọ pé Obi ṣètò idibò ìjọba ìbílẹ̀ àbí kò ṣeé nígbà tí ó jẹ gómìnà.
ÀWỌN OHUN TÍ Ó YẸ KÍ Ẹ KỌ́KỌ́ MỌ̀ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
Kí Supreme Court, ilé ẹjọ́ tí ó ga jù lọ ní Nàìjíríà tó gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé kí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ máa ṣe ijoba ara wọn ní oṣù keje, ọdún 2024, àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ kò jẹ ki àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mí.
Bí àwọn gómìnà yìí se maa n se ni pé wọ́n kìí fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní owó wọn tí ìjọba àpapọ̀ máa ń fún wọn ní osoosu (monthly federal allocation), wọn sì tún máa ń fi àwọn ènìyàn wọn sípò olùdarí fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ dípò kí wọ́n ṣètò idibò ìjọba Ìbílẹ̀ fún àwọn tó máa ṣe alaga ìjọba ìbílẹ̀.
Ilé ẹjọ́ yìí sọ pé kí ìjọba àpapọ̀ máa san owó tí ìjọba àpapọ̀ máa ń fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ sí inú àpò owó ìjọba ìbílẹ̀ dípò kí wọ́n máa san sínú àpò àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀, kí ìdàgbàsókè lè wà ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀.
Peter Obi ṣe gómìnà fún Ìpínlẹ̀ Anambra láti oṣù kẹta, ọdún 2006 sí oṣù kẹta, ọdún 2014, pẹ̀lú àwọn idaduro ilé ẹjọ́ àti ìgbà tí wọ́n fẹ́ yọ kúrò nípò gómìnà.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
CableCheck ríi pé ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kìíní, ọdún 2014, ní bíi oṣù méjì kí ìjọba Obi tó parí, ó ṣètò idibò ìjọba ìbílẹ̀ káàkiri àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Anambra.
Ètò idibò yìí jẹ́ àkọ́kọ́ irú ẹ ní Ìpínlẹ̀ Anambra láti ọdún 1998, èyí tí ó túmọ̀ sí pé wọn kò ṣètò irú idibò báyìí rí fún ọdún mẹ́rìndínlógún.
Ní ìgbà yẹn, ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Grand Alliance (APGA) ti ó ń ṣe ìjọba ní Ìpínlẹ̀ Anambra nígbà náà se àṣeyọrí ní ìjọba ìbílẹ̀ ogún nínú mọkanlelogun, wọn sì ní àwọn aṣojú agbegbe (councilors) mẹrinleniọọdunrun nínú àwọn aṣojú ọọdunrun àti mẹrindinlọgbọn ti wọn di olórí agbegbe nígbà ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ náà.
Ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kìíní, ọdún 2014, ọjọ́ kẹta lẹ́hìn ìdìbò ijoba ìbílẹ̀ yìí, Obi búra fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tuntun yìí, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n se iṣẹ́ pẹ̀lú Willie Obiano, ẹni tí àwọn ará Ìpínlẹ̀ Anambra dìbò yàn gẹ́gẹ́bí gómìnà Ìpínlẹ̀ náà.
CableCheck tún ríi pé ilé isẹ ìròyìn kan ti kọ́kọ́ se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Wike yìí, lẹ́hìn ìgbà tí Reno Omokri, oluranlọwọ tẹ́lẹ̀ fún Ààrẹ kan tẹ́lẹ̀ sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ kejìlá, oṣù keje, ọdún 2024.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ tí Wike sọ yìí kìí se òótọ́.