Kemi Badenoch, arábìnrin tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òsèlú alátakò tí wọ́n ń pè ní Conservative Party ní orílẹ̀ èdè United Kingdom (UK) ti sọ pé àwọn ọmọ òhun kò lè di ọmọ Nàìjíríà nítorí pé òhun jẹ́ obìnrin ọmọ Nàìjíríà.
Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ogunjọ, oṣù keje, ọdún 2025, nígbà tí Fareed Zakaria, agbohunsafẹfẹ tó n ṣe iṣẹ́ fún Cable News Network (CNN) n fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, nígbà tí òṣìṣẹ́ CNN yìí ń ṣe àyẹ̀wò ìyàtọ̀ ètò ìrìn àjò sí Nàìjíríà àti orílẹ̀ èdè Britain.
Badenoch sọ pé ó rọrùn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà láti di ọmọ Britain ju kí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn di ọmọ Nàìjíríà.
“Kò fẹ́ẹ̀ẹ́ seése, fún àpẹẹrẹ, láti di ọmọ Nàìjíríà. Mo jẹ́ ọmọ Nàìjíríà nítorí pé ọmọ Nàìjíríà ni àwọn òbí mi. Àwọn ọmọ mi kò lè di ọmọ Nàìjíríà nítorí pé mo jẹ́ obìnrin,” Badenoch ló sọ báyìí. Ó tún sọ pé “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà wá sí UK, wọ́n máa gbé níbẹ̀ fún ìgbà kan, wọ́n sì máa ní àǹfààní láti di ọmọ UK. Ẹ jẹ́ kí a yé máa hùwà bíi ẹni tí kò lóye.”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kìí se òótọ́. UK ni wọ́n bí arábìnrin yìí tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Olukemi Adegoke kò tó se ìgbéyàwó sí. Àwọn òbí rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Yorùbá ní Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ mu wá sí Nàìjíríà, ó sì se ìgbà kékeré rẹ̀ ní Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ mu padà sí UK nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.
Kí wọ́n tó mu padà, ó lọ sí ilé-ìwé aládàani ní ìlú èkó (Lagos), kò sì nílò ìwé tí ó fún akẹ́kọ̀ọ́ láyé láti kàwé níbì kan (student visa) nítorí pé ọmọ Nàìjíríà ni àwọn òbí rẹ̀.
Ìwé tí ó fún akẹ́kọ̀ọ́ láyé láti kàwé níbi kan yìí (student visa R7A) jẹ́ ìwé àyè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé tó fún ènìyàn láàyè láti wá tàbí wọ orílẹ̀ èdè kan. Irú ẹ ní wọn máa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá wá sí Nàìjíríà láti kàwé (the type of visa issued to international students in Nigeria). Àwọn tí wọ́n bá jẹ́ ọmọ Nàìjíríà kò nílò ìwé yìí láti kàwé ní Nàìjíríà.
Badenoch se ìgbéyàwó pẹ̀lú Hamish Badenoch, òṣìṣẹ́ ilé ifowopamọ ní orílẹ̀ èdè Scotland. Olukemi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lo Badenoch, eléyìí ló jẹ́ kí ó di Kemi Badenoch. Ọmọ mẹta ni wọ́n bí.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
CableCheck se àyẹ̀wò ìwé òfin Nàìjíríà (Nigerian Constitution), láti wo ọ̀rọ̀ arábìnrin yìí.
Gẹ́gẹ́bí abala karundinlọgbọn, apá kẹta apá kìíní (section 25 (1c), ìwé òfin Nàìjíríà ti ọdún 1999 se wí, ẹni tí wọ́n bá bí ní orílẹ̀ èdè mìíràn ti di ọmọ Nàìjíríà tí ìkan nínú àwọn òbí rẹ̀ bá jẹ́ ọmọ Nàìjíríà. Eléyìí túmọ̀ sí pé òbí kan nínú òbí méjì tí ènìyàn ní ni ó nílò láti di tàbí jẹ́ ọmọ Nàìjíríà. Tí a bá wo ibi tí wọ́n ti bí àwọn òbí arábìnrin yìí, òfin Nàìjíríà fi ààyè gba àwọn ọmọ Kemi Badenoch kí wọ́n di ọmọ Nàìjíríà.
Jíjẹ́ ọmọ Nàìjíríà nípa pé àwọn òbí tàbí ìkan nínú àwọn òbí ènìyàn tàbí àwọn òbí tí wọ́n bí òbí ènìyàn jẹ́ ọmọ Nàìjíríà fún ènìyàn ní àǹfààní láti jẹ́ ọmọ Nàìjíríà nígbà tí wọ́n bá bí eniyan (Nigerian citizenship by birth).
Ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọ Nàìjíríà nípa ọ̀nà yìí ní àǹfààní ní oríṣiríṣi. Lára àwọn àǹfààní yìí ni pé ó lè wá/wọlé sí Nàìjíríà bí ó se fẹ́, ààbò sì wà fún un.
Òfin Nàìjíríà gbà kí ènìyàn jẹ́ ọmọ Nàìjíríà, kí ó sì tún jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn (dual citizenship). Àmọ́, àwọn ohun kan wà tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ se tàbí má ṣe lábẹ́ òfin tí irú nkan báyìí bá fẹ́ wáyé.
Abala kejìdínlógún, apá kìíní ìwé òfin Nàìjíríà sọ pé ènìyàn tí ó bá jẹ́ ọmọ Nàìjíríà nítorí pé wọ́n bi sí Nàìjíríà lè ṣètò bó ṣe máa di ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn láì pàdánù jíjẹ́ ọmọ Nàìjíríà.
Àmọ́sá, ẹni tí wọ́n kò bí sí Nàìjíríà, tí ó di ọmọ Nàìjíríà nípa sísọ ará ẹ di ọmọ Nàìjíríà ma pàdánù jíjẹ́ ọmọ Nàìjíríà tí ẹni yìí bá sì fẹ́ jẹ́ tàbí jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn.
Ní àfikún, Òfin kò sọ pé ènìyàn kò lè jẹ àǹfààní jíjẹ́ ọmọ Nàìjíríà nítorí pé ó jẹ́ obìnrin tàbí ọkùnrin. Ohun tí ó lè má jẹ́ kí ènìyàn tí ó bá jẹ́ ọmọ Nàìjíríà jẹ́ àǹfààní jíjẹ́ ọmọ Nàìjíríà ni tí ọkọ tàbí aya ọmọ Nàìjíríà bá jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn.
Abala kẹrindinlogun, apá kejì, ìwé òfin Nàìjíríà (section 26 (2a) of Nigerian Constitution) sọ pé “obìnrin tí ó bá fẹ́ ọmọ Nàìjíríà lè di ọmọ Nàìjíríà.”
Àwọn ọkùnrin ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn tí wọ́n bá fẹ́ ọmọ Nàìjíríà kò lè di ọmọ Nàìjíríà nípa fífi orúkọ sílẹ̀ ní abẹ òfin Nàìjíríà. Ọ̀nà tí wọ́n lè fi di ọmọ Nàìjíríà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò tí kò rọrùn.
Èyí túmọ̀ sí pé kò lè rọrùn fún ọkọ arábìnrin yìí láti di ọmọ Nàìjíríà. Àmọ́sá, òfin yìí kò kan àwọn ọmọ ènìyàn tí ọ̀rọ̀ báyìí kàn tí àwọn òbí tàbí àwọn òbí tí wọ́n bí òbí wọ́n jẹ́ ọmọ Nàìjíríà.
ASHLEIGH PLUMPTRE, ẸNI TÍ Ó JẸ́ ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ MEJI
Ashleigh Plumptre, ọmọ obìnrin ọdún mẹtadinlọgbọn kan jẹ́ agbabọọlu ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Britain. Ó ń gbá bọọlu fún AI-Ittihad, ní Saudi Arabia àti Super Falcons, ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin tí Nàìjíríà.
Tim Plumptre, bàbà Ashleigh jẹ́ ọmọ ìlú èkó, ní Nàìjíríà, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Britain. Nígbà ìdíje ère bọọlu 2022 Women’s African Cup of Nations (WAFCON), Ashleigh pinnu láti láti gbá bọọlu fún Nàìjíríà, orílẹ̀ èdè bàbà rẹ̀, èyí tí ó túmọ̀ sí pé kò gbà bọọlu fún Britain nígbà yìí.
Nínú ifọrọwanilẹnuwo kan nínú oṣù keje, ọdún 2025, Tim sọ pé òhun tọ́ Ashleigh láti mọ nípa àṣà àti ìṣe Nàìjíríà nípa jíjẹ́ kó lọ gbé pẹ̀lú Harry Dotun Plumptre, ẹni tí ó jẹ́ bàbà fún Tim pẹ̀lú àwọn ẹbí Tim ní Nàìjíríà.
Ashleigh jẹ́ ìkan nínú àwọn agbabọọlu tí wọ́n ń díje lọ́wọ́lọ́wọ́ fún 2025 WAFCON.
BI A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ tí Kemi Badenoch sọ pé àwọn ọmọ òhun kò ní àǹfààní láti di/jẹ́ ọmọ Nàìjíríà nítorí pé ohun jẹ́ obìnrin kìí se òótọ́. Èyí lè ṣẹlẹ̀ tí ó bá ṣètò pé òhun kìí se ọmọ Nàìjíríà mọ́.