Ọ̀rọ̀ kan lori àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára sọ pé ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti sọ ‘ètò òfin àṣemáṣe lórí ayélujára, ti ọdún 2025’ di òfin.
Orí X, ohun ìgbàlódé alámì krọọsi, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀, WhatsApp àti Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára ni àwọn ènìyàn ti pín ọ̀rọ̀ yìí jù.
Ọ̀rọ̀ yìí tún sọ pé àwọn àgbékalẹ̀ yìí ti “di òfin tí ìjọba lè lò láti dá sẹ̀ríyà fún ẹni tó bá tàpá sófin yìí káàkiri Nàìjíríà.”
“Ilé ìgbìmọ̀ asòfin Nàìjíríà ti sọ ètò fún àṣemáṣe lórí ayélujára, 2025 (Cybercrimes Act, 2025) di òfin lábẹ́ Godswill Akpabio, Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asojusofin àgbà. Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo àgbékalẹ̀ fún ìwà pàlàpálá lórí ayélujára tí di òfin káàkiri Nàìjíríà,” báyìí ni ara ọ̀rọ̀ yìí sọ.
“Tí ó bá jẹ́ ẹni tó ń lo ayélujára, bíi ki o máa fi nǹkan síbẹ̀ láti dá àwọn ènìyàn lára yá lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise bíi WhatsApp, Facebook, Telegram àti bẹẹ bẹẹ lọ, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tí òfin yìí sọ nítorí pé ìjọba kò ní gbọ́ pé o kò mọ̀ pé òfin báyìí wà.”

Ọ̀rọ̀ yìí tún sọ pé ara àwọn àgbékalẹ̀ òfin yìí ni pé ẹnikẹni ti o ba wo tàbí tú àwọn ẹ̀rọ alágbèéká fún íbaraẹnisọrọ ẹnì kan laiba jẹ́ pé ẹni tí ó nií gbà ẹ láyè “á fi ẹ̀wọ̀n bíi ọdún márùn-ún gbára.”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tó ń lo X tí fi ọ̀rọ̀ yìí síta pẹ̀lú àwòrán ní bíi ọ̀nà kan náà, pẹ̀lú àwòrán Akpabio.
Daddy Freeze, gbajúgbajà agbohunsafẹfẹ ni Nàìjíríà fi ọ̀rọ̀ yìí síta lórí Facebook lórí ibi kan tí wọ́n ti máa ń fi ọ̀rọ̀ síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “iṣẹ́ takuntakun ni Akpabio, asojúsòfin àgbà se. Ṣọ́ra nípa àwọn ohun tí ó máa máa fi sórí ayélujára. Kí ni èrò ẹ nípa ọ̀rọ̀ yìí?

Ẹnì kan tí ó ń jẹ́ @emmaikumeh ló fi ọ̀rọ̀ yìí sórí X ní ọjọ́ kẹtalelogun, oṣù kẹjọ, ọdún 2025, ó sì kọ “bí mo se rí ọ̀rọ̀ yìí lórí WhatsApp” rèé pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó fi síta. Àwọn ènìyàn igba ló ti tún ọ̀rọ̀ yìí pín, àwọn ènìyàn ọgbọ́n ni wọ́n ti tọ́ka sí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn irínwó ni wọ́n ti fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí.
A tọ́jú ara àwọn ọ̀rọ̀ yìí síbí àti síbí yìí.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Àyẹ̀wò tí CableCheck, ti TheCable Newspaper, se fi hàn wá pé Nàìjíríà kò ní òfin kankan tó ń jẹ́ ètò òfin fún àṣemáṣe orí ayélujára, 2025, (“Cybercrimes Act, 2025”). Òfin tí Nàìjíríà ní lórí àṣemáṣe orí ayélujára ni a mọ̀ sí “Cybercrimes (Prohibition, Prevention, etc) (Amendment) Act, 2024.”
Ààrẹ Bọ́lá Tinubu bọ̀wọ̀ lu òfin yìí ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejì, ọdún 2024. Òfin tí Ààrẹ bọ̀wọ̀ lù yìí jẹ́ àtúnṣe àwọn ara Cybercrimes (Prohibition, Prevention, etc) Act, 2015.
CableCheck ṣàkíyèsí pé àwọn ènìyàn ti ń pín ọ̀rọ̀ yìí lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára láti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹjọ, ọdún 2025, èyí tí ó bọ́ sí ìgbà kan náà tí àwọn ilé ìgbìmọ̀ asojusofin àgbà lọ fún ìsinmi ti wọ́n máa ń lọ ní ọdọọdún.
Ni ọjọ́ kẹtalelogun, ọdún 2025, ilé ìgbìmọ̀ asojusofin àgbà lọ fún ìsinmi tí wọ́n máa ń lọ ni ọdọọdún, wọ́n sì máa padà dé fún iṣẹ́ òfin síse ní ọjọ́ kẹtalelogun, ọdún 2025.
Àwọn ilé ìgbìmọ̀ àwọn asojusofin kékeré (house of representatives) lọ fún ìsinmi ti wọn ní ọjọ́ ketadinlọgbọn, oṣù keje, ọdún 2025.
Irú àgbékalẹ̀ láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa se àṣemáṣe lórí ayélujára báyìí kò lè di òfin nígbà tí àwọn ilé ìgbìmọ̀ asojusofin méjèèjì lọ fún ìsinmi.
Àwọn àgbékalẹ̀ òfin tí wọ́n wà nínú ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn pín ká yìí kìí se ìkankan náà pẹ̀lú Cybercrimes Act, 2024.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn pín kiri tó sọ pé ilé ìgbìmọ̀ asojusofin àgbà Nàìjíríà ti sọ àgbékalẹ̀ fún àṣemáṣe lórí ayélujára di òfin ní ọdún 2025 (Cybercrimes Act, 2025) kìí se òótọ́.