Délé Mọmọdu, ẹni tí ó ń tẹ magasini Ovation (ovation magazine), síta sọ pé Independent National Electoral Commission (INEC), àjọ tí ó ń ṣe ètò ìdìbò ní Nàìjíríà nọ ọọdunrun ó lé ní marunlelaadọta biliọnu naira lórí ohun tí a mọ̀ sí bimodal voter accreditation system (BVAS) nígbà ìdìbò ọdún 2023.
“Kí ni ìdí tí a fi máa fi ohun ìní wa tí kò pọ̀ ṣòfò nígbà tí a lè yipada láti ìjọba tiwantiwa sí ìjọba tí ọba tàbí àwọn ènìyàn ìdílé ọba ń ṣe àkóso rẹ̀,” lára ọ̀rọ̀ yìí sọ báyìí. Àkòrí ọ̀rọ̀ yìí ti wọ́n fi sí orí ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán ara wọn ní èsì ẹgbẹrin dín ní méje.
Àwọn ènìyàn fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ní ọọdunrun àti marunlelogun.
” Ọọdunrun ó lé marunlelaadọta biliọnu naira fún BVAS, ènìyàn márùn-ún sọ pé kò pọndandan kí wọ́n lòó? Ǹjẹ́ èyí kò panilẹrin? irú orílẹ̀-èdè wo ni eléyìí? atẹjade yìí parí báyìí?
Mọmọdu díje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP) tí ó wáyé ní oṣù karùn-ún, ọdún 2022.
Lẹ́hìn tí ó kùnà nínú ìbò yiyan àwọn tí ó tó láti díje, PDP yàn-án gẹ́gẹ́bí olùdarí ètò ìpolongo fún ẹgbẹ́ òsèlú náà.
BVAS
BVAS-Bimodal Voter Accreditation System jẹ́ ohun ìgbàlódé ti INEC lo ní ọdún 2021 láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú ètò ìdìbò.
Ohun àmúlò ìdìbò yìí ṣe iforukọsile àti idanimọ àwọn oludibo nípa gbígba ohun idanimọ láti ara àwọn ènìyàn. A tún máa ń lòó láti ṣe atẹjade èsì ìbò lórí ohun tí a mọ̀ sí iRev.
ÀWỌN ẸGBẸ́ ÒSÈLÚ ALÁTAKÒ BÍNÚ SÍ BÍ INEC KÒ ṢE GBÉ ÈSÌ ÌBÒ JÁDE LÓRÍ OHUN ÌGBÀLÓDÉ IREV.
Nígbà tí ìdìbò yìí kù díẹ̀ kó wáyé, INEC sọ pé àwọn ní agbára láti gbé èsì ìbò jáde ní aipẹ lórí ohun ìgbàlódé iReV.
Àmọ́, INEC kùnà láti gbé èsì yìí jáde ní waransesa tàbí ní kọmọnkọmọ lórí iRev. Wọ́n ní aisedeede orí ayélujára ló fàá. Eléyìí fa kí àwọn ènìyàn bínú sí INEC. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kí àwọn ẹgbẹ́ òsèlú alátakò gbé Tinubu lọ sí ilé-ẹjọ́. Wọ́n ní àṣeyọrí rẹ̀ gẹ́gẹ́bí Ààrẹ nínú ìdìbò ọdún 2023 kò yọranti.
Oṣù kan lẹ́hìn ìdìbò yìí, Festus Okoye, agbẹnusọ tẹ́lẹ̀rí fún INEC sọ pé “kò yẹ” kí àwọn ènìyàn sọ pé ìjọba fi owó àwọn ènìyàn tí ó ń san owó orí ṣòfò nítorí “aisedeede” tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí wón gbé èsì ìbò Ààrẹ náà jáde.
ÌDÁJỌ́ ILÉ–ẸJỌ́
Ní ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹsàn-án, ilé ìdájọ́ sọ pé Bọla Tinubu ni ó ṣe àṣeyọrí nínú idije fún Ipò Ààrẹ tí ó wáyé ní ọjọ́ karundinlọgbọn, oṣù kejì, ọdún 2023.
Ilé ìdájọ́ yìí, tí Haruna Tsammani jẹ́ olórí rẹ̀ da ẹjọ́ tí Atiku Abubakar, Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Peter Obi, Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labour Party-LP) àti ẹgbẹ́ òsèlú Allied Progressives Movement (APM) gbé lọ sí ilé-ẹjọ́.
Nínú ìdájọ́ tí gbogbo àwọn adajọ ilé idajọ ìbò yìí fi ọwọ́ si, ilé ìdájọ́ yìí sọ pé ẹ̀sùn tí àwọn Ólùdíje tí a mẹ́nuba lókè yìí fi kan Tinubu kò ní òdodo nínú.
Ile ìdájọ́ náà sọ pé INEC lè gbé èsì ìbò jáde bí wọ́n bá ṣe fẹ́.
Àwọn adajọ márùn-ún náà fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé òfin tí ó wà fún ètò ìdìbò kò sọ pé dandan ni kí INEC gbé èsì náà jáde lórí ohun kan pàtó.
IYE OWÓ TÍ WỌ́N NỌ LÓRÍ BVAS
Ní ọdún 2021, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa owó isuna níwájú àwọn ilé igbimọ asofin àgbà, Mahmud Yakubu, olórí INEC sọ pé àjọ tí ó ń ṣe ètò ìdìbò náà yóò nọ ọọdunrun àti márùn-ún biliọnu naira fún ètò ìdìbò ọdún 2023.
Ní ọdún 2022, Yakubu ṣe àlàyé síwájú sí pé lẹ́yìn owó tí àwọn máa nọ fún ìdìbò yìí, àádọ́ta biliọnu naira ni INEC fẹ́ ṣe ètò rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Owó yìí lé ní biliọnu mẹwa naira ju ti owó ètò ìdìbò fún ọdún 2022. Ti ọdún 2022 jẹ ogójì biliọnu naira.
Nigba tí ó ń parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ètò owó tí wọ́n máa nọ fún ọdún 2023, èyí tí ó jẹ́ àádọ́ta biliọnu ọọdunrunlenimarun biliọnu náírà fún eto ìdìbò Àpapọ̀, gbogbo owó tí INEC fẹ́ nọ jẹ́ ọọdunrun àti àádọ́ta lé ní márùn-ún biliọnu náírà.
Àwọn tí ó ń ṣe ètò ìgbáradì fún ìdìbò (INEC’s election project planning (EPP) committee) sọ pé nínú biliọnu ọọdunrunlenimarun náírà tí a yà sọtọ fún ìdìbò yìí, INEC sọ pé “eejilelọgọjọ biliọnu ó dín ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà fún ìṣètò fún àwọn ènìyàn tí wọ́n yóò lò, biliọnu mẹtadinlọgọfa ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù fún ohun ètò ìdìbò amusẹya, àti biliọnu méjìdínlógún ó lé ní ẹẹdẹgbẹta mílíọ̀nù náírà, èyí tí ó jẹ́ owó miran fún ètò ìdìbò náà ni àwọn yóò nọ.”
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ tí Délé Mọmọdu sọ pé INEC nọ biliọnu ọọdunrunlelaadọta àti márùn-ún náírà lórí mashinni BVAS kìí se òótọ́.
Owó yìí jẹ́ iye Àpapọ̀ owó tí INEC fẹ́ nọ fún eto ìdìbò ọdún 2023-ọọdunrunlenimarun biliọnu náírà fún ètò ìdìbò àti àádọ́ta biliọnu náírà fún owó tí wọ́n máa ń nọ ní ọdọọdún.
Lára biliọnu ọọdunrunlenimarun náírà yìí, INEC ya biliọnu mẹtadinlogun ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà fún ohun ìgbàlódé tí a lè lò ní orí ayélujára sọtọ. Èyí túmọ̀ sí pé lára biliọnu mẹtadinlogun ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà ni wọ́n ti yọ owó tí wọ́n nọ fún BVAS.