TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: INEC kò nọ ọọdunrun ó lé marunlelaadọta biliọnu naira lórí BVAS bí Délé Mọmọdu ṣe wí
Share
Latest News
Viral post wey claim sey dem don pass ‘Cybercrimes Act 2025’ no correct
Ózí na-ekwu nà é mepụ̀tálá ìwú megidere cybercrime bụ̀ àsị́
Irọ́ ni fídíò tó sọ pé Nàìjíríà ti sọ ‘Cybercrimes Act, 2025’ di òfin
Hoton hoto hoto ko bidiyo mai zagaya yanar gizo da sauri akan hanyar ”Dokar Laifukan gizo 2025′ karya ce
Fídíò Tinubu níbi tí ó ti ń rọ́ kẹ̀kẹ̀ mọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà nítorí pé wọ́n pe ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní AI kìí se òótọ́
Bidiyon Tinubu na barazana ga mutanen dake kirar maganar a matsayin AI, hadawa akayi
Video wey Tinubu dey threaten citizens wey call im statements AI na fake
Íhé ńgósị́ ébé Tinubu nà-àbárá ńdị́ ná-ákpọ́ ókwú ya AI bụ̀ ǹkè é nwòghàrị̀rị̀ énwòghárị́
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

INEC kò nọ ọọdunrun ó lé marunlelaadọta biliọnu naira lórí BVAS bí Délé Mọmọdu ṣe wí

Yemi Michael
By Yemi Michael Published September 23, 2023 7 Min Read
Share

Délé Mọmọdu, ẹni tí ó ń tẹ magasini Ovation (ovation magazine), síta sọ pé Independent National Electoral Commission (INEC), àjọ tí ó ń ṣe ètò ìdìbò ní Nàìjíríà nọ ọọdunrun ó lé ní marunlelaadọta biliọnu naira lórí ohun tí a mọ̀ sí bimodal voter accreditation system (BVAS) nígbà ìdìbò ọdún 2023.

“Kí ni ìdí tí a fi máa fi ohun ìní wa tí kò pọ̀ ṣòfò nígbà tí a lè yipada láti ìjọba tiwantiwa sí ìjọba tí ọba tàbí àwọn ènìyàn ìdílé ọba ń ṣe àkóso rẹ̀,” lára ọ̀rọ̀ yìí sọ báyìí. Àkòrí ọ̀rọ̀ yìí ti wọ́n fi sí orí ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán ara wọn ní èsì ẹgbẹrin dín ní méje.

Àwọn ènìyàn fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ní ọọdunrun àti marunlelogun.

” Ọọdunrun ó lé marunlelaadọta biliọnu naira fún BVAS, ènìyàn márùn-ún sọ pé kò pọndandan kí wọ́n lòó? Ǹjẹ́ èyí kò panilẹrin? irú orílẹ̀-èdè wo ni eléyìí? atẹjade yìí parí báyìí?

Mọmọdu díje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP) tí ó wáyé ní oṣù karùn-ún, ọdún 2022.

Lẹ́hìn tí ó kùnà nínú ìbò yiyan àwọn tí ó tó láti díje, PDP yàn-án gẹ́gẹ́bí olùdarí ètò ìpolongo fún ẹgbẹ́ òsèlú náà.

BVAS

BVAS-Bimodal Voter Accreditation System jẹ́ ohun ìgbàlódé ti INEC lo ní ọdún 2021 láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú ètò ìdìbò.

Ohun àmúlò ìdìbò yìí ṣe iforukọsile àti idanimọ àwọn oludibo nípa gbígba ohun  idanimọ láti ara àwọn ènìyàn. A tún máa ń lòó láti ṣe atẹjade èsì ìbò lórí ohun tí a mọ̀ sí iRev.

ÀWỌN ẸGBẸ́ ÒSÈLÚ ALÁTAKÒ BÍNÚ SÍ BÍ INEC KÒ ṢE GBÉ ÈSÌ ÌBÒ JÁDE LÓRÍ OHUN ÌGBÀLÓDÉ IREV.

Nígbà tí ìdìbò yìí kù díẹ̀ kó wáyé, INEC sọ pé àwọn ní agbára láti gbé èsì ìbò jáde ní aipẹ lórí ohun ìgbàlódé iReV.

Àmọ́, INEC kùnà láti gbé èsì yìí jáde ní waransesa tàbí ní kọmọnkọmọ lórí iRev. Wọ́n ní aisedeede orí ayélujára ló fàá. Eléyìí fa kí àwọn ènìyàn bínú sí INEC. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kí àwọn ẹgbẹ́ òsèlú alátakò gbé Tinubu lọ sí ilé-ẹjọ́. Wọ́n ní àṣeyọrí rẹ̀ gẹ́gẹ́bí Ààrẹ nínú ìdìbò ọdún 2023 kò yọranti.

Oṣù kan lẹ́hìn ìdìbò yìí, Festus Okoye, agbẹnusọ tẹ́lẹ̀rí fún INEC sọ pé “kò yẹ” kí àwọn ènìyàn sọ pé ìjọba fi owó àwọn ènìyàn tí ó ń san owó orí ṣòfò nítorí “aisedeede” tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí wón gbé èsì ìbò Ààrẹ náà jáde.

ÌDÁJỌ́ ILÉ–ẸJỌ́

Ní ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹsàn-án, ilé ìdájọ́ sọ pé Bọla Tinubu ni ó ṣe àṣeyọrí nínú idije fún Ipò Ààrẹ tí ó wáyé ní ọjọ́ karundinlọgbọn, oṣù kejì, ọdún 2023.

Ilé ìdájọ́ yìí, tí Haruna Tsammani jẹ́ olórí rẹ̀ da ẹjọ́ tí Atiku Abubakar, Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Peter Obi, Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labour Party-LP) àti ẹgbẹ́ òsèlú Allied Progressives Movement (APM) gbé lọ sí ilé-ẹjọ́.

Nínú ìdájọ́ tí gbogbo àwọn adajọ ilé idajọ ìbò yìí fi ọwọ́ si, ilé ìdájọ́ yìí sọ pé ẹ̀sùn tí àwọn Ólùdíje tí a mẹ́nuba lókè yìí fi kan Tinubu kò ní òdodo nínú.

Ile ìdájọ́ náà sọ pé INEC lè gbé èsì ìbò jáde bí wọ́n bá ṣe fẹ́.

Àwọn adajọ márùn-ún náà fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé òfin tí ó wà fún ètò ìdìbò kò sọ pé dandan ni kí INEC gbé èsì náà jáde lórí ohun kan pàtó.

IYE OWÓ TÍ WỌ́N NỌ LÓRÍ BVAS

Ní ọdún 2021, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa owó isuna níwájú àwọn ilé igbimọ asofin àgbà, Mahmud Yakubu, olórí INEC sọ pé àjọ tí ó ń ṣe ètò ìdìbò náà yóò nọ ọọdunrun àti márùn-ún biliọnu naira fún ètò ìdìbò ọdún 2023.

Ní ọdún 2022, Yakubu ṣe àlàyé síwájú sí pé lẹ́yìn owó tí àwọn máa nọ fún ìdìbò yìí, àádọ́ta biliọnu naira ni INEC fẹ́ ṣe ètò rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Owó yìí lé ní biliọnu mẹwa naira ju ti owó ètò ìdìbò fún ọdún 2022. Ti ọdún 2022 jẹ ogójì biliọnu naira.

Nigba tí ó ń parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ètò owó tí wọ́n máa nọ fún ọdún 2023, èyí tí ó jẹ́ àádọ́ta biliọnu ọọdunrunlenimarun biliọnu náírà fún eto ìdìbò Àpapọ̀, gbogbo owó tí INEC fẹ́ nọ jẹ́ ọọdunrun àti àádọ́ta lé ní márùn-ún biliọnu náírà.

Àwọn tí ó ń ṣe ètò ìgbáradì fún ìdìbò (INEC’s election project planning (EPP) committee) sọ pé nínú biliọnu ọọdunrunlenimarun náírà tí a yà sọtọ fún ìdìbò yìí, INEC sọ pé “eejilelọgọjọ biliọnu ó dín ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà fún ìṣètò fún àwọn ènìyàn tí wọ́n yóò lò, biliọnu mẹtadinlọgọfa ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù fún ohun ètò ìdìbò amusẹya, àti biliọnu méjìdínlógún ó lé ní ẹẹdẹgbẹta mílíọ̀nù náírà, èyí tí ó jẹ́ owó miran fún ètò ìdìbò náà ni àwọn yóò nọ.”

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Ọ̀rọ̀ tí Délé Mọmọdu sọ pé INEC nọ biliọnu ọọdunrunlelaadọta àti márùn-ún náírà lórí mashinni BVAS kìí se òótọ́.

Owó yìí jẹ́ iye Àpapọ̀ owó tí INEC fẹ́ nọ fún eto ìdìbò ọdún 2023-ọọdunrunlenimarun biliọnu náírà fún ètò ìdìbò àti àádọ́ta biliọnu náírà fún owó tí wọ́n máa ń nọ ní ọdọọdún.

Lára biliọnu ọọdunrunlenimarun náírà yìí, INEC ya biliọnu mẹtadinlogun ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà fún ohun ìgbàlódé tí a lè lò ní orí ayélujára sọtọ. Èyí túmọ̀ sí pé lára biliọnu mẹtadinlogun ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà ni wọ́n ti yọ owó tí wọ́n nọ fún BVAS.

TAGGED: BVAS, Dele Momodu, INEC

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael September 23, 2023 September 23, 2023
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

Viral post wey claim sey dem don pass ‘Cybercrimes Act 2025’ no correct

One post for social media platforms claim sey di national assembly don pass di “Cybercrimes…

August 30, 2025

Ózí na-ekwu nà é mepụ̀tálá ìwú megidere cybercrime bụ̀ àsị́

Ózí a hụtara na soshal midia kwuru na ụlọ ọme iwu Naijiria emeputala iwu megidere…

August 30, 2025

Irọ́ ni fídíò tó sọ pé Nàìjíríà ti sọ ‘Cybercrimes Act, 2025’ di òfin

Ọ̀rọ̀ kan lori àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára sọ pé ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà…

August 30, 2025

Hoton hoto hoto ko bidiyo mai zagaya yanar gizo da sauri akan hanyar ”Dokar Laifukan gizo 2025′ karya ce

Wani rubutu da aka buga a dandalin sada zumunta ya yi iƙirarin cewa majalisar dokokin…

August 30, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Viral post wey claim sey dem don pass ‘Cybercrimes Act 2025’ no correct

One post for social media platforms claim sey di national assembly don pass di “Cybercrimes Act 2025” into law. Dem…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 30, 2025

Ózí na-ekwu nà é mepụ̀tálá ìwú megidere cybercrime bụ̀ àsị́

Ózí a hụtara na soshal midia kwuru na ụlọ ọme iwu Naijiria emeputala iwu megidere "mpụ e ji ịntanetị eme…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 30, 2025

Irọ́ ni fídíò tó sọ pé Nàìjíríà ti sọ ‘Cybercrimes Act, 2025’ di òfin

Ọ̀rọ̀ kan lori àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára sọ pé ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 30, 2025

Hoton hoto hoto ko bidiyo mai zagaya yanar gizo da sauri akan hanyar ”Dokar Laifukan gizo 2025′ karya ce

Wani rubutu da aka buga a dandalin sada zumunta ya yi iƙirarin cewa majalisar dokokin ƙasar ta amince da dokar…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 30, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?